Ìjọba Oyo kò ní gbára lé owó láti òkè mọ́, á dojú kọ owó lára ìrìnàjò afẹ́ - Olatunbosun

Wasiu Olatunbosun

Kọmisona fun Aṣa ati irinajo afẹ ni nipinlẹ Oyo, Ọmọwe Wasiu Olatunbosun ti ṣalaye wi pe ipinlẹ Oyo ti ṣetan lati mu idagbasoke ba eto Igbafẹ ati Asa ju ti atẹyìnwa wa lọ.

Ọmọwe Wasiu Olatunbosun lo fi idi eyi mulẹ nibi ayẹyẹ ipatẹ lati sami ayajọ irinajo afẹ lagbaye to waye ninu Gbongan Bowers Tower ti gbogbo eeyan mọ si layipo nilu Ibadan.

Olatunbosun, ninu ọrọ rẹ ṣalaye wi pe, ijọba ipinlẹ Oyo n ṣakitiyan lati ri wi pe idagbasoke baa ẹka to risi Igbafẹ.

O ni eyi yoo mu ki ẹka naa le pese iṣẹ fun awọn ọdọ ipinlẹ Oyo, ti awọn ibudo isẹmbaye nipinlẹ naa yoo tunbọ ni okiki si.

Ayajọ Asa

"Bi ilu Dubai se ni epo rọbi to, irinajo afẹ ko ida pupọ ninu owo to n rogun sì asunwọn ijọba"

O tun ṣalaye wi pe laipẹ ọjọ o seṣee ki ipinlẹ Ọyọ mase gbe ara le owo lati asunwọn ijọba apapọ mọ nitori ẹka Igbafẹ ati Asa nijọba yoo gbẹ ẹru isuna ipinlẹ Oyo le lori.

Olatunbosun ni " Ọdọdun ni ipinlẹ Oyo n ṣe ayajọ ọjọ Asa ati idagbasoke irinajo afẹ, ọpọ ilu lagbaye lo mu eto Igbafẹ lokunkundun.

Bí apẹẹrẹ ilu Dubai pẹlu bi wọn ti ni epo rọbi to, irinajo afẹ ko ida pupọ ninu owo to rọgun sì asunwọn ijọba orilẹ-ede naa.

Oni afoju sun ipinlẹ Oyo ni wi pe laarin ọdun meji sì mẹta, idagbasoke yoo deba ipinlẹ Oyo latara ẹka Asa ati irinajo afẹ.

Lara awọn eto waye lati sami ọjọ asa to waye ni ere ibilẹ ati orin kikọ nibi ti ọpọ awọn eekanlu peju si.

Gbọngan Layipo Bowers Tower to wa lori oke Aremọ nilu Ibadan, tii se ọkan gbogi lara ibudo igbafẹ to n pawo wọle fun ijọba ipinlẹ Oyo, si ni eto naa ti waye.

Ajọ isọkan orilẹede agbaye lo ya ọjọ Kẹtadinlọgbọn osu kẹsan ọdọọdun sọtọ lati fi sami ayajọ agbelarugẹ irinajo afẹ jakejado agbaye.