Sam Larry ti wà ní àhámọ́ ọlọ́pàá

Sam Larry

Oríṣun àwòrán, @tvcnewsng

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti fi ṣikun mu Balogun Eletu, ti ọpọ eeyan mọ si Sam Larry lori iwadii to n lọ lọwọ lori iku oloogbe Ilerioluwa Aloba ‘Mohbad.’

Agbẹnusọ ileeṣẹ naa, Benjamin Hundeyin lo fi ọrọ ọhun lede ninu atẹjade kan loju opo Twittter rẹ.

O ni ‘Balogun Olamilekan Eletu ti ọpọ mọ si Sam Larry ti wa ahamọ wa. O si ti n ran wa lọwọ ninu iwadii wa to n lọ lọwọ.”

Iroyin ni ileeṣe naa ti kọkọ fi iwe pe Sam Larry ati oludasilẹ ileeṣẹ Marlian Record, Naira Marley, fun iwadii lori iku oloogbe ọhun.

Ọsẹ to kọja ni ọlọpaa tun fidi rẹ mulẹ pe oun ti pari iṣẹ lori ayẹwo oku Mohbad lati mọ irufẹ iku to pa a, awọn si n duro de esi.

Atẹjade naa ni “A ti pari ayẹwo oku rẹ, esi ayẹwo naa ni a n duro de bayii.”

SP Benjamin Hundeyin

Oríṣun àwòrán, SP Benjamin Hundeyin

Eyii lo waye lẹyin ti ọlọpaa wu oku naa lẹyin ti awọn mọlẹbi rẹ ti kọkọ sin in lẹyin ọjọ to dagbare faye.

Ọlọpaa tun ti fi ṣikun ofin mu nọọsi ti wọn ni o fun oloogbe labẹrẹ naa ṣaaju iku rẹ lọjọ kẹjila, oṣu Kẹsan an ti a wa yii.

Wayi o, Naira ti sọ pe oun ṣetan lati pada si Naijiria lati ran ọlọpaa lọwọ ninu iwadii wọn lati mọ kulẹkulẹ ohun to ṣekupa Mohbad, amọ ọlọpaa gbọdọ kọkọ fi ọkan oun balẹ pe aabo to peye yoo wa fun oun.

Naira Marley lo sọ ọrọ ọhun ninu ifọrọwerọ pẹlu oṣiṣe Aarẹ Naijiria tẹlẹ, Reno Omokri.

Ó pẹ́ tí Mohbad ti fẹ́ gbẹ̀mí ara rẹ̀ tẹ́lẹ̀, àwọn kan ń halẹ̀ mọ́ ọ àmọ́ kìí ṣe láti ọ̀dọ̀ mi - Naira Marley

Naira Marley

Oríṣun àwòrán, nairamarley/Instagram

Gbajumọ olorin takasufe Azeez Fashola ‘Naira Marley’ ti sọ pe oun ṣetan lati pada wa si Naijiria lati wẹ orukọ oun mọ ninu ẹsun lilọwọ ninu iku Mohbad ti awọn eeyan fi kan oun.

Naira Marley lo fi ọrọ naa lede ninu ifọrọwerọ kan pẹlu oṣiṣẹ Aarẹ Naijiria tẹlẹ, Reno Omokri.

Lati igba ti Mohbad ti jade laye lawọn eeyan ti n naka si Naira Marley pe o lọwọ ninu iku naa.

"Araalu ti ba orukọ mi jẹ kaakiri ori ayelujara pe mo mọ nipa iku Mohabad"

Eyii ko ṣẹyin awon fidio ibi ti awọn eeyan kan ti igbagbọ wa pe wọn jẹ oṣiṣẹ rẹ ti n lu oloogbe naa niluu bara.

Ifẹrọwerọ pẹlu Omokri yii ni ifọwerọ akọkọ ti Naira Marley yoo ṣe lẹyin iku Mohbad.

O ni awọn araalu ti ba orukọ oun jẹ kaakiri ori ayelujara pe oun mọ nipa iku Mohabad, oun yoo si pada wa si Naijiria ti ọlọpaa ba le fi da oun loju pe abo to peye yoo wa fun oun.

“O pẹ ti Mohbad ti fẹ gbẹmi ara rẹ tẹlẹ”

Naira Marley ṣalaye pe o ti to akoko diẹ ti Mohbad ti n gbero lati gbẹmi ara rẹ ṣaaju iṣẹlẹ ọhun.

O ni “Igba kan wa ti mo wa nilẹ Amẹrika, ti ọmọge kan pe mi pe Mohbad ti ara rẹ mọ inu ile igbọnsẹ pe oun fẹ pa ara oun...”

“Nigba naa ni mo pe e lati ibi ti mo wa ti mo si ka ifọrọwerọ naa silẹ nibi ti mo ti n bere lọwọ rẹ pe ‘ki lo de ti o fẹ fi pa ara rẹ... ti o ba pa ara rẹ bayiii, ki ni o fẹ ki awọn eeyan maa sọ?”

“Ọrọ naa ka mi lara to bẹẹ ti mo fi ke si pe ko fi ara rẹ lọkan balẹ, ti awọn mọlẹbi rẹ ko ba fi ọ lọkan balẹ, o le kuro lọdọ wọn.”

“O fẹ pa ara rẹ....”

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Instagram post

“Mo gbagbọ pe awọn kan n dunkoko mọ Mohbad, ṣugbọn kii ṣe lati ọdọ mi”

Naira Marley tẹsiwaju pe lootọ ni ọkan oloogbe naa ko balẹ amọ oun ko lọwọ si i.

“Emi gẹgẹ bii ẹnikan gbagbọ pe ọkan rẹ ko balẹ o si nilo iranlọwọ.”

“Mo gbagbọ pe awọn kan n dukoko mọ ati pe awọn eeyan kan n lepa rẹ, amọ kii ṣe lati ọdọ wa, ko si ninu ewu kankan lọdọ mi.”

“To ba jẹ pe oun tabi ẹnikẹni wa ninu lọdọ mi ni ko si ni si ẹni ti yoo ṣe fidio lati maa fẹsun kan mi.”

“Mi o kii ṣe ọmọ ẹgbẹ okunkun, ọdun 2019 ni mo lọ si Naijiria, mi o si mọ nnkan to n jẹ ẹgbẹ okunkun ṣaaju asiko naa.”

“Koda mo korira ẹgbẹ okunkun, awọn kan ti gbiyanju lati fa mi sinu ẹgbẹ okunkun ri amọ wọn ko ṣe aṣeyọri.