Sọ́jà méjìlá kú ní Niger torí ìkọlù àwọn alákatakítí ẹ̀sìn

Nigher Coup

Oríṣun àwòrán, getty Images

O kere tan, ọmọ ogun mejila lo ti jade laye ni Niger lẹyin ti awọn alakatakiti ẹsin kọlu wọn ni iha iwọ oorun orilẹ-ede Niger.

Iroyin ni awọn meje lo ku ninu ikọlu naa nigba ti awọn ọmọ ogun marun un mii ku ninu ijamba ọkọ lasiko ti wọn lọ doola awọn akẹgbẹ ti awọn alakakiti kọlu.

Minisita eto abo ilẹ naa lo fi ọrọ ọhun lede ninu atẹjade kan.

Nnkan bii kilomita aadọwa si ilu Niamey, to jẹ olu ilu orillẹ-ede Niger ni ikọlu ọhun ti waye.

Agbegbe naa tun sunmọ ala ilẹ to so Mali, Burkina faso ati orilẹede naa pọ.

Awọn ologun kan ti wọn ko fẹ fi orukọ wọn lede sọ fun ileeṣẹ iroyin Reuters pe ko din ni ologun mẹwaa to kọkọ ku nibu ikọlu naa.

Awọn agbebọn ikọ Al-Qaeda ati Islamic State maa n ṣe ikọlu lemọlemọ si awọn ologun atawọn araalu lagbegbe ti iṣẹlẹ ọhun ti waye.

Iroyin ni ori alupupu ni ọgọrọ awọn agbesunmọmi naa wa ti wọn ti ṣina ibọn bolẹ fun awọn ologun ni ilu Kandaji.

Àkọlé fídíò, Wolii Arole: Bí Ọlọ́run bá ní kí ń dá ṣọ́ọ̀ṣì tàbí orí òkè àdúrà tèmi sílẹ̀, màá ṣe é

Ipa wo ni bí France ṣe ń kó ọmọ ogun rẹ̀ kúrò yòó ní lórí Niger?

Niger coup

Oríṣun àwòrán, GETTY IMAGES

Ijọba orilẹ-de France ti sọ pe oun ti ṣetan lati ko awọn ọmọ ogun oun kuro ni Niger lẹyin awọn awuyewuye to n waye laarin rẹ ati ijọba ologun Niger lẹyin iditẹgbajọba to waye nibẹ.

Aarẹ Emmanuel Macron ni eredi igbesẹ na ko ṣeyin pe awọn ologun to wa lori alefa bayii ko ṣetan lati gbogun ti igbesumọmi, wọn si fẹ tẹsiwaju lati fi Aarẹ Mohamed Bazoum sinu atimọle.

Pupọ ninu awọn ọmọ orilẹ-ede Niger lo koro oju si France lẹyin ti ologun yọ Bazoum nipo, to jẹ ẹni ti France gba pe o jẹ ojulowo Aarẹ

Bi awọn eeyan ilu Niger ṣe n gbogun ti awọn ologun France naa ni awọn eeyan orilẹ-de France n fun Macron lọrun nile.

Niger ni orilẹ-ede kẹta ti ologun yoo ti gbajọba lara awọn orilẹ-ede ti France ko lẹru ṣaaju, iyẹn lẹyin Mali ati Burkina Faso.

Lara awọn ẹsun ti awọn ologun to bajọba naa fi kan Aarẹ Bazoum ni pe ohun gbogbo ti France ba n fẹ lo n ṣe lodi si ifẹ araalu.

Ki ni yoo sẹlẹ bawọn ọmọ ogun France se n kuro ni Niger?

Lati igba ti iditẹgbajọba ti waye lawọn agbesumọmi ti n ṣe ikọlu lemọlemọ si awọn ologun ati araalu ni Niger

Onimọ kan nipa ohun to n lọ nilẹ Afrika, Bram Posthumus, sọ pe bi awọn ologun naa ko ṣe faramọ ọmọ ogun France lorilẹ-ede wọn mu ko lera fun France lati fi awọn ọmọ ogun rẹ silẹ nibẹ.

Yatọ si eyii, ọpọ awọn olugbe Niger ni wọn n binu si iha ti France kọ si iditẹgbajọba ọhun.

Pupọ wọn lo gbagbọ pe kii ṣe irufẹ iha kan naa ni France kọ si iditẹgbajọba to waye ni Garbon ati Chad.

Ojuṣaju ti France n ṣe yii jẹ ki awọn eeyan Niger korira rẹ, gẹgẹ bii ohun ti Abdoulaziz Abdoulaye Amadou, to jẹ onimọ nipa ẹsin Islam sọ.

O ni “K ilo de ti Macron yoo fi sọ pe ijọba ologun wa kii ṣe ojulowo, amọ o gba pe ojulowo ni ijọba ologun Gabon ati Chad.”

Lati igba ti iditẹgbajọba ti ṣẹlẹ ni awọn agbesumọmi ti n ṣe ikọlu lemọlemọ si awọn ologun ati awọn araalu ni Niger.

Igbagbọ wa pe ti awọn ọmọ ogun France ba le fi Niger silẹ, aye yoo gba awọn agbesumọmi naa lati le maa ṣọṣẹ bo ṣe wu wọn siwaju.