Ète ìdìtẹ̀gbàjọba wáyé ní Burkina Faso, ọwọ́ tẹ àwọn ológun tó fẹ́ dìtẹ̀gbàjọba

Burkina Faso

Oríṣun àwòrán, Reuters

Awọn ologun to ditẹgbajọba ni Burkina Faso ti sọ pe awọn bẹgi dina igbesẹ awọn kan lati gba ijọba lọwọ awọn.

Diẹ lo ku ko pe ọdun kan bayii ti awọn ologun naa gbajọba, ti ọgagun Ibrahim Traoré si sọ ara rẹ di Aarẹ fidihẹ orilẹ-ede naa.

Gẹgẹ bii ohun ti wọn sọ, ọjọ Abamẹta ni igbiyanju iditẹgbajọba naa waye.

Ninu atẹjade kan ti wọn ka lori ẹrọ amohunmaworan, ijọba naa ni awọn ologun kan atawọn eeyan mii gbero lati da oju ijọba awọn bolẹ.

O ni “Wọn ni ero buburu lati kọlu awọn ileeṣẹ ijọba ki wọn si sọ orilẹ-ede wa sinu rogbodiyan.”

O fi kun pe ọwọ awọn ti tẹ awọn kan lara awọn ti wọn fura si pe wọn lọwọ ninu rẹ.

Lẹnu ọjọ mẹta yii ni awọn iroyin kan sọ pe wahala n waye laarin awọn ologun naa to gbajọba lọwọ oloṣelu.

Lọjọ Iṣẹgun, awọn iroyin kan jade pe awọn kan fẹ ditẹgbajọba, eyii to mu ki ọpọ araalu ṣe ifẹhonuhan nigboro ilu Ouagadougou lodi si iditẹgbajọba naa, ti wọn si sọ pe ijọba ologun to wa lori oye tẹ awọn lọrun.

Lọjọ ifẹhonuhan kan naa ni ijọba ọhun fofin de iwe iroyin Jeune Afrique ti wọn n gbe jade ni ede Frence, lori ẹsun pe o n fẹnu tẹnbẹlu ijọba ologun Traoré.

Oṣu Kẹsan an ọdun to kọja ni ijọba to wa lori alefa lọwọ yii gbajọba, eyii to jẹ iditẹgbajọba keji laarin oṣu mẹjọ.