Olórí ẹgbẹ́ awakọ̀èrò l’ Eko, MC Oluomo ránṣẹ́ ìkìlọ̀ sí ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ NLC

Aworan MC Oluomoati iwode NLC kan

Oríṣun àwòrán, others

Alaga ẹgbẹ awakọ ero nipinlẹ Eko, Musiliu Akinsanya ti ọpọ mọ si MC Oluomo ti kilọ fun ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC lorilẹede Naijiria, lati dẹkun yiyọ ṣuti ete si ọrọ ẹgbẹ awakọ ero NURTW.

MC Oluọmọ ki awọn adari ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC fi tiwọn ṣe tiwọn ki wọn si jẹ ki awọn adari ẹgbẹ awakọ naa ṣe atunto ẹgbẹ naa funrarawọn.

Atẹjade ti MC Oluọmọ fi sita lọjọru lo ti sọ eyi pẹlu awuyewuye to n waye lori akoso ẹgbẹ awakọ NURTW lẹnu ọjọ mẹta bayii.

Awuyewuye to waye laarin igun meji to n ja du ipo adari ẹgbẹ naa nilu Abuja lo fa yanpọnyanrin lolu ileeṣẹ ẹgbẹ naa nilu Abuja lọsẹ diẹ sẹyin, to si ṣe okunfa bi awọn ọlọpaa ṣe gbe aarẹ ẹgbẹ naa, Tajudeen Baruwa si atimọle.

Igbesẹ yii lo mu ki aarẹ ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC, Joe Ajaero pe fun itusilẹ rẹ lasiko to ba minisita fun ọrọ oṣiṣẹ, Simon Lalong sepade laipẹ yii.

Eto wa fun oye jíjẹ lẹgbẹ NURTW -MC Oluọmọ

Ninu ọrọ rẹ, alaga ẹgbẹ awakọ ero nipinlẹ Eko naa ṣalaye pe ọrọ iyansipo adari lo n fa rugudu, ilana si ti wa laarin ẹgbẹ naa lori bi wọn yoo se maa pin ipo laarin ẹkun gbogbo ti won pin in si.

O ni “ẹkun keji, to jẹ ẹkun iwọ oorun gusu Naijiria ni ipi aarẹ igbakeji ati majẹobajẹ ẹgbẹ tọ si lati lo saa ọlọdun mẹrin meji.”

O ni awọn ọmọ ẹgbẹ lẹkun wọnyi ni yoo wa yan ẹni ti wọn ba fẹ fun awon igbimọ apapọ lati fọwọsi nibi ipade aṣoju tiyoo waye lori rẹ.

‘Saa iṣakoso Baruwa at’awọn alaga nipinlẹ gbogbo ti pari’

Aworan rugudu kan

Oríṣun àwòrán, others

Àkọlé àwòrán, Wahala waye nilu Abuja laarin igun mejeeji to n figagbaga fun ipo adari ẹgbẹ awakọ ero NURTW laipẹ yii

Bakan naa ni MC Oluọmọ tun salaye pe labẹ ofin ati ilana aatẹẹle ẹgbẹ awakọ saa ro yẹ ki Tajudeen Baruwa gẹgẹ bi aarẹ ẹgbẹ naa, ati saa awọn alaga ẹgbẹ naa lẹka ipinlẹ pẹlu ti pari.

O ni ohun to kan bayii lẹyin ti wọn ti ya ju gbogbo aawọ to wa nilẹ laarin ẹgbẹ baa ni pe ki ipade ẹlẹku jẹkun o waye lati yan awọn oludije fun awọn ipo gbogbo.

“Lasiko iṣejọba Baruwa ipinlẹ marun ninu mẹfa ni wọn ti gbẹsẹle iṣẹ ẹgbẹ NURTW Ipinlẹ Ekuti nikan ni wọn ti n ṣiṣẹ.”