Àṣẹ tí ilé ẹjọ́ pa nípa bí INEC ṣe fẹ́ lo MC Oluomo fún pínpín ohun èlò ìdìbò lọ́la rèé

Musiliu Akinsanya

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Ile ẹjọ giga ti ipinlẹ Eko ti dajọ loni ọjọ Ẹti nipa igbesẹ ti ajọ eleto idibo Naijiria fẹ gbe lati lo alaga ẹgbẹ awọn awakọ ati gareji ni ipinlẹ Eko, Musiliu Akinsanya ti ọpọ mọ si MC Oluomo fun pinpin awọn nnkan elo idibo kan ni ipinlẹ Eko.

Idajọ naa sọ pe ni kia ki INEC dẹkun lilo MC Oluomo tabi ẹnikẹni to to mọ ọ ri ati gbogbo ẹni to ba n ṣiṣẹ labẹ rẹ gẹgẹ bi oṣiṣẹ tabi awakọ fun pinpin ohun elo idibo.

Eyi ni ẹjọ ti adajọ Chukwujekwu Aneke da latari ẹjọ ti ẹgbẹ oṣelu Labour Party ati oludije wọn fun ipo Gomina nipinlẹ Eko, Gbadebo Rhodes-Vivour atawọn mẹrin mii pe.

Awọn mẹrin mii ti wọn lọwọ ninu ipẹjọ yii ni: ẹgbẹ oṣelu African Democratic Congress, Boot Party pẹlu awọn oludije wọn sipo gomina, Funsho Doherty ati Wale Oluwo.

Ni ọjọ Aje ọsẹ yii ni ile ẹjọ naa sun igbjọ yii siwaji pẹlu idajọ fidihẹ kan ti wọn fi sita lọjọ naa ti wọn fi sun un siwaju di ọjọ Ẹti (oni) fun idajọ.

Awọn olupẹjọ nipasẹ agbẹjọro wọn, Abass Ibrahim sọ niwaju ile ẹjọ pe ki ile ẹjọ dajọ pe “gbigba MC Oluomo siṣẹ tabi yiyan an, tabi nini ajọṣepọ pẹlu rẹ tabi igbimọ awọn awakọ rẹ nipinlẹ Eki lati ba ajọ INEC pin ohun elo idibo ọdun 2023 tapa si abala ofin ikẹrindinlọgbọn ati ikẹtadinlọgbọn ninu iwe ofin orilẹede Naijiria ti ọdun 2022 ti o si lodi si ofin.”

Wọn ni idi eyi ni pe bi wọn ba lo adari ẹgbẹ awọn awakọ eyi ti Gomina Babajide Sanwo-Olu ti ipinlẹ Eko ṣa gbekalẹ rẹ yoo faaye gba magomago idibo, ọgbọn alumọrọyi ati adọgbọn ṣe ohun ti ko tọ lasiko idibo ni ifẹ ẹgbẹ oṣelu APC eyi ko dara wọn si n fẹ ki wọn dawọ rẹ duro ni kiakia.

Awọn olupẹjọ naa kọ gbogbo ohun to jẹ ẹdun ọkan wọn yii si bii ọna marun un ti wọn si ṣọwọ si ile ẹjọ.

Ẹwẹ, ajọ INEC ko kọ iwe kankan lati fesi si ipẹjọ naa tabi yala ki agbẹjọro kankan ṣoju wọn pẹlu bo ṣe jẹ pe wọn fi gbogbo iwe ipẹjọ naa ṣọwọ si wọn bi ile ẹjọ ṣe paa laṣẹ.

Ṣáájú, ilé ẹjọ́ pàṣẹ kí INEC má kó nǹkan ìdìbò fún MC Oluomo láti pín, ìdí nìyìí

Musiliu Akinsanya

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Ile ẹjọ giga kan ni ipinlẹ Eko yi paṣẹ lati dena ajọ eleto idibo orilẹede Naijiria ki wọn ma ṣe gbe iṣẹ pinpin awọn ohun elo idibo fun alaga ibudokọ ati gareji ipinlẹ Eko, Musiliu Akinsanya ti ọpọ mọ si MC Oluomo tabi ẹnikẹni to ba n ṣoju rẹ.

Adajọ Chukwujekwu Aneke gba ipẹjọ yii wọle lẹyin to gbọ ẹjọ naa eyi ti ẹgbẹ oṣelu Labour Party atawọn ẹgbẹ oṣelu meji mii pẹlu awọn oludije ipo gomina wọn.

Yatọ fun ẹgbẹ oṣelu Labour Party ati oludije ipo gomina rẹ nipinlẹ Eko, Gbadebo Rhodes-Vivour, awọn ẹgbẹ oṣelu mii tawọn fiwe ipẹjọ tako MC Oluomo ranṣẹ ni African Democratic Party ti oludije rẹ jẹ Funsho Doherty ati Boot Party ti oludije rẹ jẹ Wale Oluwo.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ohun ti awọn oniroyin jabọ ni pe ajọ eleto idibo to jẹ olujẹjọ kan ṣoṣo ninu ẹjọ yii ko farahan nile ẹjọ bo tilẹ jẹ pe agbẹjọro to n ṣoju awọn ẹgbẹ oṣelu naa, Abass Arisekola sọ fun ile ẹjọ pe wọn fi iwe ipẹjọ naa ṣọwọ si ajọ INEC.

Agbẹjọro awọn olupẹjọ tun sọ fun ile ẹjọ pe lara idi ti wọn fi pe ẹjọ yii ni pe awọn onibara oun ko ni ni ifọkanbalẹ ti ipenija aiwaye ni irọwọ-rọsẹ idibo nipinlẹ Eko yoo si kọ wọn lominu gidi gan.

“Fun anfani idajọ ododo lati ma faye gba ajọ eleto idibo ki wọn gbe igbesẹ tabi tun gbe igbesẹ mii siwaju sii lori ọrọ yii ni a ṣe pe ẹjọ naa”.

Ẹwẹ, nigba ti adajọ gbọ lẹnu olupẹjọ to si tun boju wo iwe ipẹjọ naa daadaa, adajọ Aneke fi lede pe: “Mo ti gbọ ẹjọ agbẹjọro mo si ti yẹ awọn aridaju to ba iwe ipẹjọ wa wo to fi mọ idi ti wọn fi pe ẹjọ. Mo ri ododo ni ipẹjọ naa. Nitorinaa, mo fi ontẹ lu ki o ma si igbesẹ kankan ni lọọlọ yii,”

Lẹyin ti ile ẹjọ pa aṣẹ yii, agbẹjọro bẹbẹ fun ki wọn din ọjọ idajọ gaan ku nitori ọjọ eto idibo to ti n sunmọ.

Adajọ Aneke fọwọ si dindin ọjọ idajọ ku o si sun igbẹjọ naa siwaju do ọjọ Kejilelogun Oṣu Keji, nigba to ni ki wọn rii daju gbogbo abajade ile ẹjọ de eti igbọ ajọ eleto idibo.

Alaga ajọ eleto idibo ni Eko, Olusegun Agbaje ti ṣaaju sọ ni ibẹrẹ Oṣu Keji pe ajọ naa yoo ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn alaṣẹ ibudokọ ati gareji ipinlẹ Eko labẹ idari MC Oluomo lati pin awọn ohun elo idibo kaakiri ipinlẹ naa.

Amọ, igun oludije ipo aarẹ lẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party (PDP), Atiku Abubakar ṣe ikilọ fun ajọ INEC pe ki wọn ma lo awọn oṣiṣẹ ibudokọ nitori ọwọ mimọ lasiko idibo.

Gomina Babajide Sanwo-Olu lo ṣe agbekalẹ igbimọ ibudokọ yii lẹyin to fopin si iṣẹ ẹgbẹ awọn awakọ (NURTW) ni Eko.