Agbébọn ṣekúpa akọ̀ròyìn lẹ́nu iṣẹ́ àti ọmọdé kan ní Florida

Oríṣun àwòrán, SPECTRUM NEWS 13
Akọ̀ròyìn iléeṣẹ́ amóhùnmáwòrán kan, Dylan Lyons tó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́rìnlélógún àti ọmọdébìnrin kan, ọmọ ọdún mẹ́sàn-án ti pàdánù ẹ̀mí wọn sọ́wọ́ agbébọn kan ní Orlando, Folrida, orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà.
Agbébọn ọ̀hún tó jẹ́ afurasí pé òun ló wà nídìí ìṣẹ̀lẹ̀ ìṣekúpani yìí tún yìbọn bá akọ̀ròyìn mìíràn, Jesse Walden àti ìyá ọmọ ọdún mẹ́sàn-án tó ṣekúpa.
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní àwọn akọ̀ròyìn náà ni wọ́n ń ṣiṣẹ́ lórí ìròyìn arábìnrin kan tí àwọn kan ṣekúpa kí agbébọn náà tó yìbọn fún wọn.
Àmọ́ ohun tí kò dájú ni pé bóyá àwọn akọ̀ròyìn náà ni afurasí agbébọn náà fẹ́ yìbọn fún.
Ìwádìí ní àwọn ọlọ́pàá bá ìbọn lọ́wọ́ afurasí náà tí kò sì fẹ́ kí àwọn ọlọ́pàá mú òun.
Ní ọjọ́rú ni ìṣekúpani kan wáyé ní Pine Hills lẹ́bàá Orlando tí wọ́n kò ìtíì mọ àwọn tó bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà lọ.
Nígbà tó pe ìpàdé àwọn akọ̀ròyìn, ọ̀gá àgbà Orange County, Orlando, John Mina ní ó ṣeéṣe kó jẹ́ wí pé àwọn akọ̀ròyìn náà wà nínú ọkọ́ tàbí lára ọks wọn nígbà tí wọ́n ṣe ìkọlù sí wọn ní nǹkan bíi aago mẹ́rin ìrọ̀lẹ̀.
Mina ṣàlàyé pé àwọn akọ̀ròyìn iléeṣẹ́ ìròyìn Spectrum News 13 náà ń ṣe ìwádìí lórí obìnrin kan tí àwọn agbébọn kan ṣekúpa kí afurasí náà tó tún dáná ìbọn yá wọn.
Lẹ́yìn tó ṣe ìkọlù sáwọn akọ̀ròyìn náà tán, afurasí agbébọn náà, Keith Moses tó jẹ́ ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún tún lọ sí ilé kan tó wà ní ẹgbẹ́ ibẹ̀ níbi tó ti yìbọn fún ọmọbìnrin náà àti ìyá rẹ̀.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Ìyá ọmọ náà ló wà ní ẹsẹ̀ kan ayé ẹsẹ̀ kan ọ̀run báyìí.
Ìròyìn ní àwọn akọ̀ròyìn mìíràn tó wà ní ìtòsí ló pèsè ìrànwọ́ fún àwọn tó farapa nínú ìkọlù náà.
Mina tẹ̀síwájú pé afurasí náà ti ní àwọn ẹ̀sùn tó pọ̀ lọ́rùn tẹ́lẹ̀ tó fi mọ́ ẹ̀sùn olè jíjà.
Bákan náà ló ní ó ṣeéṣe kó jẹ́ wí pé afurasí náà rò wí pé bóyá ọlọ́pàá ni àwọn akọ̀ròyìn náà lọ fi yìbọn bà wọ́n.
Akọ̀ròyìn iléeṣẹ́ amóhùnmáwòrán WESH 2 sọ wí pé kò pẹ́ tí òun àti ayàwòrán kúrò níbẹ̀ kí ìṣẹ̀lẹ̀ náà tó wáyé.
Charter Communications, iléeṣẹ́ tó ni iléeṣẹ́ amóhùnmáwòrán náà ní àjálù ńlá ló wáyé ní Orlando àti pé ikú àwọn òṣìṣẹ́ náà jẹ́ ìbànújẹ́ ọkàn fún àwọn.
Akọ̀wé ilé ààrẹ Amẹ́ríkà, Karine Jean-Pierre nínú àtẹ̀jáde tó fi sórí ayélujára ní àwọn bá ẹbí àwọn akọ̀ròyìn tó pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ nínú ìkọlù náà kẹ́dùn àti gbogbo iléeṣẹ́ Spectrum News tí wọ́n ń bá ṣiṣẹ́.
Àwọn akọ̀ròyìn ogójì ló pàdánù ẹ̀mí wọn lọ́dún 2022 gẹ́gẹ́ bí àtẹ̀jáde àjọ tó ń rí ààbò àwọn akọ̀ròyìn “Committe to Protect Journalist”. Ènìyàn kan péré nínú wọn lọ jẹ́ láti Amẹ́ríkà.












