Ọ̀pọ̀ èèyàn farapa lásìkò tí àwọn jàndùkú kọlu àwọn alátìlẹyìn Kwakwanso ní Kano

DAN IYA

Oríṣun àwòrán, DAN IYA

Ọpọ araalu lo farapa lasiko ti awọn janduku kọlu awọn ololufẹ oludije sipo Aare labẹ asia ẹgbẹ oṣelu NNPP, Rabiu Musa Kwakwanso, ni Kano.

Ohun gbogbo ti padabọ sipo bayii lẹyin ti awọn agbofin lọ pana rogbodiyan ọhun.

Iroyin ni asiko ti awọn ololufẹ Kwakwanso lọ pade rẹ ni rogbodiyan naa bẹ silẹ.v

Awọ alatilẹyin ẹgbẹ NNPP ti Kwakwanso ti n dije ti fẹsun kan ijọba ipinlẹ naa pe oun lo ran awọn janduku lati kọlu wọn.

Amọ ijọba ipinlẹ ọhun ti fesi pe irọ to jinna si ootọ ni ẹsun naa.

Awọn oṣojumi koro ṣalaye fun BBC pe aarin awọn ololufẹ Kwakwanso ati APC ni ija ọhun ti waye.

Wọn ṣalaye pe “Nigba ti a n bọ, a ri ọpọ ọkọ ti wọn ti fọ gilaasi wọn.”

“A ri ọpọ eeyan ti wọn farapa, amọ niwọn igba ti ọkọ wa ko duro mi o le sọ iye wọn ni pato.”

KWANKWASIYYA REPORTER

Oríṣun àwòrán, KWANKWASIYYA REPORTER

Ẹnikan ti wọn ba ọkọ rẹ jẹ ni Naibawa 'Yan Lemo, sọ pe wọn kọlu oun latari pe oun wọ asọ ti aworan ati awọ Kwakwanso wa lara rẹ.

O ni “Ọkọ kan n tẹle ọkọ wa, o si n pariwo pe ki a kuro lọna fun oun, ni kete ti mo duro bayii ni mo ri awọn ọdọ kan ti wọn jade ninu mọto naa pẹlu oniruru ohun ija oloro lọwọ ti wọn si kọlu wa.”

Ẹwẹ, NNPP ti fẹsun kan awọn ọmọ ẹgbẹ alatako pe awọn lo n dena de Kwakwanso ko ma le lafaani lati dibo lọjọ Abamẹta.

Wayi o, BBC ti kan si APC lori ẹsun ti NNPP fi kan an, amọ aṣoju ẹgbẹ ọhun to ba wa sọrọ ti sọ pe irọ ni gbogbo ẹsun ti NNPP fi kan awọn.