Lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ wákàtí, Iléeṣẹ́ Ọlọ́pàá Finland tú adelé olórí IPOB, Simon Ekpa sílẹ̀

Oríṣun àwòrán, Simon Ekpa/Twitter
Ileeṣẹ ọlọpaa Finland ti tu adele olori ẹgbẹ adijagbara to n pe fun ominira Biafra, Simon Ekpa silẹ lẹyin ti wọn fi ofin mu sọdọ fun ọpọlọpọ wakati.
Akọroyin to fi idi ọrọ naa mulẹ fun BBC ni ileeṣẹ ọlọpaa tu Ekpa silẹ lẹyin ti wọn fi ọrọ jumitoro ọrọ pẹlu rẹ fun ọpọlọpọ wakati.
Ekpa farahan lori fọkan to gbe sori ayelujara Twitter rẹ nibi to ti n ṣe ajọyọ lori nkan to pe ni “Aseyori ọjọ akọkọ konilegbele”.
Ekpa, ẹni to jẹ ọmọ orilẹede meji, Naijiria ati Finland ni o bẹrẹ fọran to gbe sori opo ayelujara rẹ pẹlu orin orilẹede Finland, to si gbe asia Finland lọwọ.
Ijọba orilẹede Naijiria ti pe akiyesi ijọba Finland si bi Ekpe ṣe n pe fun iyapa awọn Igbo lati ma kopa ninu eto idibo to n bọ.
A ko le sọ boya wọn fi ẹsun kankan kan Ekpe lorilẹede Finland.

Oríṣun àwòrán, others
Bawo ni wọn ṣe mu Ekpa?
Ileeṣẹ ọlọpaa Finland gba Simon Ekpa mu, ẹni to kede konilegbele ni ẹkun guusu ila oorun orilẹede Naijiria saaju eto idibo aarẹ lọjọ Satide ni ile rẹ lọjọbọ, Ọjọ kẹtalelogun, oṣu keji, ọdun 2023.
Ohun ti wọn mu Ekpa fun ni ko ti ye wa sugbọn mimu Ekpa waye lẹyin ti ijọba apapọ orilẹede Naijira kesi aṣoju Ijọba Finland llorillẹede Naijiria, Leena Pylvanainen lori ọrọ Ekpa bi o ṣe n dunkoko lori eto idibo ni guusu ila oorun.
Ijọba Naijiria ni awọn ko ni fi ọwọ kekere mu Ekpa ti ijọba Finland ba kuna lati ṣe oun to yẹ lori dunkoko ọkunrin naa lati da eto idibo ru.
Agbẹnusọ ileeṣẹ iroyin Finland, Helsingin Sanomat sọ fun BBC pe akọroyin wọn lọ si ile Ekpa lati lọ ṣe ifọrọwọrọ sugbọn wọn ri bi ileeṣẹ ọlọpaa ṣe n gbinyanju lati mu Ekpa lọ si agọ wọn.
Akọroyin naa, Matilta Jokinen sọ fun BBC pe nigba ti oun bẹrẹ lọwọ awọn ọlọpaa pe kini Ekpa ṣe ti wọn fi gbe, o ni wọn ko da oun lohun.
Tani Simon Ekpa?
Simon Ekpa jẹ ọmọ orilẹede Naijiria ati Finland to jẹ adele olori ẹgbẹ to n pe fun ominira Biafra.
Orilẹede Finland ni Ekpa n gbe nibi to ti n saaju ipe fun ominira fun Biafra, to si sọ fun awọn ẹẹya igbo lorilẹede Naijiria lati kopa ninu eto idibo ti ijọba apapọ ba kuna lati tu Nnamdi Kanu silẹ.
Ekpa, lori opo ayelujara Twitter rẹ sapejuwa ara rẹ gẹgẹ bi ajafẹtọ ọmọniyan, oludasilẹ, agbẹjọrọ, oloṣelu, agbẹnusọ Biafria ati bẹbẹlọ.
O kede ọjọ marun un lati ọjọ kẹtalelogun titi di ọjọ kẹjidinlọgbọn gẹgẹ bi ọjọ konilegbele rẹ, to si ti da rukerudo silẹ ni apa guusu ila oorun naa.















