BBC 100 Women 2022: Ibijoke Faborode, àjọ Elect Her: Kò sí ohun tí ọkùnrin n ṣe tí obìnrin kò lè ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ

Àkọlé fídíò, Ibijoke Faborode, àjọ Elect Her: Kò sí ohun tí ọkùnrin n ṣe tí obìnrin kò lè ṣe jù bẹ́ẹ̀

Faborode sọ nipa ipa ti ajọ Elect Her ti ko lati ta awọn oludibo jí si ẹtọ wọn ninu idibo.

Ibijoke Faborede jẹ ọkan lara akọni ọgọrun un obìnrin ti BBC da lọla pe wọn pegede ninu iṣẹ akọni ti wọn n ṣe ni agbaye.

Oun ni oludari ajó ti kii ṣe ti ijoba ti wọn n pe ni 'Elect Her'.

O jẹ akọni to n ja pe ki awọn Obinrin tubọ ko pa ninu eto iṣelu Naijiria ki nkan le tẹsiwaju sii.

Ajọ Elect Her jẹ ajọ aranilọwọ to tun n pese itaniji fun awọn oludibo kaakiri Naijiria ki wọn le tubọ mọ ẹtọ wọn sii.