Ètò ìdìbò 2023: Ààbò tó dájú wà f'áwọn Agunbaniro-Ahmed Dogara

Aworan Ahmed

Oríṣun àwòrán, National Youth Service Corp/Facebook

Bi eto idibo aarẹ orilẹeded Nigeria ti sumo le Ọgagun Yushau Dogara Ahmed ṣalaye wi pe awọn agunbanirọ ọkẹ mẹwa ni yoo sise pẹlu ajọ to risi eto idibo INEC.

Ọgagun Ahmed oludari ikọ agunbanirọ ni gbogbon awọn Agunbaniro ti ajo INEC fẹ lo ninu eto idibo ni wọn ti se idanilẹkọ fun ti wọn si kilọ fun wọn lati maṣẹ gba ounjẹ lọwọ ẹnikẹni.

Ninu ọrọ rẹ Ahmed rọ awọn agunbanirọ lati ṣe pẹlẹ nibikibi ti wọn ba gbe wọn si lati ṣisẹ ki wọn si yẹra lati gba owo lọwọ awọn oloselu.

Ahmed nigba ti oun ba awọn Akọroyin sọrọ labuja lori ipalẹmo awọn agunbanirọ ni”awọn Agunbanirọ to le ni ọkẹ mẹwa ni wọn ti ṣe idanilẹkọ fun ni ti wọn si ti ṣetan lati ṣiṣẹ”

AWORAN

Oríṣun àwòrán, National youth service corps/Facebook

O ni awọn ti peṣe aabo to peye fun awọn Agunbanirọ ṣe ninu ati nlẹyin eto idibo yii pataki oun si ti ṣe ipade pẹlu awọn alasẹ ẹka aabo lati mu aabo awọn agunbaniro lokunkun dun.

Ahmed teṣiwaju lati ṣalaye pe ajo to se amojuto eto idibo INEC ti ṣeleri lati peṣe aabo fun awọn agunbaniro to wa ni igberiko.

O rọ awọn agunbanirọ lati ṣe isẹ wọn bi o ti ye ki eto idibo ọdun yii le kẹsẹ jari.