Ètò ààbò tó dájú máa wà lásìkò ìbò - Ọlọ́pàá

Àwòrán àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò lásìkò ìpàdé tí wọ́n ṣe ní Ondo

Awọn ẹṣọ alaabo nipinlẹ Ondo lo ti fi da awọn olugbe ipinlẹ naa loju pe aabo to peye yoo wa lakoko eto idibo apapọ ilẹ yii lọjọ Satide ati lẹyin rẹ.

Kọmiṣọna ajọ ọlọọpa ni ipinlẹ naa, Oyeyemi Oyediran, lo fi idaniloju yii han lẹyin ipade idakọnkọ tawọn adari ajọ ẹṣọ alaabo nipinlẹ naa ṣe pẹlu adele adari ajọ eleto idibo, INEC, nipinlẹ ọun.

Oyediran ni agbarijọ awọn ẹṣọ alaabo ẹgbẹrun meje ni yoo pese aabo jakejado ipinlẹ naa lakoko idibo.

Kọmiṣọna ọlọọpa naa wi pe “ipade ti awa adari ajọ eleto abo ṣe la fi ṣe atunyẹwo awọn igbesẹ taa fẹ gbe lati rii pe ko si laasigbo kankan lasiko ati lẹyin eto idibo nipinlẹ yii”.

Àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò lásìkò ìpàdé wọn

O fi kun pe gbogbo awọn ẹṣọ alaabo ti yoo jade lati boju to aabo ẹmi ati dukia awọn araalu ni wọn ti gba idanilẹkọ to peye lati le mu ki wọn ṣe iṣẹ naa bo ṣe tọ.

Oyediran wa rọ awọn olugbe ipinlẹ naa lati jade ṣe ẹtọ wọn gẹgẹ bi ọmọ orilẹede Nigeria tootọ ni pẹlẹkutu lai si gbe igbesẹ to lee da omi alaafia ru nipinlẹ naa.

Adele kọmiṣọna ajọ INEC nipinlẹ Ondo, Oyetola Oyelami to wipe gbogbo eto lo ti to ni ko si ohun kan to le da eto idibo ru nipinlẹ naa.

Oyelami ni “awọn oṣiṣẹ to le ni ẹgbẹrun mẹtadinlogun ni yoo ṣiṣẹ ni oriko idibo ojilelẹẹdẹgbaaji-din-meje jakejado ipinlẹ yi lọjọ Satide”.

Kọmiṣọna eleto idibo ọun wipe awọn oludibo to le ni miliọnu kan ati ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹrin lo ti gba kaadi idibo alalopẹ nipinlẹ naa ti kaadi to le ni ẹgbẹrun lọna ọọdunrun ṣi wa lọdọ ajọ naa ti wọn ko tii gba.

Oyelami fi kun pe ọwọngogo epo bẹntiro ati owo naira ko ni ṣe ipalara fun igbaradi ajọ naa rara toripe wọn ni ọna ti wọn yoo fi bori ipenija naa.