Òní ni ìpolongo ìkẹyìn tí Bola Tinubu (APC) yóò ṣe ṣáájú ìdìbò 2023, wo ọ̀nà míràn tí o lè gbà ní Eko

aworan

Oríṣun àwòrán, Asiwajubolaahmed/Facebook

Ijọba ipinlẹ Eko ti ya opopona miran sile lati gba fun awọn ọkọ ayọkẹlẹ bi ipinlẹ Eko ti fẹ gbalejo ipolongo ibo aarẹ ẹgbẹ oṣelu APC loni.

Ninu atẹjadẹ ti Ọga agba ajọ to risi igokegodo ọkọ nipinlẹ Eko, Bolaji Areagba filede.

Bolaji rọ awọn awakọ lati tẹle ilana tuntun na ko le mu adinku ba iṣẹju ti wọn o lo loju popo.

LASTMA ro awọn awakọ to gba ọna papakọ ofurufu si Maryland lati lo opopona Kodesoh si Obafemi Awolowo kiwọn jade si opopona Kudirat Abiola si Ojota.

Ajọ na ni apakan awọn opopona ni Ikorodu yo wa ni ṣiṣi fun lilo laisi idaduro.

Bolaji rọ awọn awakọ to n bọ lati papako ofurufu ibilẹ si Ketu-mile 12 lati gba ọna Kodesho si opopona Obafemi Awolowo si ile iṣẹ ijọba (secretariat) si ọna Mobolaji Johnson si OBIRI Ojota si Ketu lo si ibikibi ti wọn nlọ.

Atejade na fikun pe awọn ẹsọ alaabo yo wa ni gbogbo opopona to lọsi papa isere ti ipolongo ibo yo ti waye,o rọ awọn ti ayipada ninu irina ma se akoba fun lati ṣe aforijin fun ijọba.