Ọmọ Yahoo tó ń díbọ́n pe òun ní Ninalowo rí ẹ̀wọ̀n ọdún méjì he

Oríṣun àwòrán, EFCC/NINALOWO
Ile ẹjọ kan niluu Warri ti ran ọkunrin kan, Omoghan Destiny Igbinosa lẹwọn lẹyin to jẹbi ẹsun pe o n dibọn bii pe oun ni gbajumọ oṣere tiata Yoruba, Ninalowo Bolanle.
Eyii lo n waye lẹyin oṣu diẹ ti oṣere naa ke sita nipa awọn kọlọrọsi to n fi orukọ rẹ lu jibiti.
Adajọ to gbọ ẹjọ ọhun, Okon Abang nile ẹjọ giga kan niluu Warri ran afurasi naa lẹwọn lori ẹsun to jọ mọ fifi ara rẹ pe ẹlomiran.
Ṣaaju ni Ninalowo ti kọkọ pariwo sita, to si kilọ fun awọn ololufẹ rẹ pe ki wọn ṣọra fun ẹnikan to n lo orukọ oun fun jibiti.
Ẹsun naa ni “Pe iwọ, Omoghan Destiny Igbinosa laarin ọdun 2021 ati 2022 niluu Benin fi ara rẹ pe Ninalowo Bolanle to jẹ oṣere tiata.”
“Ti o si fi awọn iwe kan ranṣẹ si Newon Quanon lori ayelujara, ninu eyii ti o ti sọ pe lati ọdọ Ninalowo lawọn iwe naa ti wa pẹlu erongba lati lu jibiti.”
“Ohun ti o ṣe yii lodi si ofin iwa ọdaran ori ayelujara ti abala 22 (2) (b) (i), eyii ti ijiya rẹ wa ninu abala ofin 22(2) (b) (IV) ti ọdun 2015.
Nigba ti wọn pe ẹjọ rẹ, afurasi naa sọ pe oun gba pe lootọ ni oun jẹbi ẹsun ti wọn fikan oun.
Lẹyin to sọ bẹẹ tan ni agbẹjọro ijọba, M. Elodi rọ ile ẹjọ naa ko da seria fun.
Amọ agbẹjoro afurasi ọhun, A. J. Onwuanaje ati Dickson Egberume bẹ ile ẹjọ naa ko fi oju aanu wo onibara awọn.
Lẹyinorẹyin, adajọ ni ki afurasi naa lọ ṣẹwọn ọdun meji tabi ko san miliọnu kan naira owo itanran.
Bẹẹ naa ni ijọba apapọ yoo gbẹsẹle ẹrọ ilewọ rẹ ati $2,235 to wa ninu apo ifọwọpamọ rẹ.












