Ọmọ ààrẹ tẹ́lẹ̀ rí ní Zimbabwe, Robert Mugabe kó sí gbaga ọlọ́pàá

Oríṣun àwòrán, AFP
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní Zimbabwe ní ọwọ́ àwọn ti tẹ ọmọ ààrẹ tẹ́lẹ̀ rí ní orílẹ̀ èdè náà, Robert Mugabe fẹ́sùn wí pé ó bá dúkìá àwọn ènìyàn jẹ́ níbi ètò ayẹyẹ kan.
Ọmọ Mugabe náà tó jẹ́ ẹni ọdún mọ́kànlélọ́gbọ̀n ló ń kojú ẹ̀sùn mẹ́ta lórí bíba dúkìá jẹ́ àti ẹ̀sùn méjì pé ó na ọlọ́pàá.
Agbẹjọ́rò Mugabe ní ọ̀pọ̀ gíláàsì ọkọ̀ ló bàjẹ́, tó sì tún tutọ́ sí ọlọ́pàá lára.
Mugabe jiyàn gbogbo ẹ̀sùn tí wọ́n kà si lọ́rùn, tí wọ́n sì ti da sílẹ̀ láti parí ọ̀rọ̀ náà ní ìtùbí ǹ nùbí.
Lẹ́yìn tí ọ̀rẹ́ Mugabe, Sindiso Nkatazo lọ fẹjọ́ sùn ní àgọ́ ọlọ́pàá ni wọ́n nawọ́ gan tí wọ́n sì ní àpapọ̀ ohun tó bàjẹ́ jẹ́ $12,000 (£10,000) nínú àtẹ̀jáde kan tí iléeṣẹ́ ọlọ́pàá fi sórí ayélujára.
Mugabe Junior ni ọmọ kejì tí ààrẹ àná náà bí pẹ̀lú ìyàwó rẹ̀ Grace Mugabe.
Fídíò kan tí Zim Live fi síta ṣàfihàn bí Mugabe ṣe ń lọ sí ilé ẹjọ́ Májísíréètì láti lọ kojú ìgbẹ́jọ́ rẹ̀ tí ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ èrò sì dà tẹ̀le.
Ní ilé ẹjọ́, agbẹjọ́rò rẹ̀, Ashiel Mugiya ní àwọn tó pe Mugabe lẹ́jọ́ kò ṣe ìwádìí wọn dáradára, tó sì bèèrè fún píparí ọ̀rọ̀ náà ní tùbí ǹ nùbí nítorí ọ̀rẹ́ ni Mugabe àti ẹni tó wá fẹjọ́ rẹ̀ sùn.
Mugiya ní wọ́n kò b;a fẹnukò, ó ṣeéṣe kí wọ́n padà sí ilé ẹja àti pé ó ṣeéṣe kí wọ́n da ẹjọ́ lílu ọlọ́pàá tí wọ́n fi kàn-án nù.
Ààrẹ tẹ́lẹ̀ rí náà, Robert Mugabe dágbére fáyé lọ́dùn 2019, ọdún méjì lẹ́yìn tí wọ́n fi tipatipa le kúrò nípò ààrẹ Zimbabwe lẹ́yìn tó lo ọdún mẹ́tàdínlógójì nípò.
Àwọn olùyànnàyànnà ọ̀rọ̀ ní ó ṣeéṣe kí àwọn ọlọ́pàá má le mú Mugabe tó bá jẹ́ wí pé bàbá rẹ̀ ṣì wà láyé.
Igbákejì Mugabe, Emmerson Mnangagwa ló rọ́pò rẹ̀ lódì sí èròńgbà ìyàwó Mugabe láti gba ipò ọkọ rẹ̀.
Ẹ̀wẹ̀, ọmọ Mugabe ti darapọ̀ mọ́ Ààrẹ Mnangagwa tó sì ń tẹ̀le lọ síbi ìwọ́de ní ọdún tó kọjá.












