Mother tongue day 2023, Akomolede Nàìjíríà, YSAN: A ti parí iṣẹ́ lórí èdè ìperí Meta-Language Yorùbá
Wọn n kọ ede Yoruba ni fasiti mẹwaa nilẹ Gẹẹsi- Ojogbon Duro Adeleke
BBC Yoruba ni awọn agba ọjẹ Olukọ ninu imọ ede ati aṣa Yoruba gba lalejo lati sami ayẹyẹ ọjọ ede abinibi ti ọdun 2021.

Oloye Dipo Gbenro to jẹ agba Olukọ sọ nipa awọn oyinbo ti wọn n wa si Naijiria lati wa kọ sii nipa ede Yoruba.
Bakan naa ni aarẹ ana ẹgbẹ Akomolede yii tun sọ nipa akitiyan ẹgbẹ Akomolede ati Asa Yoruba fun itẹsiwaju ede naa ni iran ti a wa yii.
Awọn onimọ kikun nipa ede Yoruba mẹrẹẹrin yii sọ ọna abayọ si iṣoro to n koju ede Yoruba bayii.

Ojogbon Dotun Ogundeji to jẹ agba ọjẹ olukọ fun ọpọlọpọ ọdun seyin lati fasiti ọlọgba ẹranko ni Ibadan mẹnuba ipenija kikọ ati mimọ ede Yoruba.
Bakan naa lo sọ nipa iṣẹ iwadii akansẹ ti Ọ̀jọgbon Babatunde Fafunwa ṣe ni fasiti olododo ti Obafemi Awolowo ni Ile Ife.
- Àwọn Olùkọ́ ìpínlẹ̀ Eko dárà lórí Akọ́mọlédè àti Àṣà lórí BBC
- Àwọn Olúkọ ìpínlẹ̀ Oyo fakọyọ lórí ètò Akọ́mọlédè àti Àṣà púpọ̀
- Àwọn Olùkọ́ Yorùbá ní ìlú Ondo fọkọyọ lórí ètò Akọ́mọlédè àti Àṣà lórí BBC Yorùbá
- Ẹ ṣúnmọ́ bí láti kọ́ ẹ̀kọ́ nípa ìsọ̀rí ọ̀rọ̀ nínú gbólóhùn Yorùbá
- Wo ìyàtọ̀ tó wà láàrin Àjọ, Àáró àti ọ̀wẹ̀, tí wọn jẹ́ àṣà ìran ara ẹni lọ́wọ́ nílẹ̀ Yorùbá
Iwadii yii lo fihan pe ọmọ ti a ba fi ede abinibi kọ a maa pegede ju ti ede omiran lọ. ati pe ẹkọ a maa tete ye wọn ju ki a lo ede miran fi kọwọn lọ.
Bẹẹ, orilẹ-ede Naijiria ko tii ṣamulo abajade iṣẹ iwadii ọpọlọ yii titi di oni.

Arabinrin Omowumi Faleye to jẹ aarẹ ẹgbẹ Akomolede ni gbogbo Naijiria naa sọrọ lori ohun to kan bayii.
Aarẹ ẹgbẹ Akomolede sọ ipa ti ẹgbẹyii ti ko lati rii pe a fi ede Yoruba kọ awọn akẹkọọ ni kilaasi.
O tun mẹnuba ipa ti ajọṣepọ ẹgbẹ pẹlu YSAN bi lati ṣiṣẹ lori ede iperi Yoruba ti wọn yoo ma a fi kọ awọn akẹkọọ ni ipele de girama lori awọn iṣẹ bii Physics, Chemistry, Geography ati bẹẹ bẹẹ lọ ni ede Yoruba.
- Ẹ̀yin tí ẹ kò gbọ́ Yorùbá, ẹ ṣúnmọ́ bí láti kọ́ lítíréṣọ̀ èdè Yorùbá lórí BBC
- Ẹ wá dánrawò níbí pẹ̀lú Àpólà Ọ̀rọ̀ Orúkọ, "Noun Phrase"
- Àṣà Oge Ṣíṣe ní Akọ́mọlédè BBC Yorùbá ń gbé yẹ̀wò lónìí, Ó yá, iṣẹ́ ti bẹ̀rẹ̀...
- Ọmọ tí wọ́n bá fi èdè Yorùbá kọ́ ní ẹ̀kọ́ máa ń pegedé jú tí èdè míràn lọ- Ọjọgbọn Ogundeji
Ni afikun, o ni Meta-Language yii ni yoo wulo fun gbogbo eeyan to fẹ tun mọ sii nipa ede Yoruba ti yoo tun jẹ ki iṣẹ awọn olukọ rọrun sii.

Ojọgbon Duro Adeleke mẹnuba iṣoro ti awon ọdọ iwoyii n ni lori itiju pe awọn n kọ nipa ede Yoruba.
Olukọ ni faisiti Ibadan nibi ti snamọnti gbe dunlẹ yii ni bẹẹ, ile ladiyẹ ko ti niyii ni ọrọ naa jọ nitori wọn n wa olukọ Yoruba kakiri agbaye ni eyi ti awọn ọmọ Yoruba miran ti wọn kọ iṣẹ miran nile iwe giga a maa re oke okun lọ kọni nipa ede ati asa Yoruba.

Awọn akọṣẹmọṣẹ yii wa gba Obi ati Alagbatọ nimọran lati kọ awọn ọmọ ni ede ati aṣa Yoruba nitori ọjọ ọla won.





