Ìyá ẹni ọdún 80 jóná mọ́lé ní Kwara

Oríṣun àwòrán, Hassan Adekunle
Iya ẹni ọgọrin ọdun kan ti jade lẹyin ti ina sọ ninu ile kan niluu Ilorin.
Ileeṣẹ panapana ipinlẹ naa sọ fun awọn akọroyin pe ojule kẹtalelogoji, lagbegbe Fate, ni isẹlẹ naa ti waye.
Gẹgẹ bii atẹjade kan ti agbẹbnusọ ileeṣẹ naa, Hassan Adekunle fi lede, o ni arakunrin kan, ọgbẹni Oni, lo fi iṣẹlẹ ọhun to awọn leti ni nnkan bii aago mẹta ọsan.
Atẹjade naa ni “A ko tii mọ nnkan to ṣokunfa ina ọhun, ninu ojule mẹrin, ẹyọkan ṣoṣo lo jona.”
“Nitori aitete ke si ileeṣẹ panpana, ina naa ba ile ọhun jẹ.”
“A tun ri iya ẹni ọgọrin ọdun kan yọ jade ninu rẹ, eyii ti a gbagbọ pe o ti jade laye ki a to pa ina naa.”
Ṣaaju ni iroyin ti kọkọ sọ pe ina jo ilegbe kan lagbegbe ile iwosan Olanipekun, eyii to dojukọ ile ẹkọ Oyeleke Memorial College, niluu Offa.
Ile to ni ojule mẹrindinlogun ni ina ọhun ti sọ, ti mẹjọ ninu rẹ si jona gurugu.
Ileeṣẹ panapana sọ pe iye owo dukia to jona nibẹ ko din ni miliọnu mejilelọgọta naira.
Lẹyin naa lo rọ awọn araalu lati maa ṣọra ki wọn si yagọ fun ohun to le mu ki ina ṣẹyọ lagbegbe wọn lasiko yii.












