SERAP pe Buhari lẹ́jọ látàrí bó ṣe fòfin de ₦‎500 àti ₦‎1000 àtijọ́

Muhammadu Buhari

Oríṣun àwòrán, @NGRPresident

Ajọ ajafẹtọ ọmọniyan, SERAP, ti pe Aarẹ Muhammadu Buhari lẹjọ lẹyin to fofin de ₦‎500 ati ₦‎1000 atijọ, eyii to lodi si aṣẹ ile ẹjọ kotẹmilọrun.

Ṣaaju ni ile ẹjọ ọhun ti kọkọ sọ pe awọn araalu le maa na ₦‎200, ₦‎500 ati ₦‎1000 atijọ lọ titi ti oun yoo fi gbọ ẹjọ ti awọn gomina pe tako CBN ati ijọba apapọ.

Ipinlẹ mẹwaa lo pe ẹjọ naa pe awọn ṣi n fẹ ki awọn araalu maa na owo atijọ lọ.

Amọ ninu ọrọ ti Aarẹ Buhari ba awọn araalu sọ lọjọbọ to kọja, o ni ₦‎200 owo atijọ nikan lawọn eeyan le maa na, nigba ti ₦‎500 ati ₦‎1000 atijọ ko ṣe itẹwọgba mọ.

Ninu ipẹjọ SERAP, eyii to ni nọmba FHC/ABJ/CS/233/2023 nile ẹjọ giga kan niluu Abuja, o ni ki ile ẹjọ naa ṣagbeyẹwo boya aṣẹ tuntun ti Buhari pa nipa owo naa ba ofin mu, nigba ti ọrọ naa ṣi wa nile ẹjọ to ga julọ.

O ni oun n fẹ ki ile ẹjọ naa kede pe ohun ti Buhari ṣe lodi si ofin.

SERAP tun n fẹ ki ile ẹjọ fofin de Aarẹ Buhari ati gomina CBN, Godwin Emefiele, ki wọn ma le fi ẹsẹ ilana tuntun lori owo naira naa mulẹ titi ti ile ẹjọ to a julọ yoo fi ṣedajọ lori ẹjọ to wa niwaju rẹ.

SERAP sọ ninu iwe ipẹjọ naa pe “Titẹle ofin ni opo to so ijọba awarawa ro ni Naijiria.”

“Aarẹ Buhari atawọn adarii gbọdọ tẹle aṣẹ ti ile ẹjọ to ga julọ ba pa fun wọn.”

“Aṣẹ lati fofin de ₦‎500 ati ₦‎1000 atijọ lodi si aṣe ile ẹjọ to ga julọ, eyii ti agbara rẹ ga ju ti Aarẹ Buhari ati ijọba lọ.”

Awọn agbeọjọro to pe ẹjọ ọhun lorukọ SERAP ni Ebun-Olu Adegboruwa, SAN, ati Kolawole Oluwadare.

Lara awọn ti SERAP pe lẹjọ pẹlu Buhari ni agbẹjọro agba Naijiria, Abubakar Malami ati banki apapọ Naijiria, CBN.