Ètò ìdìbò 2023, àjọ FRSC yọ̀nda òṣìṣẹ́ 21,783 láti ṣerànwọ́ lásìkò ìdìbò

Oríṣun àwòrán, Federalroadsafetycorps/FACEBOOK
Bi eto idibo aarẹ Ọdun 2023 ṣe ku ọjọ perete ajọ to risi eto irina orilẹede yii Federal Road Safety Corp (FRSC) ti ṣetan lati yonda awọn oṣisẹ rẹ to le ni ọke kan lati pese iranwọ ki eto idibo naa le kẹsẹ jari.
Alukoro ajọ naa, Bisi Kazeem ninu atẹjade to fi ikede naa lede ṣalaye pe ọkọ ayọkẹlẹ 769; ambulansi 139; ajagbe ọkọ mẹtalelọgbon ni ajọ FRSC o fi sọwọ fun lilo lasiko eto idibo ọdun yi.
Bisi ni Ajọ FRSC yoo ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn ajọ ẹsọ alaabo miran lati rii daju wi pe awọn eronja eto idibo de ibiti wọn a ti lo ki wọn si pada si ile isẹ INEC .
Gẹgẹ bi atẹjadẹ na ti sọ, awọn oṣiṣẹ ajọ FRSC o ṣabojuto igoke-gbodo ọkọ ni awọn agbegbe ti eto idibo ti n waye.
Bisi ni ajọsepọ pẹlu awọn ẹsọ alaabo paapa julọ osiṣẹ ile iṣẹ ọlọpaa lati ri daju wi pe eto idibo ọdun yii kẹsẹ jari.
O ni ajo FRSC yoo se ayẹwo gbogbo ọkọ irinna ti ajọ INEC yoo lo lati ko gbogbo awọn eroja eto idibo ti awọn osiṣẹ FRSC yoo si tun ṣabojuto bi irọwọrọsẹ yoo ṣe wa ni gbogbo ibudo eto idibo.
Ninu atẹjade naa o ro awọn osiṣẹ ajọ FRSC lati fi wa ọmọluwabi si gbogbo ohun ti wọn sẹ ki eto idibo ọdun yii le kẹṣejari.











