CSP Patrick Agbazue, Ọlọ́pàá méjì mìíràn wà ní gbaga fún ẹ̀sùn ìṣekúpani lọ́nà àìtọ́

Oríṣun àwòrán, IgpBaba Alakali/Facebook
Ọga agba ile iṣẹ Ọlọpaa Alkali Baba ti gbe ikọ tutun kalẹ lati ṣe iwadii ẹsun ipaniyan lọna aito ti wọn fi kan awọn ọlọpaa Zone 13 to wa ni ẹkun Ukpo-Dunkofia ati ile iṣẹ ọlọọpa Ipinlẹ Anambra.
Ẹsun ipaniyan lọna aitọ ni wọn ti fi kan CSP Patrick Agbazue ti olu ile-iṣẹ ọlọọpa ni Abuja n ṣe iwadii lori rẹ.
CSP Patrick ni wọn fẹsun ipaniyan lọna aitọ kan, ti wọn ni o ni ọpọlọpọ millionu naira ninu asuwọn banki rẹ eyi ti o ju iye ti oun gba gẹgẹ bi owo oṣu rẹ.
Lara ẹsun miran ti wọn fi kan ni gbigbe awọn oku ti wọn pa lọ si ile igbokupamọ si aladani eyiti o tako ofin ijọba.
Ninu atẹjade ti ile iṣẹ ọlọpaa gbe jade lori itakun ayelujara rẹ ni Ọga agba ọlọpaa IGP Usman Alkali Baba ti gbe ikọ ti yoo fimufinlẹ lori awọn ẹsun ti wọn fi kan CSP Patrick Agbazue ati ile iṣẹ Ọlọọpa ipinlẹ Anambra.
Awọn ẹsun naa ni, ẹsun ipaniyan lọna aitọ, aiṣe iṣẹ ọlọpaa lọna to yẹ.

Oríṣun àwòrán, Screengrab twitter/princeOlumuyiwaAdejobi
Ki lo tu aṣiri yii sita?
Laarin ọsẹ yii ni iroyin kan gba igboro kan lori awọn ikanni ayelujara bii ti gbajugbaja oniroyin ori ayelujara nipa bi ikọ Ọlọọpa ṣe n ji awọn alaisẹ gbe, iwa ipaniyan lọna aitọ ati fifipa gba ọrọ lẹnu awọn alaisẹ ti wọn ni CSP Patrick Chukwuemeka Agbazue ẹniti o je aladari ikọ Ọlọọpa to ri si iṣẹlẹ pajawiri (RRS) ni Ipinlẹ Anambra ko sodi n ṣe.
Atẹjade naa fi kun pe awọn oṣiṣẹ ọlọpa ti wọn fẹsun kan ti wa ni olu ilu Naijiria ni ile iṣẹ ọlọpaa lati sọ tẹnu wọn bi iwadii lori awọn ẹsun naa ṣe n teṣiwaju.
Awọn ọlọpa naa ni CSP Patrick Agbazue, SP Nwode Nkeiruka alukoro ile isẹ ọlọpa fun Zone 13, Ukpo Dunkofia ati Insipekitọ Harrison Akama ti o n sisẹ po pẹlu ikọ RRS.
Baba Alkali ni ababọ eto iwadii ni yoo sọ oun ti ile isẹ ọlọọpa yoo ṣe.
Iṣekupani lọna aitọ awọn agbofinro Orilẹede yii.
ọpọlọpọ igba ni wọn ti fẹsun ipaniyan lọna aitọ kan ile iṣẹ ọlọọpa orilẹede yii,ọkan ninu ohun to faa iwọde EndSARS odun 2022 ko sẹyin fifi iwa ipa muni ati ifiya jẹni lọna aitọ lo jẹ ki ọpọlọpọ pe fun wi wọgile ẹka SARS, eyiti ile iṣẹ ọlọọpa ti wọgile.
Bi ile iṣẹ ọlọọpa ti n gbiyanju lati fọ iṣẹ naa ma ni awọn kan lara wọn ṣi n hu iwa buruku eyiti o n tabuku ile iṣẹ naa.
Ọkan ninu iṣẹlẹ bẹẹ ni eyiti o waye nipinlẹ EKO nibi ti afurasi ọlọọpa kan ti yinbọn mọ agbẹjoro Bolanle Raheem lọjọ Keresimesi Ọdun 2022.
Agbẹjọro ọhun ni wọn yinbon mọ laya ti o si padanu ẹmi rẹ.
Afurasi ọlọọpa Vambi Drambi lo n jẹjo lọwo nile ẹjọ giga ipinlẹ Eko lori ẹsun naa.















