Nítorí ìnira ọ̀wọ́ngógó naira àti epo, Ooni Ile Ife wọ́gilé àjọ̀dún Aje ní Ile ife

Oríṣun àwòrán, Ile Oodua
Ọọni ile Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ogunwusi ti fi ayẹyẹ ajọdun Aje ti ọdun yii rọ di ọjọ miran ọjọ ire.
Aafin Oodua ni ko si idi meji fun igbesẹ yii ju wahala inira ọwọngogo owo naira tuntun ati ọwọngogo epo bẹnitor to gbode lorilẹede Naijiria bayii.
Atẹjade kan ti agbẹnusọ fun Ọọni Ile Ifẹ, Ọtunba Moses Ọlafare fi sita sọ pe Ọọni kede igbesẹ wiwọgile ajọdun Aje ti ọdun yii lẹyin to ṣe ipade pẹlu igbimọ awọn lọbalọba ilẹ Ifẹ lori ipenija ti awọn ọmọ Naijiria n ba finra lọwọlọwọ.

Oríṣun àwòrán, Ile Oodua
“Gẹgẹbi Baba, inu Kabiyesi Ọọni ko dun, o si ti ṣe ipade pẹlu Iyalaje oodua, Ọmọọbabinrin Toyin Kọlade to jẹ alakoso ajọdun naa atawọn alẹnulọr gbogbo lati rii pe nnkan yanju bi o ti n tẹsiwaju lati maa gbadura fun orilẹede Naijiria.”
Agbẹnusọ fun Ọọni sọ pe ikede yoo waye lori ọjọ tuntun ti ajọdun naa yoo waye.
Ajọdun Aje jẹ pataki ajọdun ni ilẹ Yoruba lati fi ṣayajọ ọrọ aje, karakata ati idagbasoke iṣuna fun mutumuwa.








