Ìbùkún ló jẹ́ fún mí láti fi Ooni ṣe ọkọ - Olori Ashley Ogunwusi

Oríṣun àwòrán, Instagram.com/hrhqueenashleyafolasade
Olori Ashley Afolasade, iyawo kẹrin ti Ooni ilu Ile Ife, Oba Adeyeye Ogunwusi fẹ wọ aafin lọdun to kọja, ti salaye idi to fi jẹ pe ibukun lo jẹ fun lati fi Ooni se ade ori.
Olori Ashley woye ọrọ yii ninu fọnran kan to gbe jade lori ayelujara atawọn ọrọ iwuri to kọ sabẹ fọnran naa, eyi to fi ṣe ajọyọ oṣu mẹrin to di aya Oba.
Olori Afolasade sapejuwe Ooni gẹgẹ bi ifẹ aye rẹ, to maa n mu inu rẹ dun ni gbogbo igba.
Bakan naa lo dupẹ fun bi Ooni se fi ifẹ han si, to si n fi gbogbo nnkan se itọju rẹ.
"Ti n ba ṣe nnkan to dara ju laye, bi mo ṣe fun Ooni ni ifẹ mi ni"
Olori naa wa seleri pe oun yoo nifẹ Ooni pẹlu gbogbo nnkan toun ni, ti ko si ni fi igba kan fi Ooni silẹ.
“Oṣu mẹrin to dara julọ ninu aye mi lati ẹyin wa ni mo lo sẹyin, a si dijọ wa titi ayeraye ni, ọkọ mi"
Ninu fọnran naa, pẹlu orin ati oriki ni Olori Afolasade fi kan saara si Ooni, to si ni mimi kankan ko ni mi igbeyawo awọn.
“Oṣu mẹrin to dara ju, ti a si jọ wa titi ayeraye ọkọ mi, ololufẹ mi ati ifẹ aye mi.
“Bi o ṣe maa n pe orukọ mi, maa n mu mi ranti baba mi to ti doloogbe, ẹni to mu wa pade ara wa.
“Ibukun nla lo jẹ fun mi pe iwọ ni ade ori mi, o ma mu inu dun ni gbogbo igba.
“Pẹlu rẹ tabi ero rẹ lọkan mi ni inu fi maa n dun.
Mo gba ladura pe ki Oba oke fun wa ni ẹmi gun gun, alaafia, owo ati awọn ọmọ alalubarika lasẹ Edumare.
"Akande Mi Ajiwe Fun’Osha, Erujeje Adimula, Olowo Ori Afolasade, modupẹ"
Bakan ni Olori Afolasade dupẹ lọwọ Ooni fun bi o ṣe fi ifẹ ba lopọ pẹlu gbogbo nnkan to ni.
“Ti eeyan ba nifẹ nnkan, eeyan ma dabobo wọn, ohun to yẹ ki eeyan ṣe niyẹn,
“Modupẹ fun bi o ṣe tọju mi ati awọn eeyan to wa ni ayika rẹ. Modupẹ fun bi o ṣe fẹran mi fun bi mo ṣe wa. O nira lati ri ẹni bi ọkan eeyan, sugbọn ti eeyan ba ti ri wọn, diwọn mu ni.
“O nira fun mi lati ri ọrọ ti mo le fi sapejuwe bi oṣe jẹ si mi Ọkọ mi

Oríṣun àwòrán, hrhqueenashleyafolasade/Instagram















