Pásítọ̀ tó gbé ìbọn Ak-47 gun orí pẹpẹ wàásù ti wà láhámọ́ ọlọ́pàá, ohun tí ìjọ House on the Rock fèsì nípa rẹ̀ rèé

Oríṣun àwòrán, House on the rock/other
Ileeṣẹ ọlọpaa ni olu ilu orilẹede Naijiria, Abuja ti fi panpẹ ofin mu Pasitọ Uche Aigbe ti ijọ House on the Rock, Abuja fun gbigbe ibọn atamatase AK-47.
Atẹjade kan ti alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni Abuja, Josephine Adeh fi sita sọ pe wọn mu pasitọ naa atawọn eeyan meji miran ljọ Aje.
Okiki Pasitọ Uche Aigbe kan lẹyin to gbe ibọn AK-47 gun ori pẹpẹ lọjọ Aiku lasiko to fẹ ṣe iwaasu ni saa isin keji.
Atẹjade naa sọ pe “Ọpọ awọn ileeṣẹ iroyin ati awọn to n sọrọ lori ayelujara lo sọ pe iwaasu ati ihuwasi pasitọ naa lọjọ yii ni ọpọlọ̀pọ ohun to le da wahala silẹ ninu.”
O fi kun un pe wọn ti mu adari ẹka abo sọọṣi naa ati insipẹkitọ ọlọpaa kan ti orukọ rẹ n jẹ Musa Audu.
Ileeṣẹ ọlọpaa ni Insipẹkitọ Musa Audu yii lo gbe ibọn rẹ fun pasitọ lọjọ ti a n wi yii eleyi ti wọn ni o lodi si ofin iṣẹ ọlọpaa.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
Wahala bẹrẹ fun pasitọ naa nigba ti awọn eeyan kan lori ayelujara fi fọto rẹ ati iroyin nipa ọrọ naa to alukoro agba fun ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria, CSP Muyiwa Adejọbi leti lori Twitter. Lẹyin to gbe ọr naa yẹwo lo ni oun ti fi to kọmiṣọna ọlọpaa lolu ilu Naijiria leti fun igbesẹ to yẹ.
Eyi lo mu ki wọn gbe pasitọ naa, ti ileeṣẹ ọlọpaa si sọ pe iwadii ṣi n lọ lọwọ lori rẹ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
Iwa ti pasitọ wa hu yii ko boju mu rara – Ijọ House on the Rock
Ṣaaju ninu atẹjade kan to fi sita ni awọn alaṣẹ ijọ House on the Rock ti bu ẹnu atẹ lu iwa ti pasitọ Aigbe hu naa.
Ijọ House on the Rock ni Pasitọ Aigbe ko gbero lati da wahala silẹ bikoṣe lati fi ṣe idanilẹkọ fun awọn ọmọ ijọ rẹ.

Oríṣun àwòrán, SCREENSHOT
“Ni ọjọ Aiku ọjọ kejila oṣu keji ni pasitọ ijọ House on the rock, Abuja, Pasitọ Uche Aigbe , ninu iwasu rẹ nipa jija ija rere pẹlu awọn ohun ija ti ẹmi, gbe ibọn ti ko lọta lati ṣe akawe iwasu rẹ lori ‘Didaabo bo igbagbọ rẹ’.”
Awọn alaṣẹ ijọ naa ni pasitọ yii ti kabamọ ihuwasii rẹ nitori pe o ti rii pe igbesẹ to ku diẹ kaato ni gbigbe ibọn lati ṣa alaye iwaasu rẹ.
“Ijọ House on the Rock ko faye gba iwa ipa bi o ti wulẹ o mọ, ori iwaasu ihinrere Jesu Kristi to wa fun alaafia ati iwa rere si gbogbo eniyan ni a duro le.”
Wọn ni ijọ naa ti n fọwọsowọpọ pẹlu awọn alaṣẹ lori iwadii si iṣẹlẹ naa, ati pe igbesẹ yoo wa labẹnu lati rii pe iru awọn iwa to tako ofin bayii ko tun waye mọ.
Páṣítọ̀ gbé ìbọn Ak-47 wọ ṣọ́ọ́ṣì lọ́jọ́ ìsinmi, ariwo sọ

Oríṣun àwòrán, House of Rock
Pasitọ kan ni ọrọ rẹ ti gba ori ayelujara lẹyin to farahan ni ilẹ jọsin rẹ, to si bọ sori pẹpẹ pẹlu ibọn AK-47 lati fi ba awọn eeyan sọrọ.
Pasitọ Uche Aigbe, ti ile jọsin House of Rock lo wọle ti awọn ọmọ ijọ rẹ pẹlu ibọn AK-47 lọjọ Aiku, ọjọ kejila, oṣu keji, ọdun 2023 niluu Abuja.
Igbesẹ naa lo ya ọpọlọpọ ọmọ Naijiria lẹnu pe bibeli, ororo ati omi adura ni awọn mọ pẹlu awọn pasitọ, bawo ni ti ibọn ṣe jẹ fun ihamọra asiko iwasu lọjọ isin.
Sugbọn ibeere to kun ọkan ọmọ Naijiria ni pe ki gan ni idi ti Pasitọ Uche fi gbe ibọn AK-47 wọle ijọsin?
Pasitọ Uche gbe ibọn wọle ijọsin lati ṣe apẹẹrẹ bi awọn olujọsin ṣe le dabobo igbagbọ wọn pẹlu ibọn
‘Daabo bo igbagbọ rẹ’ ni akori iwasu ti Pasitọ Uche ṣe lọjọ isin, ti wọn si gbe sori ayelujara Facebook ile ijọsin naa.
Pasitọ Uche gbe ibọn wọle lati fi ṣe apẹẹrẹ bi awọn olujọsin ṣe le dabobo igbagbọ wọn pẹlu ibọn.
“O ni awọn nnkan ti ko ni nnkan ṣe pẹlu ẹsin, Ọlọrun kii ṣe apidan tabi olugbala, bẹẹ ni o mọ ohun gbogbo lati ana di ọla.
Sugbọn ko ki n wo ana lati fi iya jẹ eeyan, idi niyẹn ti ẹ fi lilo ibọn lati dabobo igbagbọ yin.”
Kete Pasitọ Uche bọ sori pẹpẹ ni awọn olujọsin bu si ẹrin nigba ti wọn ri pasitọ pẹlu ibọn lọwọ.
Ọpọ wọn si ni lati sun sẹyin sugbọn Pasitọ agba ni ki ẹnikẹni maa ṣe bẹru.
“Mo dira wa laarọ yii nitori pe mo fẹ daabo bo igbagbọ mi.” Eyi ni Pasitọ Uche sọ, to si na ibọn naa soke.
“Lasiko ti a wa yii, a ni lati da abo bo igbagbọ wa lọwọ awọn janduku, awọn agbebọn ati awọn ika eniyan ti wọn kẹyin Ọlọrun si wa.
Ki ni awọn eeyan sọ lori ayelujara nipa bi Pasitọ se gbe ibọn wọ sọọsi lọjọ isinmi?
Ọpọ awọn eeyan lori ayelujara lo ti bu ẹnu atẹlu igbesẹ Pasitọ, ti wọn si pe fun iwadii lẹkunrẹrẹ lọdọ ileeṣẹ ọlọọpa lati mọ ibi ti Pasitọ naa ti ri ibọn.
@Uzomaehiemere1 se apejuwe igbesẹ Pasitọ Uche gẹgẹ bi eyi ti ko ni aburu ninu ati pe Pasitọ Uche kan fẹ fi ibọn ọhun ṣe apẹẹrẹ ni.
"Apẹẹrẹ lasan ni igbesẹ yii wa fun. Kii ṣe pe o fi da alafia ilu ru tabi fa rogbodiyan.
Pasitọ Uche Aigbe jẹ ọkan lara awọn Pasitọ to jẹ eeyan dada ti mo mọ."
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 3
Deji Adesogan ntiẹ rọ ileeṣẹ ọlọpaa lati ṣe iwadii lori ibi ti Pasitọ ti ri ibọn to gbe wọ sọọsi.
"Se o tọrọ ibọn naa lọwọ awọn ẹsọ alaabo ni tabi o gba a lọwọ ileeṣẹ ọlọpaa?
"Eyi lodi sofin, ti ijọba si gbọdọ da si."
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 4
Bakan naa, Stephen Ikechukwu fẹ mọ ibi ti Pasitọ Uche ti ri ibọn to gbe wọ sọọsi.
O wa n beere lọwọ ileesẹ ọlọpaa ati aarẹ Muhammadu Bihari pe ki lo n sẹlẹ lorilẹẹede yii?
O tun n beere pe se orilẹede yii ti di orilẹ=ede ti ko tẹle ofin mọ ni? ti ohun gbogbo si ti dori koda.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 5