"Ìmúra ìgbeyàwó là ń ṣé, ọjọ́ tó yẹ ká kéde ìyàwó rẹ̀, ni wọ́n ṣekú pa ọkọ ìyàwó"

Oríṣun àwòrán, Sumaila Inuwa
Inu ẹkun ni idile Yahaya Inuwa Sumaila, ọmọ ọdun marundinlọgbọn ti awọn eeyan kan pa wa nitori wọn fẹsun ole kan wa.
Awọn ẹbi Inuwa, to n gbe ni ijọba ibilẹ Sumaila ni ipinlẹ Kano, lo n rọ ijọba lati ṣe idajọ awọn to pa Inuwa naa.
Yahaya, ọmọ ọdun marundinlọgbọn lo n foju sọna lati ṣe igbeyawo, ki awọn eeyan kan to fẹsun ole kan-an, ti wọn si pa a.
Sabiu Inuwa tii se ẹgbọn oloogbe ṣalaye fun akọroyin BBC pe ile iṣẹ ọlọpa ti fi awọn marun han fawọn akọroyin, ninu awọn mejidinlogun to ṣiṣẹ ibi naa.
Sabiu ni aburo oun, Yahaya ṣe abẹwo si ile afẹsọna rẹ lọjọ ti isẹlẹ naa waye.
O ni bi aago mẹwa alẹ ni awọn eeyan kan, ti wọn wa Ọkada, wa fẹsun kan aburo oun pe oun lo ji Ọkada awọn ni agbegbe Gwarabjawa ,ti wọn si pa.
"Ọjọ ta sin aburo mi, lo yẹ ka kede ọjọ igbeyawo rẹ"
O ni Ọkada Bajaj ni wọn ji gbe, ti Ọkada aburo oun je GQ, ṣugbọn awọn to ṣeku pa aburo oun ko gbọ nkankan, ti wọn si bẹrẹ si ni na Yahaya.
Sabiu ni aburo oun gbiyanju lati sa fun ẹmi rẹ ṣugbọn o yọ ṣubu, ti wọn si ṣa ni ada, ki wọn to da Bẹntiro si lara, ti wọn si sun nina.
Sabiu ni ọjọ ti awọn sin aburo oun, lo yẹ ki wọn kede ọjọ igbeyawo rẹ.

Oríṣun àwòrán, Sabiu Inuwa
Aláàánú ni ọmọ mi, o sì n bọwọ fun àwọn àgbà - Ìyá olóògbé
Zainabu Isyaku tii se iya ologbe Yahaya ni, ipakupa ni wọn pa ọmọ oun nitori lẹyin ti wọn pa tan, wọn wọ oku rẹ nilẹ, ki wọn to da bẹntiro si lara, ti wọn si sun nina.
Nigba to n sọrọ pẹlu omije, iya oloogbe naa ni ipalẹmo igbeyawo ọmọ oun ni awọn n gbaradi fun, ki wọn to ṣeku pa.
Oun naa ni oun ṣalaye fun wọn pe oun kii se ole ṣugbọn wọn o gbọ.
Zainabu ni ẹlẹyinju aanu ni Yahaya, to si bọwọ fun ọpọlọpọ awọn eeyan.
O wa rọ awọn agbofinro lati fi iya to tọ jẹ awọn to wa nidi isẹlẹ naa, ki irufẹ isẹlẹ naa ma ba a waye mọ.
Awọn mẹwa ninu awọn mejidinlogun ni awọn agbofinro mu, ki awọn afurasi mẹjọ to ṣẹku, to fẹsẹ fẹ, ti ọpọ wọn si sa kuro nilu.
Ẹwẹ, awọn marun ni wọn mu wa si ile ẹjọ fun ẹsun ipaniyan lọjọru, ki ile ẹjo to sun igbẹjọ lori ẹsun naa ṣiwaju.















