Ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọ́n fún mi ní májèlé jẹ, káwọn agbanipa tó kọlù mi - Apostle Suleman

Oríṣun àwòrán, Instagram
Pásítọ̀ àti olùdásílẹ̀ ìjọ Omega Fire Ministries International, Apostle Johnson Suleman ti tú pẹrẹpẹ́rẹ̀ ọ̀rọ̀ lórí bí àwọn kan ṣe fẹ́ gbẹ̀mí rẹ̀ lọ́dún tó kọjá.
Ìgbà àkọ́kọ́ nìyí tí Suleman yóò máa sọ̀rọ̀ lórí ìkọlù náà, èyí tó wáyé ní oṣù Kẹwàá, ọdún 2022 níbi tí ènìyàn méje, tó fi mọ́ ọlọ́pàá mẹ́ta, ti pàdánù ẹ̀mí wọn.
Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ níbi ètò kan, ni Apostle Suleman ti sọ̀rọ̀ lórí gbogbo nǹkan tó wáyé lásìkò tí ìkọlù ọ̀hún ṣẹlẹ̀ si.
"Èmi ni mo wa ọkọ̀ ayẹta tí agbébọn kọlú, mo fi ọkọ̀ gbá ọkàn lára àwọn agbanipa náà, kí ọlọpàá tó yìnbọn pá"
Apostle Suleman ní òun ni òun wa ọkọ̀ òun lọ́jọ́ tí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí wáyé àti pé àwọn tí kò mọ̀, rò wí pé bóyá awakọ̀ kan ló yọ òun lọ́wọ́ ikú.
Ó ṣàlàyé pé òun ni òun kọ́kọ́ fi ọkọ̀ gbá ọkùnrin tó gbé ìbọn láti yìn-ín fún òun níbi ìkọlù náà, kí ọlọ́pàá tó wá pa á pátápátá.
“Ó wá síwájú ọkọ̀ láti yìnbọn fún mi bí mo ṣe ń wa ọkọ̀, mo sì ń sọ ọ́ lọ́kàn mi wí pé ìwọ ọmọkunrin yìí ti kú báyìí.”
“Táyà àti bọ́nẹ̀tì ọkọ̀ mi kìí ṣe ayẹta àmọ́ gbogbo ìgbìyànjú ọmọkùnrin náà láti fi ìbọn fọ́ wọn ló já sí pàbó.”
Sulaiman ní ọta ìbọn kò wọlé sára ẹ́ńgìnì ọkọ̀ òun àmọ́ bí òun ṣe dé ilé, tí òun gbé ọkọ̀ náà kalẹ̀ báyìí ni ẹ́ńgìnì pa iná, tí kò sì ṣiṣẹ́ mọ́.
"Àwọn tó ń bá mi gbé wà lára àwọn tó fẹ́ pá mi"
Apostle Suleman wá ṣíṣọ lójú rẹ̀ pé púpọ̀ nínú àwọn tó jẹ́ ènìyàn òun, tó bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà lọ, lo jẹ́ wí pé àwọn náà wà lára àwọn tó jọ gbìmọ̀ pọ̀ láti ṣe ikú pa òun.
Ó ní èrò wọn ni pé àwọn ènìyàn náà kò ní sí níbi ìṣẹ̀lẹ̀ náà àmọ́ tí ọ̀rọ̀ bẹ́yìn yọ fún wọn , ṣùgbọ́ ó ní òun kò ní fi gbogbo ẹnu sọ̀rọ̀.
Ó tẹ̀síwájú pé àwọn kan máa ń fẹ́ kí ènìyàn máa gbé wọn gẹ̀gẹ̀ àmọ́ tó jẹ́ wí pé òfúùtù-fẹ́ẹ́tẹ̀ ni wọ́n.
"Ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọ́n ti fún mi ní májèlé jẹ àmọ́ tí Ọlọ́run ń kó mi yọ"
Suleman tẹ̀síwájú nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé àìmọye ìgbà ni wọ́n ti fún òun ní májèlé jẹ àmọ́ tí Ọlọ́run ń kó òun yọ.
Ó wá rọ àwọn ọmọ ìjọ náà tó ń ṣe ìwáàṣù fún láti súnmọ́ Ọlọ́run dáradára, kí wọ́n le máa borí ìṣòro èyí tó bá ń kojú wọn.
Ó sọ wí pé ọ̀gá àgbà àjọ ológun kan tilẹ̀ sọ fún òun pé kò sí ẹni tó le pa òun mọ́ nítorí ìkọlù tí òun bórí lọ́wọ́ àwọn agbanipa mẹ́sàn-án kìí ṣe ohun tó kéré rárá.















