Ìkọlù sí Apostle Suleiman, Kọmíṣánà pàṣẹ kí wọn yọ DPO kúrò nípò

Aworan Apostle Suleiman

Oríṣun àwòrán, WeLoveApostleJohnsonSuleman

Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Edo labẹ akoso Kọmiṣana ipinlẹ naa AIG Abutu Yaro ti paṣẹ pe ki DPO agọ ọlọpaa Auchi duro ṣẹgbẹ kan naa titi ti awuyewuye lori iku ọkan lara awọn afurasi agbebọn to ṣe ikọlu si Apostle Suleiman.

Apostle Suleiman ni oludari ati oludasilẹ ijọ Omega Fire Ministries Worldwide ti awọn agbebọn ṣe ikọlu si lasiko ti o ndari irinajo bọ.

Ninu atẹjade kan totẹwa lọwọ, kọmisana sọ pe pipaṣẹ pe ki DPO gba idaduro jẹ ọkan lara igbesẹ wọn lati fi mọ kunkundun ohun toṣokunfa iku ọkan lara awọn ọmọ ikọ agbebọn to ku lagọ ọlọpaa.

Bẹẹ ni wọn lo nbi lati wa ṣalaye lẹkunrẹrẹ ohun to wa nidi ọrọ yi ni ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa.

Bakna naa ni ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn ti bẹrẹ sinitọ pinpin awọn afurasi to ṣe ikọlu si Apostle Suleiman lọjọ Ẹti.

Chidi Nwabuzor to jẹ alukoro ọlọpaa sọ fun BBC pe ọlọpaa mẹta, awakọ meji, araalu meji ati ọkan lara awọn oṣiṣẹ Apostle Suleiman lo padanu ẹmi wọn ninu ikọlu yi.

Nwabuzor tẹsiwaju pe ọkan lara awọn to n ba Suleiman ṣiṣẹ moribi lọwọ awọn agbebọn yiṣugbọn awọn ko mọ ibi to wa bayi.

Ọlọ́pàá Edo sọ ìdí tí ọ̀kan lára agbébọn tó kọlu Apostle Sulaiman ṣe kú

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Edo, SP Chidi Nwabuzor ti ṣaaju sọ pe irọ ni iroyin to ni awọn ọlọpaa mọọmọ pa ọkan lara awọn agbebọn to kọlu Apostle Johnson Suleman ti ọwọ t lasiko ikọlu naa..

Ọjọ Ẹti ni iroyin gbalẹ pe awọn agbebọn kọlu ọkọ oludasilẹ ijọ Omega Fire Ministries Worldwide naa ati awọn ọkọ miran to kọwọrin pẹlu rẹ, ni opopona ilu Sabongida si Auchi.

Ọlọpaa mẹta ati awakọ meji, araalu meji ati ọmọ ọdọ kan nile apostle na ni ibọn pa.

Wakati diẹ lẹyin iṣẹlẹ ọhun ni Suleman kede lori ayelujara pe ọwọ ọlọpaa tẹ ẹnikan lara awọn to kọlu oun loju ẹsẹ, amọ wọn tun pada yinbọn pa a.

"Awọn agbebọn kọju ibọn sawọn ọlọpaa, ni ibọn ṣe ba ọkan lara wọn.”

Nigba to n ba BBC sọrọ lori isẹlẹ naa ati bi afurasi agbebọn naa se ku, Nwabuzor sọ pe ọmọ ọdọ kan ri aaye salọ, ti wọn ko si tii mọ ibi to wa.

SP Nwabuzor sọ pe lasiko ti ikọlu naa n waye ni ileeṣẹ ọlọpaa ni Auchi gba ipe pajawiri, ti wọn si sare lọ si ibẹ.

“N ṣe ni awọn janduku naa kọju ija ibọn si awọn ọlọpaa naa, ko to o di pe ibọn ọlọpaa ba ẹnikan lara wọn.”

O ni ni nkan bi aago marun-un irọlẹ ni ikọlu naa waye.

“Ọlọpaa mẹta to wa pẹlu Suleman, awakọ mẹta ati ọmọ ọdọ obinrin kan lo ku.

Bakan naa ni alukoro ọlọpaa sọ pe ọwọ tun tẹ ọkọ kan lara eyi ti awọn ‘janduku’ naa gbe wa.

SP Nwabuzor ṣalaye pe iwadii alagbara ti bẹrẹ lori iṣẹlẹ naa.

Nigba ti BBC beere lọwọ rẹ boya awọn agbani pa lo kọlu Apostle Suleman, alukoro ọlọpaa naa sọ pe oun ko tii le fidirẹ mulẹ titi iwadii yoo fi iru awọn ti wọn jẹ han.

Ọwọ́ tẹ ọ̀kan lára agbébọn tó kọlù mí àmọ́ ọlọ́pàá pa á lójú ẹsẹ̀ - Apostle Sulaiman

APOSTLE SULEMAN

Oríṣun àwòrán, @APOSTLESULEMAN

Ọrọ miran ti n foju han lori isẹlẹ ikọlu ati ipaniyan tawọn agbebọn kan se si ojisẹ Ọlọrun Apostle Johnson Sulaiman ni irọlẹ Ọjọ Ẹti.

Iroyin miran to tun jade sita lori isẹlẹ naa ni pe ọwọ tẹ ọkan lara awọn agbebọn to se ikọlu si ojisẹ Ọlọrun naa.

Gẹgẹ bi Apostle Johnson Sulaiman ti kede loju opo Twitter rẹ lẹyin ti ikọlu naa waye, o ni se ni wọn fa afurasi naa le awọn ọlọpaa lọwọ.

Amọ ojisẹ lọrun naa ti wa n gbarata pe se ni awọn ọlọpa pa afurasi agbegbọn naa loju ẹsẹ, eyi to ya oun lẹnu.

Awọn agbebọn to kọlu mi kii se ajinigbe, wọn mọọmọ fẹ pa mi ni - Apostle Sulaiman

Ninu fidio kan to ju soju opo Twitter rẹ naa, lo ti se afihan oju afurasi agbebọn ti ọwọ tẹ naa, ẹni ti ẹjẹ wa lara asọ rẹ.

“Ki lo de tẹ fi pa loju ẹsẹ, ki lo de, ta lẹ fẹ bo ni asiri, tẹ fi pa agbebọn naa?”

Awọn ibeere yii ni Apostle Johnson Sulaiman n ju soju opo ayelujara rẹ lori lhun tawọn ọlọpaa se ọhun.

O wa yan pe afurasi naa kii se ajinigbe rara bikose apaayan to mọọmọ wa dena de oun lati pa oun atawọn to kọwọrin pẹlu ohun

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

Ki lo ti waye saaju lori isẹlẹ naa?

Agbébọn kọlu Apostle Sulaiman, èèyàn méje kú

Apostle Johnson Sulaiman ati ọkọ ti ibọn ba

Oríṣun àwòrán, Twitter

Awọn gende agbebọn ti kọlu oludasilẹ ijọ Omega Fire Ministries, Apostle Johnson Sulaiman atawọn eeyan to kọwọrin tẹle lẹyin nirọlẹ ọjọ Ẹti.

Lasiko isẹlẹ naa, ti eeyan meje lara awọn alatilẹyin ati ẹsọ rẹ naa lo jade laye.

Lara awọn to ku la ti ri osisẹ ọlọpaa mta ati awọn alatilẹyin Apostle Sulaiman mẹrin ti wọn wa ninu ọkọ to kọwọrin pẹlu rẹ.

Ọpopona ilu Auchi si Benin nipinlẹ Edo si la gbọ pe isẹlẹ naa ti waye.

Iroyin ni awọn agbebọn naa kọlu Apostle Sulaiman lasiko to n ti irinajo bọ lati orilẹede Tanzania.

Bẹẹ ni wọn yọ ibọn si ni agbegbe Sabongida nibi to ti pa aala pẹlu ilu Warake, to si fẹ wọ ilu Auchi.

Bi o tilẹ jẹ pe awọn agbebọn naa da ibọn bo awọn ọkọ rẹ, to fi mọ eyi ti oun gan wa ninu rẹ amọ, ori ko ojisẹ Ọlọrun naa yọ.

Wn n gbe awọn to fara pa

Oríṣun àwòrán, Twitter

Iyawo mi atawọn ọmọ wa ninu ọkọ pẹlu mi nigba ti agbebọn kọlu wa - Sulaiman

Nigba to n fidi isẹlẹ naa mulẹ ninu fidio kan to sare se lẹyin isẹlẹ naa, Apostle Sulaiman ni ori lo ko oun yọ ti wọn ko fi ri oun pa.

O ni lootọ lawọn agbebọn naa kọlu mọto oun, ti wọn si doju ibọn kọ oun, bẹẹ ni aya oun atawọn ọmọ wa ninu awọn ọkọ to kọwọrin pẹlu oun.

“Wọn pa ọlọpaa atawọn to wa lẹyin mi, eeyan meje lo ku lapapọ ninu isẹlẹ naa.

Awọn eeyan to sisẹ ibi yii n reti pe ki n darukọ awọn, ki wọn le jade wa sọ pe ko ri bẹẹ, amọ n ko ni se bẹẹ.

Ootọ ọrọ to wa nibẹ ni pe ẹ ko le ri mi pa o nitori ọwọ Ọlrun ni mi mi wa, ojisẹ Ọlrun ni mi.”

Lara awọn eeyan to ku ninu isẹlẹ naa ni awakọ Sulaiman wa, ti iroyin agbọsọgbanu yii si ti gba ori ayelujara kan, tawọn eeyan si ti n sọrọ nipa rẹ.

Ta ni Apostle Johnson Sulaiman ti agbebọn kọlu?

Gbajugbaja ojisẹ Ọlọrun lorilẹede Naijiria ni Apostle Johnson Sulaiman, ti okiki rẹ si kan kari aye.

Orukọ ile ijọ̀sin rẹ to da silẹ ldun 2004 ni Omega Fire Ministries International, ti olu ijọ naa si wa nilu Auchi nipinlẹ Edo

Ọjọ Kẹrinlelogun osu Kẹta ọdun 1971 ni wọn bi ojisẹ Ọlọrun naa nipinlẹ Edo.

O maa n se iwaasu ọrọ Ọlọrun kaakiri agbaye ati lawọn ori mohunmaworan.

Ọ́pọlọpọ ẹka ijọba rẹ lo wa kaakiri, to fi mọ ilu Abuja.

Apostle Johnson Sulaiman si wa lara awọn ojisẹ Ọlọrun ni orilẹede Naijiria ti awuyewuye maa n waye lori wọn lọpọ igba.

Awọn awuyewuye to si maa n waye lori ojisẹ lọrun yii lo nii se pẹlu ọrọ owo ati obinrin.