Ọlọ́run ní kò sí iṣẹ́ tí màá ṣe tí yòó là mí àfi ajíhìnrere - Ojo Ade

Àkọlé fídíò, Ojo Ade: Ìṣẹ́ àti òṣì bá mi fínra, mo fọdún mẹ́wàá ṣe àìsàn láìsí ẹni tó mọ̀
Ọlọ́run ní kò sí iṣẹ́ tí màá ṣe tí yòó là mí àfi ajíhìnrere - Ojo Ade

Ìṣẹ́ àti òṣì bá mi fínra, tí mo sì fọdún mẹ́wàá ṣe àìsàn láìsí ẹni tó mọ̀ - Ajíhìnrere Ojo Ade

Ojo Ade

Oríṣun àwòrán, Evangelist Ojo Ade

Ogbontarigi akọrin ẹmi, Ajihinrere Ojo Ade, ti sọ pe lati kekere ni oun ti ni imisi ati ẹbun orin kikọ.

Ninu ifọrọwanilẹnuwo kan pẹlu BBC Yoruba, Ajihinrere Ojo Ade ni oun ko kọ iṣẹ orin lọdọ ẹnikẹni, o ni ṣugbọn gẹgẹ bi ọmọde, ibi ti wọn ba ti n kọrin ni oun maa n wa.

 O ni n ṣe ni oun ma n jokoo ti awọn ẹgbẹ akọrin kan ti wọn n pe ni ‘Monbo’ ni ilu abinibi rẹ, Ikeji-Ile nipinlẹ Osun, lati woran bi wọn ṣe n se igbaradi orin wọn, gẹgẹ bi ọmọde.

Ojo Ade gbajumọ pupọ fun tita ẹ̀dà duuru kan ti wọn n pe ni ‘accordion’, eyi to fi ma n kọ orin rẹ pẹlu.

Aadọta Naira ni ẹgbọn mi ra accordion ti mo kọ́kọ́ lò - Ojo Ade

Accordion naa, ni Ajihinrere Ade sọ pe ẹgbọn oun kan lo kọkọ ra a fun oun.

O ni “ẹgbọn mi kan wa ti mo maa n ṣere lọ ile wọn, ọrẹ wọn kan ra accordion kekere, nitori rẹ ni mo ṣe maa n lọ si ibẹ lojojumọ tori wọn jẹ ki n fi ṣere.

Ni ọjọ kan, Ojo Ade beere lọwọ ẹgbọn rẹ ọhun pe ṣe o le ba oun naa ra accordion.

Ẹgbọn rẹ ọhun si ra irinṣẹ orin ti a n wi yi fun, eyi to jẹ irinṣẹ orin rẹ akọkọ.

Ni gbogbo asiko naa, Ojo Ade ko tii mọ pe iṣẹ orin ihinrere kikọ ni oun yoo ṣe gbẹhin.

“Aadọta Naira nigba yẹn l’ọun ni wọn bami ra accordion naa. Bi igba ti wọn si yọnda gbogbo aye fun mi ni, inu mi dun, kii ṣe pe mo ti mọ tẹ naa ṣugbọn mo tẹ dele ni.”

Bayii lo ṣe bẹrẹ iṣẹ orin kikọ, to si gbe rẹkọọdu orin rẹ akọkọ jade ni ọdun 1981, ati ikeji ni ọdun 1963.

"Ipọnju ati oṣi ba mi finra gan-an"

Agba akọrin naa sọ pe olori ohun to jẹ iṣoro oun ju ni aini nigba ti oun bẹrẹ iṣẹ orin ẹmi kikọ.

O ṣalaye pe ọna di, deebi pe atijẹ atimu di inira fun oun.

Ẹwẹ, Ojo Ade sọ pe Ọlọrun tun didi ba oun sọrọ lati ibẹrẹ pe ko si iṣẹ ọwọ ti oun le ṣe rere ninu rẹ, biko ṣe iṣẹ ihinrere.

“Asiko ti mo ni nnkan nira yẹn mi o duro tori mo n kọrin fun Baba Abiara.”

O ni ọjọ kan, oun ni ki Wolii Abiara gbadura fun oun, ninu adura naa ni wọn ti sọ fun oun pe ko si iṣẹ ti oun le ṣe to le la oun, a fi ki oun ṣe iṣẹ Oluwa.

“Baba sọ pe iṣẹ ti Ọlọrun gbe fun mi ju pe a n kọrin nikan. Lẹyin yẹn ni iṣẹ iranṣẹ ti ṣọọṣi bẹrẹ, amọ kii ṣe pe mo n joko si ṣọọṣi naa, iṣẹ iyinrere kaakiri agbaye naa ni a n ba kiri.”

Ojo Ade

"Ọdun mẹwaa ni mo fi ṣe aisan, ṣugbọn ko si ẹni to mọ, mo dẹ n ṣe isọji kiri"

Yatọ si iṣoro airi owo naa, Ojo Ade sọ pe aisan kan tun kọlu oun debi pe niṣe ni oun ma n gbe baagi oogun kiri bi ẹni to n ta oogun oyinbo.

“Ọdun mẹwaa ni mo fi ṣe aisan, ṣugbọn ko si ẹni to mọ, mo dẹ n ṣe isọji kiri ṣugbọn emi naa mọ pe kosi alaafia laagọ ara mi.

“Ti mo ba fẹ rin irinajo lọ si isọji, awọn ọmọ ko gbudọ gbagbe apo oogun, afi bi ẹni ti o n ta oogun.”

Lara awọn idojukọ ati ipenija ti akọrin ẹmi naa ni oun tun ni ni pe wọn ti po majele mu fun oun ri, ti oun si ti ni awọn ijamba ojupopo, amọ Ọlọrun gbe oun bori iṣoro.

Bakan naa lo ṣalaye pe oun ṣe aisan nla kan ni ọdun 2020, to si jẹ ọpẹlọpẹ Ọlọrun ni ko jẹ ki oun ku.

'Inu adura ni mo ti ṣaba ma n gba imisi orin'

Ajihinrere Ojo Ade sọ fun BBC pe orin 'Ojo ola mi a dara' ni o sọ oun di olokiki.

O ṣalaye pe lasiko ti nkan nira fun oun, ni oun gba imisi orin naa, to si jẹ apẹẹrẹ bi aye oun ṣe ri ni asiko naa.

" Ni ọjọ kan mo n lọ ni adugbo kan ni Molete ni ilu Ibadan, ni bata kan ṣoṣo ti mo ni bajẹ laarin ọna ni ọsan gangan.

" Itiju nla ni lọjọ yẹn... ohun yẹn kan sọ fun mi kẹlẹ pe 'ọmọ, o lọjọ ọla ti o dara'."

O ni misi yẹn lowa jẹ ki oun kọ orin pe bi ọjọ oni ba koro, mo ni ọjọ ọla ti o dara.

Ojo Ade

Awọn nkan mii to yẹ ki o mọ nipa Ajihinrere Ojo Ade

Ọdun 1959 ni wọn bi ni ilu kan ti wọn n pe ni Ikeji-Ile, nipinlẹ Osun.

O lọ si ile ẹkọ alakọbẹrẹ ni ilu naa. Lẹyin rẹ si lo wa si ilu Eko lati kọ iṣẹ bi wọn ṣe n tun nkan elo inu ile to n lo ina ṣe.

O gbajumọ fun awọn orin bii:

Oja abiamo

Ojo ola mi a dara

Satani ko sinmi

Oja Okunkun

Ta lo le gba wa

Sun m'Ọlọrun ati bẹẹ bẹẹ lọ