Aderoju Yekini: Barrister sọ fún mi lójú àlá kó tó kú pé ká tẹ̀síwájú pẹ̀lú báǹdì òun

Àkọlé fídíò, Aderoju Yekini: Barrister sọ fún mi lójú àlá kó tó kú pé ká tẹ̀síwájú pẹ̀lú báǹdì òun

Aderoju Yekini: Barrister sọ fún mi lójú àlá kó tó kú pé ká tẹ̀síwájú pẹ̀lú báǹdì òun

Odu, ti kii se aimọ fun oloko lagbo orin kikọ ati ere Fuji lorilẹede Naijiria ti nilẹ Yoruba lapapọ ni Sikiru Ayinde Barrister jẹ.

Amọ kokoro ko jẹ kawọn ololufẹ gbajumọ akọrin yii gbadun obi rẹ to gbo kaka lagbole orin kikọ nitori iku ja ẹmi rẹ pati mọ wọn lọwọ lẹni ọdun mejilelọgọta.

Ọjọ Kẹrindinlogun osu Kẹjila ọdun 2010 ni Barrister jade laye lẹyin to ti fi ọdun marundinlogoji kọrin Fuji.

Bi o tilẹ jẹ pe onirese rẹ ko fin igba mọ amọ eyi to ti fin silẹ, ko le parun, tawọn ololufẹ rẹ si nifẹ rẹ loju aye ati lẹyin iku rẹ.

Ọna lati mu iranti Barrister wa sookan aya awn ololufẹ rẹ lo mu ki BBC Yoruba kan si ọkan lara awọn onilu to gbajugbaja lẹyin Barrister nigba to wa loke eepẹ.

Ọpọ igba si ni Barrister maa n kọrrin ki ọkunrin onilu naa bii ..."Aderoju Onilu mi, o ya oo..."

Onilu Barrister

Oluwarẹ rẹ ni Aderoju Ayanwale Yekinni, ti ọpọ eeyan mọ si Aderoju onilu Barrister.

Aderoju si ba BBC Yoruba sọrọ nipa ajọsepọ rẹ pẹlu Barrister, bi agba akọrin naa se jade laye ati ohun to waye lẹyin iku oloogbe naa.

Mo ti lu ilu fawọn iya ibeji jo, ji were, lu ilu fun onitiata, ki n to pade Barrister - Aderoju Yekinni

Nigba to n salaye fun BBC nipa igbesi aye rẹ, Aderoju ni ọmọ bibi ilu Ayetoro ni agbegbe Ariwa Yewa, nipinlẹ Ogun ni oun.

O ni ọmọ ọdun mẹrin abọ si marun ni oun ti n lu ilu kaakiri igboro.

Koda, o ni oun ti lu ilu kaakiri ọja lati gba owo, oun si tun ti lu ilu fawọn iya ibeji to n jo kiri lati se agbe gba owo.

Bakan naa lo ni oun ti lu ilu ri fawọn alaboyun, awọn onitiata, oun si ti ji were fawọn alaawẹ ri, ki oun to de ọdọ Sikiru Ayinde Barrister.

"Akoko adun ati ikoro ni mo la kọja nigba ti mo wa pẹlu Barrister amọ akoko adun ju ti ikoro lọ"

Aderoju salaye pe oun la akoko adun ati ikoro kọja lasiko ti oun dara pọ mọ ẹgbẹ akọrin Sikiru Ayinde Barrister.

Amọ o ni oun dupẹ pe akoko adun ju ti isoro lọ fun oun lasiko ti oloogbe naa wa laye.

Onilu naa wa se apejuwe rẹ pẹlu Barrister ọga rẹ bii eyi to da mọran, ti ko si si ibi ti ko le ran oun lọ.

O wa se apejuwe Barrister bii eeyan rere, eeyan daadaa, abiwa pẹlẹ, onisuuru, ẹni ti kii fi oju pa eeyan rẹ, to si n se fun tẹbi tara.

Onilu Barrister

"Mo si ba Barrister sọrọ ni ọjọ kẹta sigba to ku, iku Barrister ba mi nibi ti ko dara, iku rẹ si n bẹ diẹ diẹ lara mi"

Aderoju, ẹni to salaye bi gbajumọ akọrin Fuji naa se ku lọdun 2010 salaye pe awọn mejeeji si dijọ sọrọ lori foonu, ko to di pe o jade laye lẹyin ọjọ kẹta.

"Nigba ti wọn lọ gba itọju loke okun, mo pe wọn ni ọjọ kẹrinla, osu kejila ọdun 2010, wọn si sọ fun mi pe ara awọn ti n ya.

Wọn beere aya mi atawọn ọmọ mi, ti wọn si ni awọn yoo pada wa sile lọjọ kẹẹdogun osu osu Kinni ọdun 2011.

Iku Barrister ba mi nibi ti ko dara, bi mo se gbọ pe wọn ku lẹyin ọjọ kẹta ta sọrọ, koda, iku wọn si wa lara mi diẹ diẹ.

Ko tiẹ ye mi bi mo se de Oshodi lati Iyana Ipaja, bi mo rin ni, bi mo wọ mọto ni, n ko tiẹ mọ, mo sa mọ pe mo de Oshodi."

"Barrister ni ki n tọju ilu mi ki oun fi de tori oun ti se 'Composition' orin to le ṣe awo orin mẹjọ lasiko toun wa lori aisan"

Aderoju Onilu Barrister tẹsiwaju pe lasiko ti akọrin Fuji naa wa loke okun nibi to ti lọ gba itọju, o sọ fun oun pe ki oun tọju ilu oun lati se awo orin tuntun.

"Barrister ni oun ti pese ọpọ orin silẹ to le se awo orin mẹjọ ti oun ba de, to si ni ki n tọju ilu mi silẹ daadaa.

Ọjọ kẹta lẹyin ta sọrọ, ni mo gbọ pe Barrister ku, o ba mi ninu jẹ pupọ."

"Barrister ba mi sọrọ loju ala ko to ku pe ki n ma jẹ ki ẹgbẹ orin oun tu tori pe oun ti ku"

Onilu Barrister wa sisọ loju rẹ pe Sikiru Ayinde Barrister ti mọ pe oun yoo ku amọ ti ko fẹ ki ẹgbẹ orin rẹ tuka lẹyin to ba ku tan.

"Ki Barrister to ku, ni mo la ala, mo ri to joko si ẹgbẹ kan, mo si lọ ba pe ọga wa, ki lo de.

O si sọ fun mi pe 'ma tori pe mo ti ku, ki bandi mi lọ silẹ, mo si fẹ ko tẹsiwaju'.

Aderoju fikun pe ki wọn to gbe oku Barrister de lati oke okun, ni oun ti yara pe awọn ọmọ ẹgbẹ orin yoku jọ.

O ni awọn si se ipada lori bi ẹgbẹ naa yoo se tẹsiwaju lẹyin iku Barrister, ti gbogbo wọn si fara mọ pe awọn yoo maa ba orin kikọ naa lọ.

"Akukọ gagara ko fẹ ki kekere wa kọ laarin awọn agba olorin ni ẹgbẹ orin Barrister Memorial Band fi tuka"

Nigba to n dahun ibeere lori ibi ti ẹgbẹ olorin Barrister wa de duro bayii lẹyin ọdun mejila ti afinju olorin Fuji naa ti di ara ilẹ.

Aderoju ni awọn tiraka lati tẹsiwaju nidi kikọ orin Fuji ti Barrister da silẹ amọ isoro ti wọn gbe ti awọn ti pọ ju.

O ni Barrister Memorial Band ni awọn yi orukọ ẹgbẹ elere naa pada si lẹyin iku ọga awọn.

"Adiẹ gagara ko fẹ ki kekere kọ ninu awọn elere giga to yi wa ka.

Awọn ti ko fẹ ki Bandi Barrister tẹsiwaju lo pọ ninu awọn elere giga to yi wa ka.

A gbe, gbe, gbe pe ka maa tẹsiwaju pẹlu ẹgbẹ akọrin Fuji Barrister Memorial Band amọ ko jọ.

Nigba to si ti fẹ la nnkan mii lọ, a yaa gbe ju silẹ."

"Ko si ẹni to ni ẹbun orin kikọ bii ti Barrister, a kii se practice, ka to se awo orin"

Gbajumọ akọrin lẹyin Barrister naa wa koro oju si ero awn eeyan kan to ni oogun tabi awure ni Barrister n lo lati fi kọrin.

Awọn eeyan naa lo ni wọn n sọ kiri pe Barrister ko ni ẹbun orin lati ọrun wa, o kan n dọgbọn si ni.

Amọ aderoju ni irọ ni wọn n pa pe Barrister ko ni ẹbun orin tabi pe ko ni imisi orin kikọ.

"N ko tii ri ẹni ti lọrun fun ni ẹbun orin kikọ to to Barrister, a ko si le fẹ se rẹkọọdu orin, ki ọga mi sọ pe ka kọkọ se Practice.

A kan maa lọ si studio ni, a si se rẹkọọdu jade , ti yoo si dun pupọ."

"Iwe, Biro ati ẹrọ agbohunsilẹ maa n wa nigberi Barrister to ba sun ni"

Aderoju fikun pe oniruuru ọna ni Barrister fi maa n ni imisi orin kikọ, to fi mọ oju ala, eyi to fidi rẹ mulẹ pe lati ọrun wa lo ti ni imisi orin kikọ.

"Nibi ti emi mọ wọn de, ti ọga mi ba fẹ sun, iwe akọsilẹ, gege ikọwe ati ẹrọ agbohunsilẹ lo maa wa ni igberi wọn.

Idi ni pe ti orin ba wa lati oju ala, wọn yoo sare kọ silẹ, wọn maa kọ orin yẹn sinu tape ẹrọ agboohunsilẹ.

Eyi ko si ni jẹ ki wọn gbagbe orin to wa ni asiko yẹn.

Mo tun wa se iwadii lọdọ awọn eeyan to ti ba wọn sisẹ ki emi to de pe se wọn kii se Practice, ki wọn to gbe orin jade tẹlẹ, ti wọn si ni bẹẹ ni.

Eyi lẹ maa fi mọ pe ẹbun ti Ọlọrun fun wọn ni orin kikọ."