Wo bí ọmọ ọdún mẹ́ta ṣé móríbọ́ nínú ikọlù agbébọn kan tó pa ọmọde 23 nílé ẹkọ́ alákọ̀bẹ̀rẹ̀

Ko tii daju bi ọmọ ọdun mẹta Emmy ṣe moribọ lọwọ ikọlu ti agbebọn kan ṣe si ile ẹkọ alakọbẹrẹ rẹ nibi ti oun ati awọn akẹgbẹ rẹ ti n kọ nipa aworan yiya ati ọrọ kikọ.
Ni nkan bi ago mẹwa owurọ lawọn olukọ awọn ọmọde yi fi aworan ranṣẹ si awọn obi wọn lati ṣafihan bi wọn ṣe n kọṣẹ.
Wakati meji lẹyin iṣẹlẹ yi ni awọn ọmọ naa kagbako iku nigba ti ọlọpaa kan to ti fẹyinti nidi iṣẹ yawọ aaye ti wọn wa to si pa awọn ọmọ naa loju orun.
Wn ba Emmy nibi to ka si lẹgbẹ oku ọkan lara awọn akẹgbẹ rẹ gẹgẹ bi iya iya rẹ ṣe sọ fakọroyin BBC.
''Ko mọ nkan to n ṣẹlẹ nigba ti wọn yoo fi ri.Niṣe lo ro pe awọn ọrẹ rẹ ti sunlọ ni''
Somsak Srithing sọ fun akọroyin wa pe ọlọpaa kan to ri nibẹ da aṣ bo loju to si gbe kuro nibi ti ẹjẹ awọn akẹgbẹ rẹ wa.
Èèyàn 37 ní ọlọ́pàá tẹ́lẹ̀ pa nílé ìtọ́jú ọmọdé, tó fi mọ́ òbí àti olùkọ́ olóyún oṣù mẹ́jọ - Ọlọ́pàá

Ẹkunrẹrẹ iroyin ti n foju han nipa bawọn ọmọde ti ko din ni mẹtalelogun se ku nile itọju ọmọde to wa lorilẹede Thailand.
Ọkùnrin kan, Panya Kamrab, tii se ọlọ́pàá tẹ́lẹ̀ rí si lo wọ ibudo itọju ọmọde naa, to si bẹrẹ si ni yinbọn mọ wọn, eyi to gbẹ̀mí àwọn ọmọdé mẹ́tàlélógún.
Lẹyin o rẹyin isẹlẹ naa, àwọn ènìyàn tí kò dín ní mẹ́tàdínlógójì la salaisi.
Apaayan to pa awọn ọmọde tun pa aya, awọn ọmọ rẹ, ko to pa ara rẹ - Ọlọpaa Thailand
Àwọn ọmọdé tó máa ń lọ sí ilé ìtọ́jú àwọn ọmọdé náà lé ní àádọ́rùn-ún.
Sùgbọ́n ojú ọjọ́ tí kò dára lẹ́nu ọjọ́ mẹ́ta yìí àti ọkọ̀ bọ́ọ̀sì tó máa ń gbé àwọn ènìyàn, ló ṣokùnfà ìdí tí àwọn ọmọdé tó wà níbẹ̀ kò ṣe ju mẹ́rìnlélógún lọ.
Ọmọ kan nínú àwọn mẹ́rìnlélógún náà ló móríbọ́ nínú ìṣẹ̀lẹ̀ ìpànìyàn yìí.
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ni Panya Kamrab, to ṣekúpa àwọn ọmọdé wọ̀nyí pa ìyàwó àti ọmọ ìyàwó rẹ̀, tó sì tún pa ara rẹ̀ náà lẹ́yìn tó pa àwọn ọmọ náà tán.
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní àwọn kò mọ ìdí tí Kamrab fi ṣe ìkọlù náà àmọ́ inú oṣù Kẹfà ni Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ti le kúrò lenu iṣẹ́ fún lílo egbògi olóró.

Iya agba daku rangbọndan nigba to gbọ iku ọmọ ọmọ rẹ
Ìyá àgbà kan, ẹni ọdún mẹ́rìnlélọ́gọ́ta, Duangphan Patphaothanum, salaye pe nígbà tí ohun kọ́kọ́ gbọ́ ìròyìn isẹlẹ náà, n ṣe ni òun dákú lọ gbọrangandan.
Ọmọ ọdún mẹ́ta ni Pattarawut, tó jẹ́ ọmọọmọ Patphaothanum, to wà lára àwọn ọmọ mẹ́tàlélógún tó pàdánù ẹ̀mí wọn níbi ìkọlù naa.
Iya agba naa si wà lára àwọn òbí àti ẹbí àwọn ọmọ náà tí wọ́n péjọ síwájú ọgbà Nong Bua Lamphua, láti kẹ́dùn ikú àwọn ọmọ wọn.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn òbí mìíràn tó wà níbẹ̀ ní, ó jẹ́ ohun ìbànújẹ́ fún àwọn láti péjọ síwájú ọgbà náà àti Iléeṣẹ́ Ọlọ́pàá fún òkú àwọn ọmọ wọn.
"Apaayan naa pa obi kan ati olukọ oloyun osu mẹjọ ni abawọle ibudo itọju ọmọde naa"
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní, Kamrab yawọ ọgbà náà tó sì kọ́kọ́ pa olùkọ́ àti òbí kan tó bá níta, kó tó wọ inú yàrá tí àwọn ọmọ náà wà lọ.
Olùkọ́ tó pa náà ni wọ́n ní ó wà nínú oyún oṣù mẹ́jọ.
Lẹ́yìn náà ló wọ inú yàrá ibi tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà wà, tó sì bẹ̀rẹ̀ sí ní pa àwọn ọmọ náà.
Wọ́n ní Kamrab ti ṣáájú yọjú sí ilé ẹjọ́ lórí ìgbẹ́jọ́ lílo egbògi olóró tó ń kojú, kó tó lọ ṣe ìkọlù náà.
Ní òwúrọ̀ yìí ló yẹ kí adájọ́ ṣe ìdájọ́ rẹ̀.















