Àwọn onímọ̀ ọrọ̀ ajé bu ẹnu àtẹ́ lu àbá ìsúná 2023 tí Buhari gbé ka ìwájú àwọn aṣòfin

Bá Ààrẹ Buhari ṣe ń gbé àbá ìsúná 2023 kalẹ̀

Ní àná ọjọ́ Ẹtì ọjọ́ Keje, oṣù Kẹwàá ọdún 2022 ní Ààrẹ Muhammadu Buhari tẹ pẹpẹ àbá ìsúná ọdún 2023 síwájú ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àpapọ̀.

Àpapọ̀ owó ìsúná náà jẹ́ ogún tírílíọ̀nù àti bílíọ̀nù mọ́kànléláàdọ́ta náírà (₦20.51trn) èyí tó fi owó tó lé ní tírílíọ̀nù méjì náírà lé sí ìsúná ọdún 2022.

Orí àádọ́rin dọ́là fún àgbá epo rọ̀bì kan àti pé tí a bá le pèsè mílíọ̀nù kan àti ẹgbẹ̀rún mọ́kàndínláàdọ́rin epo rọ̀bì fún títà ní wọ́n gbé àbá ìsúná náà lé lórí.

 Tírílíọ̀nù 11.9 náírà ni èròńgbà wí pé yóò jẹ́ owó tíi yóò wọlé fún ìjọba nínú owó tí wọ́n fẹ́ ná ọ̀hún pẹ̀lú ìrètí pé wọn yóò yá owó yòókù láti lè mú kí àbá ìsúná náà jẹ́ mímúṣẹ.

Ìjọba ní tírílíọ̀nù mẹ́fa náírà ni àwọn yà sọ́tọ̀ láti fi san èlé orí owó tí wọ́n ya èyí tó ṣàfihàn pé ìpèníjà ńlá ń bọ̀ fún Nàìjíríà nídìí owó níná lọdún 2023.

Àbá ìsúná ti wá ṣokùnfà awuyewuye láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Nàìjíríà pàápàá pẹ̀lú èròńgbà ìjọba láti tún yá owó láti fi kún àbá ìsúná náà.

Àbá ìsúná 2023 kò wúlò fún ọjọ́ ọ̀la Nàìjíríà – NACCIMA

Adarí àpapọ̀ fún ẹgbẹ́ àwọn olókoòwò, ilé iṣẹ́, ìwakùsà àti ètò ọ̀gbìn Nàìjíríà, NACCIMA, Olusola Obadimu júwe àbá ìsúná 2023 ti Ààrẹ Buhari gbé síwájú ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin bí i èyí tí kò ní àǹfàní tí yóò ṣe fún àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè yìí.

Obadimu ní ìjọba ń gbèrò láti yá ₦8.4trn tí wọn yóò sì tún fi ₦6.3trn san gbèsè padà nínú rẹ̀.

Ó ní ìgbèsẹ́ yìí kò dára tó rárá nítorí ní ṣe ló dàbí pé ojú kan náà ni orílẹ̀ èdè yìí ti ń fò tí wọ́n sì ń bà síbẹ̀ bákan náà nítorí ìjọba kàn ń gba gbèsè láti fi san gbèsè ni.

Ó fi kun pé gbogbo àbá ìsúná àtẹ̀yìnwá náà kò so èso rere fún àwọn ọmọ Nàìjíríà.

Ó tẹ̀síwájú pé kókó ohun tí òun rí níbi àbá ìsúná náà kò kọjá ọ̀rọ̀ ètò ìdìbò tó fẹ́ wáyé ní ọdún tó ń bọ̀.

Obadimu ní àsìkò ti tó fún ìjọba láti yé gbáralé owó epo rọ̀bì nìkan mọ́ kí wọ́n wá ọ̀nà láti máa fi pa owó láti ẹ̀ka mìíràn kí yíya owó láti fi ṣe àwọn àkànṣe iṣẹ́ lé dínkù jọjọ.

Ààrẹ Buhari ń bá àwọn ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin sọ̀rọ̀

Oríṣun àwòrán, Tolani Alli

Yíyá owó gọbọi láti fi kún àbá ìsúná kò le mú ìdàgbàsókè bá Nàìjíríà – Ekpo

Nínú ọ̀rọ̀ tirẹ̀, onímọ̀ nípa ọrọ̀ ajé kan tó tún ti fìgbà kan rí jẹ́ gíwá àgbà ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì ìlú Uyo, Ọ̀jọ̀gbọ́n Akpan Ekpo ní ohun tó léwú ni fún Nàìjíríà láti máa yá owó láti fi kún àbá ìsúná.

Ekpo ní ọdọọdún ni gbèsè ọrùn Nàìjíríà ń pọ̀ sí bẹ́ẹ̀ náà sì ni iye tí wọ́n ma ma sàn láti fi dá gbèsè náà padà yóò máa pọ̀ si.

Ó ní yíyá owó láti máa fi ṣe àwọn nǹkan pẹ́ pẹ̀ pẹ́ máa ṣe àkóbá ńlá fún orílẹ̀ èdè yìí àti pé ìfàsẹ́yìn ló ma mú bá orílẹ̀ èdè.

Ọ̀jọ̀gbọ́n Hassan Oaikhenan ti ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì Benin ní tirẹ̀ ní ó ti fojú hàn pé àbá ìsúná 2023 kò ní ìwúlò kankan nítorí orí gbèsè ni ìjọba gbe lé látilẹ̀.

Oaikhenan ní ìjọba kàn fẹ́ ṣe àmúṣẹ gbígbé àbá ìsúná kalẹ̀ láìsí ipa rere kankan tó ma mú bá àwọn ará ìlú.

A tiraka láti mú Nàíjíríà gòkè àgbà, àmọ́ àwọn afẹ̀míṣòfò ba ǹkan jẹ́ - Buhari

Aarẹ Muhammadu Buhari

Oríṣun àwòrán, Twitter

Aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari ti ni ijọba oun gbaradi lati koju eto aabo to dẹnukọlẹ.

Buhari sọ eyi nibi ayẹyẹ ikẹkọjade awọn ikọ omoogun 69th Regular Course Cadets tile ẹkọsẹ ologun Nigerian Defence Academy (NDA) ni ilu Kaduna.

O kere tan, awọn ọmọogun to le ni igba lo kẹkọ jade, ti wọn si darapọ mọ ikọ ọmọogun orilẹede Naijiria.

Bí a ṣe gbáradì rèé pé kí ọrọ̀ ajé rú gẹ́gẹ́ sókè nígbà tí a dé ìjọba àmọ́...

Aworan

Oríṣun àwòrán, Twitter/Buhari

Ninu ọrọ rẹ, Aarẹ Buhari ni igbiyanju awọn agbesunmọmi ati awọn agbatẹru wọn ni lati ba gbogbo eto ti ijọba ti ṣe lati ri pe ọrọ̀ aje Naijiria ko dẹnukọlẹ jẹ.

‘’Bakan naa ni awọn agbesunmọmi naa tiraka lati ba eto ati ilana lati mu iwuri ba ikọ ọmọogun Naijiria jẹ.’’

Aarẹ ni wẹrẹ ti awọn de ijọba ni awọn ti gbe ilana kalẹ lati mu ibugbooro ba awọn ileeṣẹ ati ohun ini ijọba Naijiria.

‘’Eto irina to fi mọ oju irin, oju popo, ori omi to fi mo ofurufu ati atunto ẹka eto ina ọba’’

‘’Bakan naa ni a tun mu atunto ba eto ile gbigbe, ipese omi ati eto ilera ni Naijiria.

‘’Amo iyalẹnu lo jẹ wi pe ibi ti awọn agbesunmọmi kọkọ ṣekọlu si ni awọn ileeṣẹ ijọba to yẹ ko mu igbayegbadun ba awọn ọmọ Naijiria.’’

‘’Akọkọ ni oju irin, oju pipo ati awọn ina ọba tuntun ti ijọba ṣe kaakiri Naijiria.’’

Mo fi da awọn eniyan loju pe eto idibo 2023 yoo lọ ni irọwọrọṣẹ- Buhari

Aworan

Oríṣun àwòrán, Twitter/Buhari

Buhari ni ki awọn eniyan ma gbagbe pe nigba ti wọn de iṣejọba, nise ni awọn agbesunmọmi n ju ado oloro si awọn ilu lakọlakọ amọ ọrọ ti yipada bayii.

Bakan naa ni aarẹ Buhari ni oun yoo ri pe eto idibo ọdun 2023 lọ ni irọwọrọṣẹ lai si rogbodiyan ni agbegbe kankan.

O tun fikun un pe oun yoo sa ipa oun lati ri pe ko si magomago ni idibo ọdun 2023 naa

Aarẹ wa fi n da awọn eniyan loju wi pe opin yoo de ba igbesunmọmi ni gbogbo agbegbe lorilẹede Naijiria.

Aarẹ Buhari wa kesi ileeṣẹ ọmọogun Naijiria lati mu iṣẹ wọn lọkunkundun ki wọn si da abo bo awọn ileeṣẹ ijọba lorilẹede Niajiria.

Bakan naa ni aarẹ ṣalaye awọn agbekalẹ ijọba lati mu idagbasoke ba eto aabo kaakiri Naijiria, ati ibugbooro ba ẹka ileeṣẹ ọmọogun Naijiria.