Ọkùnrin tó pa ìyá rẹ̀ jẹ́wọ́ fún mọ̀lẹ́bí lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ méjì
‘Ìyá mi pè mí lọ́mọ alè ni mo ṣe fun lọ́rùn pa àmọ́ ẹ̀rí ọkàn kò jẹ́ ki n gbádùn’

Oríṣun àwòrán, SCREENSHOT
Ilé ẹjọ́ Májísíréètì ti ìlú Akure, tíí ṣe olú ìlú ìpínlẹ̀ Ondo, ti ju Tope Momoh, ẹni ọdún méjìdínlógún, sí àhámọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n Olokuta.
Ẹ̀sùn wí pé Tope Momoh fún ìyá rẹ̀, Stella Momoh lọ́rùn pa, ló ń kojú níwájú ilé ẹjọ́ náà.
Ní ọjọ́ Kẹfà, oṣù Keje ni Tope Momoh fún ìyá rẹ̀ ní ọrùn pa nígbà tí èdè àìyedè wáyé láàárín àwọn méjéèjì.
Ìṣẹ̀lẹ̀ náà ló wáyé ní ìlú Ikakumo Akoko, ìjọba ìbílẹ̀ Akoko North East ìpínlẹ̀ Ondo.
"Lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ méjì tí wọ́n ti sin ìyá náà ni Tope jẹ́wọ́ pé òun ni òun pa ìyá òun"
Ẹ̀sùn ìpànìyàn ni olùpejọ́, Nelson Akintimehin kà sí Tope Momoh lọ́rùn.
Akintimehin sọ fún ilé ẹjọ́ pé ní àárín òru ni Tope fún ìyá rẹ̀ ní ọrùn pa nítorí wí pé ìyá rẹ̀ pè é ní ọmọ àlè.
Ó ní lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ méjì tí wọ́n ti sin ìyá náà ni Tope tó jẹ́wọ́ wí pé òun ni òun pa ìyá òun.
Ó fi kun pé ṣaájú ni àwọn ẹbí ti ń ṣe kàyéfì lórí ohun tó ṣokùnfà ikú òjijì tó pa Stella Momoh.
Ọ̀pọ̀ mọ̀lẹ̀bí olóògbé naa sì ni kò sì mọ ohun tó fa ikú náà títí Tope fi wá jẹ́wọ́ wípé ọwọ́ òun ni ikú ìyá náà ti wá.
Akintimehin ní ìwà tí Tope wù náà lòdì sí abala 319 (1) òfin ìpínlẹ̀ Ondo tọ́dun 2006.
Bákan náà ló rọ ilé ẹjọ́ láti fi Tope sí àhámọ́ fún ìgbà kan náà, títí àbájáde ìmọ̀ràn adarí ẹ̀ka olùpẹjọ́ ìjọba àpapọ̀ yóò fi jáde.
Ẹ̀rí ọkàn kò jẹ́ ki n gbaádùn ni mo ṣe jẹ́wọ́ fún àwọn ẹbí pé èmi ló pa ìyá mi - Tope
Nígbà tó sọ̀rọ̀, Tope Momoh tọrọ kí ilé ẹjọ́ fi ojú àánú wo òun nítorí láti ìgbà tí ìyá òun ti kú, ni ẹ̀rí ọkpan ti ń jẹ́ òun.
Ó ní nítorí ẹ̀rí ọkàn tó ń jẹ́ òun lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ méjì tí wọ́n sin òkú ìyá òun, ni òun ṣe lọ jẹ́wọ́ fún àwọn ẹbí wí pé òun ni òun fún ìyá náà ni ọrùn pa.
Adájọ́ Musa Al-Yunnus nígbà tó ń gbé ìdájọ́ rẹ̀ kalẹ̀, ní kí wọ́n fi Tope Momoh sí àhámọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n Olokuta, títí tí ìgbẹ́jọ́ rẹ̀ yóò fi paí.
Ogúnjọ́ oṣù Kẹwàá, Ọdún 2022 ni adájọ́ sún ìgbẹ́jọ́ náà sí.















