Áfíríkà làwọn ènìyàn ti ń gbẹ̀mí ara wọn jùlọ lágbàáyé - WHO

Oríṣun àwòrán, SCREENSHOT
Àjọ ètò ìlera àgbáyé, WHO ti kéde pé ilẹ̀ adúláwọ̀ ni àwọn tó ń pa ara wọn ní àgbàyé pọ̀ sí jùlọ.
Nínú àtẹ̀jáde kan tí WHO fi léde ní ilẹ̀ adúláwọ̀ ni àwọn orílẹ̀ èdè mẹ́fà nínú orílẹ̀ mẹ́wàá níbi tí àwọn ènìyàn ti ń gba ẹ̀mí ara wọn pọ̀ sí jùlọ wà.
Adarí àjọ WHO fẹ́kùn Áfíríkà, Matshidiso Moeti nínú àtẹ̀jáde náà ní dókítà tó wà fún ṣíṣe àyẹ̀wò ọpọlọ kò tó iye tó yẹ kó wà rárá gẹ́gẹ́ bí àlàkalẹ̀ WHO.
"Dókítà kan péré ló wà fún itọju ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta àwọn ènìyàn ní Áfíríkà"
Moeti tẹsiwaju pe dókítà kan péré ló wà fún itọju ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta àwọn ènìyàn.
O ni éyìí ló fi ọ̀nà ọgọ́rùn-ún díkùn sí iye tí WHO ní ó yẹ kó wà ní orílẹ̀ èdè kan.
WHO ní ènìyàn mọ́kànlá nínú ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún ènìyàn ló ń gba ẹ̀mí ara wọn fúnra wọn lẹ́kùn Áfíríkà.
O ni èyí ló ju ènìyàn mẹ́sàn-án sí ọgọ́rùn-ún ènìyàn ní àwọn ẹkùn mìíràn.
Bákan náà ni wọ́n ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn dókítà tó ń tọ́jú àwọn eeyan to ni ìlera ọpọlọ kìí wà ní àwọn ìgbèríko.
Awọn ìlú ńlá nìkan ni àwọn dókítà yìí máa ń wà ní ẹkùn Áfíríkà.

Oríṣun àwòrán, SCREENSHOT
"Ìlera ọpọlọ ló kó ìdá mọ́kànlá nínú ọgọ́rùn-ún ìdí tàwọn ènìyàn fi máa ń pa ara wọn"
Wọ́n ní ìlera ọpọlọ ló kó ìdá mọ́kànlá nínú ọgọ́rùn-ún ohun tó ń ṣokùnfà ìdí tí àwọn ènìyàn fi máa ń pa ara wọn ní òde òní.
Moeti ṣàlàyé pé WHO ti wá ṣe ìfilọ́lẹ̀ ìpolongo lórí ayélujára báyìí pẹ̀lú èròńgbà láti dènà kí àwọn ènìyàn máa dá ẹ̀mí ara wọn légbodò láì pé ọjọ́.
Ìfilọ́lẹ̀ náà ń wáyé ṣáájú àyájọ́ ọjọ́ ìlera ọpọlọ ní àgbáyé èyí tó máa ń wáyé ní gbogbo ọjọ́ Kẹwà, oṣù Kẹwàá.
Wọ́n ní èròńgbà àwọn ni láti kàn sí mílíọ̀nù mẹ́wàá ènìyàn lẹ́kùn adúláwọ̀.















