ASUU lulẹ̀ lẹ́ẹ̀kejì, ilé ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn ní kò padà sẹ́nu iṣẹ́ kíákíá

Oríṣun àwòrán, @ASUU_NEWS
ilé ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn ti paṣẹ fun ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ fasiti Naijiria, ASUU, lati pada sẹnu iṣẹ lẹsẹkẹsẹ.
Idajọ yii lo waye lẹyin ti ASUU bẹ ile ẹjọ naa, lati da idajọ ile ẹjọ to n gbọ ọrọ aawọ oṣiṣẹ ati gbanisisẹ danu, lẹyin to paṣẹ ki wọn pada sẹnu iṣẹ ṣaaju.
Bo tilẹ jẹ pe ile ẹjọ kotẹmilọrun naa ni ASUU lẹtọọ lati pe ẹjọ kọtẹmilọrun lori idajọ ile ẹjọ ọrọ oṣiṣẹ naa.
Amọ o ni wọn gbọdọ gbọran si aṣẹ ile ẹjọ ọhun, ki wọn si pada sẹnu iṣẹ lati oni ọjọ keje, oṣu Kẹwaa, ọdun 2022 yii.
"ASUU ko gbọdọ pe ẹjọ miran tako àṣẹ ileẹjọ lai jẹ pe o kọkọ pada sẹnu isẹ"
Igbimọ ẹlẹni mẹta ti adajọ Hamman Barka n dari sọ pe ASUU gbọdọ pe ẹjọ kotẹmilọrun fun idajọ naa, laarin ọjọ meje ti idajọ ọhun ko ba tẹ wọn lọrun.
Amọ o fi kun pe, ASUU gbọdọ fi ẹri han pe awọn olukọ fasiti ti pada sẹnu isẹ ki wọn to pe ẹjọ kotẹmilọrun naa.
Wọn ni ti ASUU ba kọ lati pada sẹnu iṣẹ, ẹjọ kotẹmilọrun ti wọn ba pe ko ni lẹsẹ nilẹ, ile ẹjọ naa ko si gba ipẹjọ ko tẹ mi lọrun naa wọle.
Iyanṣẹlodi ASUU yii ni ọkan lara iyanṣẹlodi rẹ to gun julọ ni Naijiria
Ti ẹ ko ba gbabe, ọjọ kẹrinla, oṣu Keji, ọdun ọdun 2022 yii ni ASUU bẹrẹ iyanṣẹlodi, eyii to ti mu ki ọpọ awọn akẹkọọ ni fasiti ijọba apapọ wa nile fun ọpọlọpọ oṣu.
Ọjọ kọkanla, oṣu Kẹrin, eyii to jẹ ọjọ kẹrindinlọgọta ti iyanṣẹlodi naa ti bẹrẹ ni ijọba apapọ to ṣe ipade pẹlu ASUU lati jiroro lori bi iyanṣẹlodi naa yoo ṣe pari amọ ipade naa fori ṣọpọn.
Nigba ti yoo fi di ọjọ kẹsan an, oṣu Karun un ni ASUU fi ọsẹ mejila mii kun iyanṣẹlodi naa.
Iyanṣẹlodi ọhun ni ọkan lara awọn iyanṣẹlodi to gun julọ ninu itan iyanṣẹlodi ASUU ni Naijiria.















