Lóòtọ́ọ́ la gba owóyàá Lapo àmọ́ a máa sán padà - Tobiloba Amusan
Tobiloba Amusan: Eré bọ́ọ̀lù ni mo kọ́kọ́ yàn láàyò àmọ́ mo ri pé kò sí ọ̀nà fún mi níbẹ̀

Laipẹ yii ni gbogbo agbaye dide lati se ayẹsi ọmọ Naijiria kan to pegede julọ lagbaye ninu idije ere sisa ọlọgọrun mita.
Oluwatobiloba Amusan ni orukọ rẹ, ojulowo ọmọ Yoruba atata ni, to si wa lati ilu Ijẹbu Ode.
Lẹyin to gba ẹyẹ agbaye naa tan, Tobiloba wa silẹ Naijiria tii se ile baba rẹ nitori ajo ko dabi ile.
Lasiko abẹwo naa si lo ti kan sawọn obi rẹ nilu Ijebu Ode, to si tun lọ sọdọ aarẹ Muhammadu Buhari, ẹni to fi ami ẹyẹ da lọla.
Ko tan sibẹ, laipẹ yii tun ni Tobiloba se abẹwo sọdọ gomina ipinlẹ Ogun, ẹni to fun ni ẹbun ile ati owo miliọnu marun naira.
BBC Yoruba wa tiraka lati wa Tobiloba kan, ta si fọrọ wa lẹnu wo nipa oriire to se nidi ere sisa yii, igbe aye rẹ, atilẹyin awọn obi rẹ ati afojusun rẹ fun ọjọ ọla.
Ere bọọlu ni mo kọkọ fi bẹrẹ ere idaraya amọ mo ri pe ọna mi ko gba ibẹ - Tobiloba
Nigba to n salaye bo se bẹrẹ ere idara, akọni obinrin naa salaye idi ere bọọlu ni oun kọkọ ya si, amọ nigba to ya o ni oun ri pe ọna oun ko gba ibẹ.
O ni lẹyin naa ni oun wa gba idi ere sisa lọ.
Tobiloba fikun pe awọn obi oun se atilẹyin alailẹgbẹ fun oun lasiko ti oun n gbaradi nidi ere sisa.
Koda, o tun fidi rẹ mulẹ fun BBC Yoruba pe awọn obi oun gan gba owo LAPO, eyiun owoya nile ifowopamọ alabọde eyi ti awọn si maa san pada.
O tun yan pe oun ko figba kankan sọ pe baba oun jo bata ti oun fi n sare ri, ohun ti oun sọ ni pe o ku diẹ ki baba oun jo bata ere sisa oun.
Amọ Tobiloba sisọ loju rẹ pe awọn akọroyin na lo pada wa gbe sita pe oun ni baba oun jo baba ere sisa oun, eyi ti ko ri bẹẹ rara.
Ehoro ori ọdan naa ni bi o tilẹ jẹ pe awọn obi oun kọkọ n ki oun nilọ pe iwe ni awọn sọ pe ki oun lọ ka, kii se ere sisa.
Sugbọn o ni wọn pada ti oun lẹyin ninu ere idaraya ti oun yan laayo naa.
“Mo fẹran ki n maa dana, jo sun, ki n si tun wo sinima, n ko fẹ iyọlẹnu rara”
Nigba to n salaye iru abuda ẹni to jẹ, Tobiloba ni oju oun kan ri bo se ri ni, oun ko buru rara, bẹẹ si ni oun nifẹ lati maa rẹrin.
Lori awọn nnkan to fẹra lati maa se, o slaaye pe oun fẹran ina dida, ki oun si maa tun maa sun.
Tobiloba ni oun ko nifẹ ki ẹnikẹni ni oun lara rara, ti oun si tun fẹran lati maa wo sinima.
“Ẹyin ọdọ, mase jẹ ki ẹnikẹni da omi tutu si yin lọkan pe ko sọna ninu ọna tẹ fẹ gba”
Nigba to n gba awọn ọdọ bii tiẹ nimọran, Tobiloba Amusan rọ wọn lati mase jẹ ki ẹnikẹni da omi tutu si wọn lọkan lori awọn idawọle wọn.
“Ẹ gbagbọ pe ohun to wu yin lọkan yẹn, ẹ le se, ẹ si ma jẹ ki ẹnikẹni si yin lọna pe ẹ ko le se tabi ko irẹwẹsi ba yin pe ọna tẹ fẹ tọ yẹn, ko sọna nibẹ.”
Tobiloba wa fi idunnu rẹ han si ami ẹyẹ ti aarẹ Muhammadu Buhari fi ha lọla, to si ni iru eyi ko tii sẹlẹri lati igba ti aarẹ ti dori allefa.






