Wo àwọn nǹkan tuntun tó jáde nípa Onyeka Onwenu, òǹkorin tó fi orin so Naijiria pọ̀

Onyeka Onwenu

Oríṣun àwòrán, Getty Images

    • Author, Uche Akolisa
    • Role, Senior Journalist
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Nigba to ku ọdun mẹta ti yoo ku, Onyeka Onwenu, gbajugbaja olorin nni, kọ akọsilẹ kan to ti sọ pe oun fẹẹ maa ṣe ajọyọ lasiko iku oun ni, bẹẹ naa lo si ṣe ṣẹlẹ.

Onyeka Onwenu fi ori itage aye silẹ lẹyin to kọrin tan nibi ayẹyẹ ọjọọbi ọrẹ rẹ kan.

Onyeka fẹ́ káwọn èèyàn jẹun, dá'pàrá ki wọ́n sì rẹ́rìn-ín ní ìrántí ikú rẹ̀

Onyeka Onwenu

Oríṣun àwòrán, Onyeka Onwenu/Instagram

Ni ọdun 2021, Arabinrin Onyeka Onwenu kọ akọsilẹ lorii bo ṣe fẹ ki wọn sin oun.

Akọsilẹ naa ka bayii pe, “ ẹ gba adura fun mi, ẹ ṣeto ayẹyẹ ounjẹ ọsan tabi ti aṣalẹ fawọn eeyan. Ẹ ṣawada, ẹ dapara nipa mi. Ẹ ṣe ajọyọ, ki kaluku si gba ibi okoowo rẹ lọ lẹyin iyẹn” .

Ko too di ọjọ ode to lọ gbẹyin yii, Onyeka ko fi bẹẹ jade fawọn eeyan lati ri mọ. Awọn asiko kan ni mama naa kan maa n da si ọrọ ọwọngogo to n ṣẹlẹ ni Naijiria.

Igba kan wa to ke sawọn olori orilẹede yii, pe ki wọn ji giri si iṣẹ wọn ki nnkan too bajẹ ju. Ọdun 2021 ni eyi.

Onyeka sọ nigba naa pe iya to ti n jẹ Naijiria tipẹ, eyi toun n ka gẹgẹ bii oniroyin ni BBC/NTA ni 1981 naa lo ṣi tun n jẹ awọn eeyan lọ lai duro.

Ilu kan ti a mọ si Oguta, nipinlẹ Imo, ni wọn ti bi Onyeka Onwenu lọdun mejilelaadọrin sẹyin.

Onyeka kawe loke okun, niluu Amerika ati New York.

O bẹrẹ iṣẹ gẹgẹ bi akọroyin nileeṣẹ tẹlifiṣan ijọba apapọ(NTA), o si gbe orin rẹ akọkọ to pe ni 'For the love of God', jade ni 1981. Orin rẹ to pe ni 'One Love' lo sọ ọ di gbajumọ ni 1986.

''Orin One Love naa jade lasiko ti Naijiria n la iṣoro ẹlẹyamẹya kọja, awọn eeyan si tẹwọ gba a daadaa nitori ifẹ ti Onyeka kede ninu rẹ.

Nitori akọrin pẹlu oriṣiiriṣii ede ti Oloogbe yii jẹ, o fi ede oyinbo, Yoruba ati ede Igbo kọrin ni 1988.

Lara orin rẹ tun ni "Wait For Me", ti oun pẹlu King Sunny Ade (KSA), olorin Juju jọ kọ ni .

Laarin ọdun 1990 ni Oloogbe Onwenu bẹrẹ si i kọrin ẹmi, ti ko kọrin taka-sufee mọ.

Onyeka Owenu kò gba rádaràda

Onyeka Onwenu

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ohun kan ti awọn eeyan mọ Oloogbe Onyeka Onwenu fun ni pe ko fi aaye gba radarada. Oun paapaa sọ bẹẹ ri, pe oun ki i fi ko tọ lọ eeyan, oun naa ko si le gba radarada lọwọ ẹnikẹni.

Ni ọdun 2000, Onyeka figba kan kọ ounjẹ silẹ, ko jẹun mọ nitori ileeṣẹ NTA to ba ṣiṣẹ ri ko fẹẹ sanwo to yẹ lori awo orin rẹ ti wọn n lo fun un.

NTA pada sanwo naa, wọn ko si lo awọn orin rẹ mọ.

Gẹgẹ bi Oloogbe Onyeka Onwenu ṣe sọ fun akọroyin kan ri, o ni, ''ti mi o ba si lori itage, mo fẹran ki n da aye mi gbe, mi o fẹran ero ati afẹfẹyẹyẹ.''

Ọpọ eeyan ni ko mọ nnkan pupọ nipa ọkọ ati idile iya yii.

Wọn ko mọ boya ọkunrin to bi awọn ọmọ rẹ mejeeji fun, iyẹn Ibrahim Ogunlende, fẹ ẹ niṣu lọka ni tabi bẹẹ kọ.

Ọmọ ọkunrin meji ti Onyeka Onwenu bi ni Tijani Ogunlende ati Ibraham Ogunlende,

Ohun kan ti awọn eeyan yoo maa ranti oloogbe yii fun ni pe o fi orin rẹ ja fun orilẹede rẹ, o si ni igboya bii ọmọ Akin.

Ọgbọnjọ, oṣu keje ọdun 2024 ni Onyeka Onwenu jade laye.