Kò rọrùn láti yọ owó ìrànwọ́ epo bẹntiró àmọ́ ohun tó ṣe pàtàkì ni – Tinubu

Asiwaju Bola Ahmed Tinubu

Oríṣun àwòrán, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Aarẹ Bola Ahmed Tinubu ti sọ pe yiyọ owo iranwọ ori epo kii ṣe ohun to rọrun, ṣugbọn ohun to ṣe pataki julọ ni lati yọ ọ danu.

Dida owo iranwọ ori epo bentiro pada jẹ ọkan pataki lara awọn ohun ti awọn olufẹhonuhan n beere fun, lati le dẹkun iṣẹ ati oṣi lawujọ.

Aarẹ Bola Tinubu lasiko to n ba awọn ọmọ Naijiria sọrọ laarọ ọjọ Aiku sọ pe ọkan pataki lara awọn igbesẹ lati mu atunto ba eto ọrọ aje ni yiyọ owo iranwọ ori epo naa jẹ.

O ni fun igba pipẹ ni eto ọrọ aje Naijiria ti dẹnukọlẹ, to si n fa idena fun ilọsiwaju.

Tinubu sọ pe “Fun bi ọdun kan le sẹyin, orileede wa, Naijiria ti de ipele to jẹ pe a ko le maa wa ọna abayọ igba diẹ lati fi yanju iṣoro ọjọ pipẹ, nitori awọn iran ti wọn ko tii bii.

“Eyi lo jẹ ki n gbe igbesẹ to le lati yọ owo iranwọ ori epo lati le dẹkun lilo owo ilẹ okeere, eyi to ti ko ipa to ku diẹ kaato ninu eto ọrọ aje wa ati ifasẹyin ilọsiwaju eto ọrọ aje.”

Aarẹ Tinubu tẹsiwaju pe igbesẹ yii ti dena ijẹ ati ere awọn onifayawọ to n gbadun naa ṣaaju.

Bakan naa lo sọ pe igbesẹ naa tun dẹkun owo iranwọ ori epo ti ko tọ, eyi to n lọ si awọn orileede to sunmọ Naijiria, to n pa awọn araalu lara, to si n ba eto ọrọ aje jẹ.

“Igbesẹ ti mo gbe yii pọn dandan bi a ba fẹẹ fi opin si aṣilo eto ọrọ aje ọjọ pipẹ ti ko ṣiṣẹ daadaa fun wa.

“Lotitọ ni mo gba pe ori mi lo ti bẹrẹ, ṣugbọn mo le fi da a yin loju pe afojusun mi ni lati mu iṣejọba de ọdọ awọn araalu nitori pe iṣejọba rere lo ṣe koko.”

TinubuWo àwọn kókó tó wà nínú ọ̀rọ̀ tí Tinubu báwọn ọmọ Nàìjíríà sọ lórí ìwọ́de tó ń lọ lọ́wọ́

Aare Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, Nigerian Presidency

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Bi iwọde ebi n pa wa ṣe n lọ lọwọ lorilẹede Naijiria, Aarẹ Bola Tinubu ti sọ pe ọrọ aje ilu yii ti fẹẹ maa daa, ki awọn eeyan ilu ma tun fa ọwọ aago ilọsiwaju ọrọ aje naa sẹyin.

Ọjọ Aiku, ọjọ kẹrin oṣu kẹjọ ọdun 2024 yii ni Aarẹ Tinubu sọ eyi di mimọ nigba to n ba awọn ọmọ Naijiria sọrọ lori ifẹhonuhan to n lọ lọwọ ati bi nnkan ṣe ri lasiko yii.

Aarẹ fi ibanujẹ rẹ han si bi awọn kan ṣe sọ ifẹhonuhan di ipaniyan, biba dukia jẹ ati ole jija.

O ba ẹbi awọn eeyan to ti padanu ẹmi wọn ninu iwọde naa kẹdun, o si rọ awọn ọdọ lati ṣe suuru.

''Ẹ ma ṣse jẹ ki ẹnikẹni tan yin pe ijọba ko fẹran yin, tabi pe a ko ri tiyin ro, ko ri bẹẹ rara. Loootọ ni pe awọn kan ti ja yin kulẹ ri, ṣugbọn ireti ọtun ti wa bayii.

''Iṣejọba mi n ṣiṣẹ takun-takun fun yin, ẹ si maa too ri esi rẹ laipẹ.

''Ẹ jẹ ki gbogbo wa jọ sowọ pọ lati pese ọjọ iwaju rere fun irandiran wa to n bọ.

Ọro aje wa ti fẹẹ maa daa, ẹ jọwọ, ẹ ma jẹ ka tun da ẹmi ẹ legbodo. Ẹ ma jẹ kawọn ọta ijọba awarawa da wa pada sẹyin.''

Bayii ni Aarẹ Bola Tinubu wi.

Nipa awọn eeyan to wa nidii iwọde to di itajẹsilẹ, Tinubu sọ pe ọwọ ofin yoo tẹ wọn bo ti wu ko ri.

O ni ki nnkan le ba dẹrun fun orilẹde yii loun ṣe gbe igbesẹ yiyọ owo iranwọ epo, (subsidy). Esi to daa si ti n jade lati ibi yiyọ owo iranwọ naa bi Aarẹ se wi.

''Àjẹsilẹ̀ gbèsè ni Naijiria n fi owo to n pa wọle san''

Tinubu fi kun un pe ajẹsilẹ gbese ni Naijiria n fi owo to n ri san. O ni ida mẹtadinlọgọrun-un (97%) owo to n wọle fun Naijiria lo fi n san gbese, ṣugbọn laarin ọdun kan iṣakoso yii, Tibubu sọ pe o ti dinku si ida mejidinlaadọrin (68%).

Ninu ọrọ owurọ ọjọ isinmi naa ni Aarẹ ti sọ pe anfaani ti wa lati nawo si awọn ẹka bii eto ilera, ẹkọ, oju ọna to ja gaara, fifun awọn ijọba ibilẹ lowo ati ominira ti wọn ko ri iru rẹ ri.

Abala afẹfẹ idana to ti n ṣojojo tipẹ, Aarẹ sọ pe ajinde ti de sibẹ bayii.

O ni loṣu keje to kọja yii ni awọn ṣafikun agba epo Naijiria si miliọnu kan ati mọkanlelọgọta ( (1.61miliion barrels per day).

Bakan naa lo ni o ri labala awọn mọto to n lo afẹfẹ bayii dipo epo rọbi(Compressed Natural Gas Initiative (CNG). Aarẹ sọ pe oun yoo pin awọn eelo rẹ fun awọn ọkọ ti yoo maa lo afẹfẹ yii, eyi ti yoo din wahala epo ku.

Ju gbogbo ẹ lọ, eto wa fun awọn ọdọ bi Tinubu ṣe wi.

O mẹnuba awọn owo iranwọ to gbe kalẹ fun awọn akẹkọọ. Bẹẹ ni ko yọ awọn idile Naijiria silẹ, ki jijẹ-mimu ati igbayegbadun le tọ wọn lọwọ.

O ṣalaye bo ṣe jẹ pe ẹgbẹrun lọna aadọrin ni oṣiṣẹ to gbowo kere julọ yoo maa gba bayii, nitori oun ti buwọ lu u lọsẹ to kọja.

Ààrẹ Bola Tinubu bá àwọn ọmọ Naijiria sọ̀rọ̀ lórí ìwọ́de tó ń lọ lọ́wọ́

Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, Ajuri Ngelale

Aarẹ Naijiria, Bola Tinubu yoo ba awọn araalu sọrọ lọjọ Aiku, ọjọ kẹrin, oṣu Kẹjọ, ọdun 2024 ti a wa yii.

Aago meje aarọ ni Aarẹ yoo ba gbogbo araalu sọrọ.

Agbẹnusọ Aarẹ, Ajuri Ngelale, lo kede bẹẹ lọjọ Abamẹta.

Ngelale sọ pe ki gbogbo ileeṣẹ amohumaworan, asọrọmagbesi atawọn ileesẹ iroyin mii ni Naijiria darapọ mọ ileeṣẹ igbohunsafẹfẹ ijọba apapọ, NTA ati FRCN fun ohun ti Aarẹ fẹ ba gbogbo araalu sọ.

O fi kun pe NTA ati FRSC yoo tun ọrọ Aarẹ gbejade ni aago mẹta ọsan ati aago meje irọlẹ.

Ọpọ araalu lo ti n reti ki Aarẹ sọrọ lẹyin ifẹhonuhan ‘ebi n pa wa’ to gbode kan lati Ọjọbọ to kọja.

Lara awọn to ke si Aarẹ pe ko sọrọ soke ni oludije sipo Aarẹ ninu ẹgbẹ oṣelu Labour, Peter Obi, atawọn eekan mii.

Ẹwẹ, awọn eeyan yoo maa reti ki Aarẹ sọrọ nipa awọn igebsẹ ti yoo gbe ki aye le dẹrun fun gbogbo mutumuwa.

Lati igba ti Tinubu ti kede pe opin ti de ba owo iranwọ ori epo bẹntiro ni gbogbo nnkan ti bẹrẹ si n gbowo lori ni Naijiria, eyii to mu ki awọn eeyan pe fun iwọde to n lọ lọwọ.