Àwọn olùwọ́de ṣe àṣekágbá ìwọ́de #EndBadGovernance nílùú Abuja

Apa ariwa orilẹede Naijiria ni iwọde 'ebi n pa wa' ti fẹsẹ mulẹ julọ pẹlu bawọn ọdọ ti tu yaya jade lati fi ẹhonu han lori bi ilu ko ti fara rọ.

Ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ tí ń lọ lọ́wọ́

  1. Àwọn olùwọ́de ṣe àṣekágbá ìwọ́de #EndBadGovernance nílùú Abuja

    Awọn Oluwọde

    Oni ni ọjọaṣekagba iwọde ebi n panu to ti bẹrẹ lawọn agbegbe kan lorilẹede Naijiria lati ọjọbọ, ọjọ kini oṣu kẹjọ ọdun 2024 ni Naijiria.

    Ni ilu Abuja tii ṣe olu ilu Naijiria, awn oluwọde ṣi jade lati kasẹ iwọde wọn nilẹ bi o tilẹ jẹ wi pe lawọn ipinlẹ miran kaakiri Naijiria to bẹrẹ iwọde naa, iwọde kankan ko waye lọjọ Abamẹta ti iwọde naa pari.

    Ṣaaju iwọde ọjọ Abamẹta lawọn ẹgbẹ kan bii “Take it back” ti n polongo kiri pe iwọde onimiliọnu kan ero lawọn yoo ṣe kaakiri awọn olu ilu ipinlẹ mẹrẹrindinlogoji ati Abuja.

    Iwadii BBC kaaakakiri awọn olu ilu ipinlẹ fihan pe ko si ohun to jọ eyi ni ọpọlọpọ awọn ipinlẹ.

    Amọṣa nibi iwọde to waye ni ọjọ Abamẹta nilu Abuja, awọn oluwọde ilu Abuja tun jade lọjọ oni Abamẹta lati tun tẹsiwaju ninu iwọde wọn lati kasẹ eto iwọde ọlọjọ mẹwaa ti wọn tun gunle, ni eyi to ti bẹrẹ lati ọjọ kinni osu Keje ọdun yii.

    Awọn Oluwọde

    Ni aago meje owurọ yii ni eto iwọde ọhiun bẹrẹ ti awọn oluwọde si n kigbe pe “ Ebi ń pawá ati ẹ dáwọ́ owó ìrànwọ́ epo padà”

    Bo tilẹ jẹ pe eto iwọde naa jẹ ki idiwọ wa lori eto ọrọfun awọn olugbe ilu,ti awọn osisẹ ijọba ti ile-isẹ wọn wa ni aarin gbungbun ilu Abuja iyẹn Federal Secretariat si gba isinmi alairotẹlẹ.

    Bakan naa, lasiko iwọde ọhun niawọn agbfinro , ikọ Dss si bẹre si n mu awọn to n dari eto iwọde ọhun.

    Ogunlọgọ awọn ikọ DSS, agbofinro ati ikọ ọmọ-ogun ni wọn n gbe ọkọ wọn rinkaakiri ilu Abuja.

    A tun ri awọn ikọ ọmọ-ogun ati agbofinro miran ni papa isereEagles Square lati mojuto eto aabo nibẹ.

  2. Ó yẹ kí ìjọba tẹ́tí gbọ́ àwọn olùwọ́de, lóòtọ́ lebi ń pa àwọn ọ̀dọ́, inú ń bí wọn, kò sí sí iṣẹ́ fún wọn -Obasanjo

    Oluṣẹgun Ọbasanjọ

    Oríṣun àwòrán, Getty Images

    Ààrẹ orilẹede Naijiria nigba kan rí, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ ti sọ pe ohun to lẹtọ lsn ọdọ awọn ọdọ to n ṣe iwọde ebi-n-panu #EndBadGovernance to n lọ lawọn ipinlẹ kan ni Naijiria n ja fun.

    Oloye Ọbasanjọ ni ohun to yẹ ni ki ijọba o tẹti si wọn ko si gbọ ohun ti wọn n sọ nitori pe, gẹgẹ bi ọr rẹ, “Nnkan ti su wọn, ebi n pa wọn, inu n bi wọn wọn o dẹ ri iṣẹ”.Aarẹ tẹlẹ naa sọ eyi lasiko to fi n gbalejo awọn aṣofin apapọ mẹfa kan to bẹẹ wo ni ile rẹ to wa nilu Abẹokuta ni ipinlẹ Ogun.

    Awọn aṣofin naa ni wọn n ṣe agbatẹru abadofin kan eyi ti wọn fi n pe fun saa ọlọdun mẹfa kan ṣoṣo fun aarẹ lorilẹede Naijiria.

  3. Àwọn agbófinró ti bẹ̀rẹ̀ sí ní gba dúkìá tí àwọn olùwọ́de kó ní Kano

    Aworan awọn oluwọde to lọ ji ẹruẹlẹru

    Oríṣun àwòrán, others

    Awọn agbofinro ti n ṣe awari awọn ọja ati ẹru tawọn oluwọde ji ko ni ileeṣẹ ijọba ibilẹ Wudi ni ipinlẹ Kano lasiko iwọde ebi n panu to waye lawọn ipinlẹ kan ni Naijiria.

    Yatọ si ilu Kano, awọn dukia ti owo rẹ to ẹgbẹlẹgbẹ miliọnu Naira lawọn oluwọde ko lọ lasiko rogbodiyan to waye lawọn ijọba ibilẹ mẹrinlelogoji to wa ni ipinlẹ Kano lasiko iwọde naa.

    Alaga ijọba ibilẹ Hajiya, Bilkisu Yakubu ṣalaye fun BBC pe ko si ọfisi fun wọn lati ṣiṣẹ bayii nitori pe wọn ti dana sun ileeṣẹ ijọba ibilẹ wọn.

    O ni kii ṣe dukia ijọba nikan ni wọn ko o, awọn janduku oluwọde naa tun ko ọja awọn ontaja atawọn eeyan miran ni ilu naa.

  4. Àwọn olóṣèlú kan ló ń ṣàtìlẹyìn fáwọn olùwọ́de tó ń dá rògbòdìyàn sílẹ̀ - Shettima

    Kashim Shettima

    Oríṣun àwòrán, Senator Kashim Shettima

    Àkọlé àwòrán, Aworan Kashim Shettima

    Igbakeji aarẹ orilẹede Naijiria, Kshim Shettima ti sọ pe awọn oloṣelu kan lo n ṣatilẹyin fawọn olufẹhonuhan to n da rogbodiyan ninu iwọde ‘ebi n pa wa’ ni Naijiria.

    Apa ariwa orilẹede Naijiria ni iwọde naa ti fẹsẹ mulẹ julọ pẹlu bawọn ọdọ ti tu yaya jade lati fi ẹhonu han lori bi ilu ko ti fara rọ.

    Koda, ọpọ awọn oluwọde ọhun lo na asia orilẹdede Russia soke eyi ti ijọba ti ṣe ikilọ wi pe iwa iditẹmọjọba lo tumọ si.

    Nigba to n ba BBC Hausa sọrọ, igbakeji aarẹ ni erongba Aarẹ Bola Tinubu ni lati ṣe iranwọ fawọn eeyan apa ariwa Naijiria, ṣugbọn o ṣalaye wi pe awọn kan lo n gbegi dina rẹ.

    Igbakeji aarẹ ni ‘’Tinubu mọ pe ilu o fara rọ lasiko yii, o si n ṣiṣẹ takun takun lati ri pe nnkan yatọ laipẹ.

    Oniruuru eto ni ijọba apapọ ti ṣe lati mu adinku ba oṣi ati iṣẹ to n ba ọpọ eeyan finra ni Naijiria.’’

    Shettima ni ijọba yoo sa gbogbo apa rẹ lati ri pe alaafia jọba papaa julọ lapa ariwa Naijiria ti iwọde ebi n pa wa ti bẹyin yọ.

    Shettima ko ṣai fidi rẹ mulẹ pe awọn oloṣelu to n ṣatilẹyin fawọn oluwọde fẹ ko Naijiria sinu rukerudo.

    Amọ, o ṣalaye pe ijọba to wa lode ko ni gba fun ẹnikẹni lati da Naijiria ru.

    Bakan naa ni Shettima tun sọ pe ijọba tun ti n lakaka lati pese iṣẹ fawọn ọdọ ti ko ri iṣẹ ṣe.

    O ni ai fi ọrọ awọn ọdọ ṣere naa lo mu ki ijọ gbe eto ẹyawo fawọn akẹkọọ ile ẹkọ giga kalẹ.

  5. Ẹ parí ìwọ́de yín o, ìwọ́de yín ń fi ebi pa wá – Àwọn oníbárà pariwo síta nílùú Kano

    Awọn onibara kan lẹgbẹ opopona

    Awọn onibara kan ni igboro ilu Kano ti pariwo sita pe ki awọn to n ṣe iwọde ni ipinlẹ naa fopin si iwọde wọn nitori pe o n koba agbe ti wọn n ṣe.

    Wọn ni a dara ki awọn to n ṣe iwọde naa ro tawọn ẹlomiran mọ tiwọn.

    Ninu ọrọ to ba ileeṣẹ akoroyinjọ NAN sọrọ Baba Haliru, ẹni aadọrin ọdun to jẹ onibara lagbegbe Rigiyar Zaki ni inira lawọn fi n gbe ile aye lati igba ti iwọde naa ti bẹrẹ.

    Alagba Haliru sọ pe owo agbe ojumọ lawọn onibara fi n jẹun ti wọn si fi n bọ ẹbi wọn, ṣugbọn eyi ko ri bẹẹ mọ lati igba ti iwọde naa ti bẹrẹ.

    O ni, “ni idile mi ti a jẹ mẹrinla, a ko tii jẹ ohunkohun fun ọjọ meji laarin ọjọ mẹrin sẹyin.

    Bakan naa lawọn onibara yooku to ba ikọ iroyin naa sọrọ pẹlu pe fun didẹkun iwọde naa ati ofin konile-o-gbele to wọ tọọ lẹyin ni ipinlẹ naa.

    Awọn onibara miran ni “ounjẹ ti awọn ni sile ti tan, bẹẹ ni ko si owo mọ nitori awọn ko raye jade lọ ṣiṣẹ titọrọ bara wọn.

  6. Ìjọba Kaduna gé “kónílé-ó-gbélé” kúrú sí agogo mẹ́jọ òwúrọ̀ sí mẹ́fà ìrọ̀lẹ̀

    Gomina ipinlẹ Kaduna

    Ijọba ipinlẹ Kaduna ti dẹ okun ofin konile-o-gbele to wa ni ipinlẹ naa lẹyin ti iwọde ‘ebi n panu’ to waye lawọn ipinlẹ kan ni Naijiria di wahala ni Kaduna atawọn ilu kan ni ipinlẹ naa.

    Gẹgẹbi aṣẹ ti ijọba ipinlẹ naa ṣẹṣẹ gbe kalẹ, awọn eeyan ipinlẹ naa le jade bayii laarin agogo mẹjọ owurọ si agogo mẹfa irọlẹ.

    Ninu atẹjade kan eyi ti kọmiṣọna fun eto abo ati ọrọ abẹle ni ipinlẹ Kaduna, Samuel Aruwan fi sita, o ni lẹyin ti igbimọ abo ni ipinlẹ naa gbe bi nnkan ṣe n lọ yẹwo, wọn ti ge asiko ‘konile-o-gbele’ kuru kuro ni wakati mẹrinlelogun ti wọn fi silẹ lọjọ Aje, ọjọ kẹrin oṣu kẹjọ ọdun 2024.

    Awọn eeyan yoo maa wa nile wọn laarin agogo mẹfa irọlẹ si mẹjọ owurọ ki wọn to le bọ sita fun iṣẹ oojọ wọn.

  7. Kókó tó wà nínú ọ̀rọ̀ tí Tinubu ṣẹ̀ṣẹ̀ báwọn ọ́mọ Nàìjíríà sọ rèé

    Aarẹ Bola Tinubu

    Oríṣun àwòrán, Bola Ahmed Tinubu

    Àkọlé àwòrán, Aworan Bola Tinubu

    Aarẹ Bola Tinubu ti rọ awọn ọmọ Naijiria lati riran kọja ipenija ti wọn n dojukọ lọwọ bayii lọ.

    Aarẹ ni ki wọn maa wo ọjọ iwaju eyi to dara.

    Tinubu sọrọ yii ninu fidio kan to fi lede loju opo ayelujara X rẹ ni Ọjọru.

    Wọnyi ni koko to wa ninu ọrọ ti Tinubu ṣẹṣẹ bọmọ Naijiria sọ:

    Ayọkuro owo iranwọ ori epo bẹntiroolu

    Tinubu ṣalaye ninu ọrọ to ṣẹṣẹ sọ wi pe ijọba o lagbara mọ lati maa san owo iranwọ ori epo bentiroolu lọ.

    Aarẹ ni oun yọ owo iranwọ yii tori ko si ninu eto ìṣúná orilẹede Naijiria lati oṣu Keje si oṣu Kejila ọdun 2023.

    Ayọkuro owo iranwọ ori epo yii wa lara awọn nkan tawọn ọmọ Naijiria n beere lọwọ ijọba Tinubu wi pe ki o da pada ki ara le rọ araalu.

    Tinubu wa rọ araalu lati tubọ fori ti i si wi pe gbogbo ohun ti ko to bayii lo maa pada wa ṣẹku.

    "Ọmọ Nàìjíríà naa lo maa pada jẹ anfani gbogbo oniruuru eto ti ijọba mi ti a n ṣe laipẹ lai jina," Tinubu lo sọ bẹẹ.

    Eto eyawo fawọn akẹkọọ ile ẹkọ giga

    Ọpọ obi ati alagbatọ lo ti n pariwo wi pe owo ile ẹkọ giga ti di gọbọi fáwọn lati san lẹyin ti ọpọ ile ẹkọ giga ti ṣe afikun owo ile iwe.

    Aarẹ Tinubu sọ nipa eto ẹyawo, NELFUND ti ijọba rẹ ṣe agbekalẹ rẹ lati ṣe iranwọ fáwọn akẹkọọ ti ko rọwọ họri.

    Eto ẹyawo NELFUND fáwọn akẹkọọ ọmọ Naijiria ni nnkan akọkọ ti Aarẹ Tinubu buwọlu lẹyin to di aarẹ orilẹede Naijiria.

    Tinubu sọ ninu ọrọ re pe ijọba oun ko ni kuna lati jẹ ki awọn akẹkọọ lanfaani si eto ẹkọ to ye korororo gẹgẹ bi ileri oun.

    O ni ko ni si akẹkọọ ti yoo pa ẹkọ rẹ ti nitori airowo san.

    Fun bi ọjọ mẹfa bayii l'awọn ọdọ ti jade ṣe iwọde lori ọwọngogo nnkan, iwa ajẹbanu ijoba ati airiṣẹ se awọn ọdọ.

    Iwọde naa to lọ wọọrọwọ l'awọn ipinlẹ kan bi ipinlẹ Eko lo ti bẹyin yọ lapa ariwa Naijiria bii ipinlẹ Bornu, Jigawa, Kaduna, Niger ati ipinlẹ Kano.

    Koda, iroyin sọ pe awọn ẹṣọ eleto abo tun yìnbon pa awọn olufẹhonuhan kan.

    Amọ, Tinubu ni Naijiria maa to kuro ninu okunkun wọ inu imọlẹ lọ.

    Aarẹ ni "mo le fi da ọmọ Naijiria loju pe lẹyin okunkun biribiri imọlẹ maa to tan."

  8. Ààrẹ Tinubu tún bá àwọn ọmọ Nàìjíríà sọ̀rọ̀, Ó ní ‘Ẹ fọkànbalẹ̀, nǹkan tó lè yí ń bọ̀ wá dẹ̀rọ̀’

    Aaeẹ Tinubu

    Oríṣun àwòrán, asiwaju bola tinubu/x

    Ààrẹ orilẹede Naijiria, Bọla Ahmed Tinubu tun ti ba awọn ọmọ Naijiria sọrọ lati fi ọkan wọn balẹ pe igba yoo yi pada, gbogbo ohun to le si n bọ wa dẹrọ laipẹ.

    Ninu ọrọ to sọ eyi ti ileeṣẹ aarẹ fi sita loju opo ayelujara gbogbo, Aarẹ Tinubu ṣalaye pe o da oun loju pe awọn igbesẹ ti iṣejọba oun n gbe lati yi ori eto ọrọ aje Naijiria pada si ọna to tọ yoo so eso rere.

    O ni bi o tilẹ jẹ wi pe nnkan ko rọgbọ lọwọ yii, ‘ti gbogbo rẹ si le koko fun mutumuwa, ṣugbọn mo rọ yin lati gbojusoke wo ọọkan kọja awọn irora to wa nilẹ lọwọ si iran rere to wa niwaju.”

    Aarẹ orilẹede Naijiria ni ko dun mọ oun ninu pe laarin asiko ti ijọba oun kede yiyọ owo iranwọ ori epo rọbi si akoko yii, nnkan lọ jaijai diẹ, sibẹ o da oun loju bi ada pe gbogbo igbesẹ atunto ọrọ aje ti iṣejọba oun n gbe ni yoo ja si aṣeyọri lẹyin o rẹyin.

    Aarẹ Tinubu ni iṣọkan isisiyi ni yóò yẹna fun ọjọ ọla to ye kooro.

    “Ijo wa ajọjo, awẹ wa ajọgba, a o si bori”

  9. Ọwọ́ DSS tẹ ọmọ orílẹ̀èdè Poland méje tó gbé àṣìá orílẹ̀èdè Russia lásìkò ìwọ́de ní Kano

    Awọn oṣiṣẹ DSS

    Oríṣun àwòrán, others

    Ọwọ awọn agbofinro lorilẹede Naijiria ti tẹ awọn ọmọ orilẹede Poland meje kan lori ẹsun pe wọn gbe aṣia orilẹede Russia lasiko iwọde ‘ebi n panu’ ni ipinlẹ Kano, lẹkun ariwa orilẹede Naijiria.

    Agbẹnusọ fun ileeṣẹ agbofinro DSS, Peter Afunanya lo sọ eyi lasiko ifọrọwerọ kan to ṣe pẹlu awọn akọroyin lọjọru.. O ni ọwọ tẹ awọn afurasi naa lasiko ti sn agbofinro DSS n sare lati pa ina rogbodiyan to waye lasiko iwọde naa.

    Bi o tilẹ jẹ pe ko sọ ẹkunrẹrẹ orukọ wọn ati iru eeyan ti wọn jẹ, alukoror ileeṣẹ agbofinro DSS naa ṣalaye pe kii ṣe pe awọn fẹ wa maa tori eyi lepa awọn ọmọ orilẹede Poland to wa lorilẹede Naijiria kiri o.

    Ileeṣẹ akoroyinjọ, Reuters ni aṣoju ijọba orilẹede Poland ni Naijiria, Stanislaw Gulinsky, ti fi idi iroyin yi mulẹ lasiko ipade rẹ pẹlawọn aṣoju ijọba Naijiria kan l’Ọjọru nilu Abuja.

    “Lọjọ meji sẹyin ni wọn mu wọn ni Kano, ohun ti mo gbọ kẹyin ni pe wọn fẹ gbe wọn wa si Abuja”

  10. Iléeṣẹ́ ológun Nàìjíríà kẹ́dùn lórí ìkú ọmọkùnrin ẹni ọdún 16 tí ṣọ́jà kan yìnbọn pa lásìkò ìwọ́de ní Kaduna

    Aworan

    Oríṣun àwòrán, screenshot

    Ileeṣẹ ọmọogun Naijiria ti kọminu lori bi ọkan lara awọn ọmọogun rẹ ṣe sekupa ọmọdekunrin ẹni ọdun mẹrindinlogun kan lagbegbe Samaru ni Zaria nipinlẹ Kaduna.

    Atẹjade kan ti alukoro fun ileeṣẹ ọmọogun oriilẹni Naijiria, Ọgagun Onyema Nwachukwu, fi sita, ṣalaye pe awọn ọmọogun gba ipe kan fun iranlọwọ lọwọ awọn janduku kan to korajọ lagbegb Samaru ti wọn n da ina si oju popo tisn si n ju okuta lu awọn ṣọja to lọ si ibẹ lati pa ina wahala naa.

    Awọn ṣọja to gbiyanju lati tu wọn ka yin ibọn lati kilọ fun wọn; amọṣa ibọn naa ba ọmọdekunrin naa ti orukọ rẹ n jẹ Ismail Mohammed

    Atẹjade naa sọ pe wọn ti fi ṣọja to yinbọn naa si ahamọ, ati wi pe ọga agba fun ileeṣẹ ọmọogun oriilẹ lorilẹede Naijiria, Ọgagunagba Taoreed Abiọdun Lagbaja ti ran ikọ lọ ba awọn ẹbi ọmọ naa kẹdun.

    Atẹjade ọhun tun fi kun un pe wọn ti sin oku ọmọdekunrin naa ni ilana ẹsin Musulumi, awọn eekan nileeṣẹ ologun lo si wa nikalẹ nibi isinku rẹ.

  11. Èyi ni ibi tí nǹkan dé dúró lónìí lórí ìfẹ̀hónúhàn ‘ebi ń pa wá’ tó ń lọ lọ́wọ́

    Awọn oluwọde
    Àkọlé àwòrán, Awọn oluwọde

    Lonii, ọjọ keje, oṣu kẹjọ ọdun 2024 ni ifẹhonuhan to n kede fopin si ijọba buburu, pe ọjọ meje to ti bẹrẹ ni Naijiria.

    Ẹ o ranti pe ọjọ akọkọ ninu oṣu kẹjọ yii ni awọn olufẹhonuhan ti bẹrẹ iwọde ọhun ni ọpọlọpọ ipinlẹ Naijiria.

    Ọpọ eeyan ni ko le sọ sibi iṣẹ oojọ wọn, bẹẹ ni awọn ontaja jokoo sile nibẹrẹ iwọde naa.

    Bo ṣe lọ wọọrọwọ lawọn ipinlẹ kan lo mu jagidijagan, ole jija ati iku wa lawọn ipinlẹ miran, paapaa lapa Ariwa orilẹede yii.

    Ninu ifẹhonuhan naa ni awọn kan tun bẹrẹ si i wọde pẹlu asia orilẹede Russia, eeyan to si ti bọ sọwọ ọlọpaa ati ṣọja lori iwọde yii ko kere rara.

    Koda, ninu rẹ ni awọn ipinlẹ bii Kano, Kaduna ati Borno ti kede ofin konile-o-gbele, ki alaafia le jọba.

    Ṣugbọn ni bayii ti iwọde naa ti wọ ọjọ keje, òye foju han pe ọpọ eeyan lo ti pada si ẹnu iṣẹ wọn.

    Nigba to ti n di bii ọjọ karun-un si ikẹfa ni ifẹhonuhan naa ti n sinmi.

    Ipinlẹ Eko, Ogun, Ondo, Osun, Kwara ati awọn ipinlẹ yooku ni Naijiria ti da bii pe ko si iwọde nibẹ rara, bẹẹ ni Kano to kede konile-gbele paapaa ti ni kawọn oṣiṣẹ pada si ẹnu iṣẹ wọn.

    Bakan naa lo ri ni ipinlẹ Kaduna, kaluku ti n mu iṣẹ aje wọn ṣe.

    Awọn to gbe ifẹhonuhan yii kalẹ paapaa ti ni ki awọn olufẹhonuhna fopin si i l’Eko.

    Ẹta horo eeyan lo n wa nibi ti wọn ti n pade lọjọ ti wọn ba fẹẹ pejọ.

    Ohun kan to gbalẹ kan bayii ni ti awọn eeyan to gbe asia Russia wọde lapa Oke-Oya, eyi ti ijọba ilẹ yii ka si iditẹ mọ ilu.

    Ọwọ ofin ti ba ninu awọn eeyan naa bi iroyin ṣe ro o, bẹẹ ni ijọba Naijiria ti ṣeleri lati fofin gbe awọn oloṣelu to lọwọ si rogbodiyan iwọde naa.

    Wọn ni wọn yoo mu awọn to wa nidii asia Russia ti wọn fi wọde ni Naijiria yii.

  12. Ìgboro ìlú Kaduna dá páropáro nítorí ìkéde kónílé-ó-gbélé

    Paroparo ni igboro ilu Kaduna tii ṣe olu ilu ipinlẹ Kaduna da lọjọ Iṣẹgun lẹyin ti ijọba ipinlẹ naa ti kede ofin konile-o-gbele lawọn ilu kan ni ipinlẹ naa.

    Aworan bi igboro ṣe ri ni ilu Kaduna.
    Aworan bi igboro ṣe ri ni ilu Kaduna.
    Aworan bi igboro ṣe ri ni ilu Kaduna.

    Ikede isede waye lẹyin ti awọn kọlọrọsi kan lo anfani iwọde ni ipinlẹ naa lati da wahala bii jagidijagan, fifọ ile iṣẹ ati ṣọọbu lati jale silẹ.

    Awọn kan lara awọn oluwọde naa tun n gbe aṣia orilẹede Russia kaakiri lasiko iwọde naa.

    Aworan bi igboro ṣe ri ni ilu Kaduna.
  13. Kò sí ọlọ́pàá tó yìnbọn lásìkò iwọ́de -Ọ̀gá Ọlọ́pàá Nàìjíríà

    Aworan awọn ọlọpaa kan

    Oríṣun àwòrán, Police NG/X

    Ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria Kayọde Ẹgbẹtokun ti sọ pe ko si ọlọpaa kankan to yinbọn lasiko iwọde to waye kaakiri awọn ipinlẹ kan ni Naijiria.

    Ọga agba ọlọpaa lorilẹede Naijiria, lo ṣalaye ọrọ yii eyi lasiko to fi n sọrọ lori ihuwasi awọn ọlọpaa lasiko iwọde yii.

    Ọga ọlọpaa Naijiria naa ṣalaye pe awọn oluwọde gan lo n doju ija kọ awọn ọlọpaa atawọn agbofinro yoku.

    O ni ninu iwadii awn adari ileeṣẹ ọlọpaa ati ileeṣẹ ọmọogun gbogbo lẹyin ipade wọn, ko si eyikeyi ninu awọn agbofinro to yin ibọn.

    “Awọn ọlọpaa tabi awọn ologun ko lo ọta ibọn lati koju awọn oluwọde. Dipo bẹẹ awọn ọlọpaa la ri ti wọn fi ara ṣeṣe loniranran ti wọn si wa lẹsẹ kan aye ẹsẹ kan ọrun bi a ṣe n sọrọ yii.”

    Gẹgẹ bi ọrọ rẹ, afẹfẹ tajutaju nikan lawọn ọlọpaa lo lasiko iwọde ọhun.

  14. Àwọn adarí olùwọ́de ní Bauchi, Katsina Kano, Kaduna àti Katsina wulẹ̀ fi ìwọ́de bojú láti hùwà ọ̀daràn ni

    Awọn oluwọde pẹlu aṣia orilẹede Russia

    Oríṣun àwòrán, channels tv

    Ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria ni awọn to ṣe akojọpọ iwọde Ebi n panu #EndBadGovernance ni ipinlẹ Bauchi Kano, Kaduna ati Katsina lo anfani iwọde naa lati fi lo awọn ọmọde kan hu iwa ọdaran ni.

    Ninu atẹjade kan ti ileeṣẹ ọlọpaa fi sita, eyi ti alukoro ileeṣẹ ọlọpaa, Olumuyiwa Adejọbi fi sita ṣalaye pe iwadii ti n waye lati fi oju gbogbo awọn to wa nidi iwa ọdaran naa sita.

    Atẹjade naa ni o le lẹdẹẹgbẹrun awọn eeyan ti ọwọ ofin ti ba bayii gẹgẹ bi afurasi lori iwa ọdaran lilo aṣia ilẹ okeere lorilẹede Naijiria.

  15. Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ àwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè tó ń ṣagbódegbà ìwọ́de pẹ̀lú àṣíá Russia

    Awọn oluwọde pẹlu aṣia orilẹede Russia

    Ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria ni ọwọ awọn ti tẹ awọn ọmọ ilẹ okeere kan ti wọn funrasi pe wọn n ṣe agbodegba fun awọn to n lo aṣia orilẹede Russia fi ṣe iwọde lawọn agbegbe kan lapa oke ọya lorilẹede Naijiria.

    Kmiṣọna ọlọpaa ni ipinlẹ Kano, Salman Garba lo sọ eyi lẹyin ipade abo ti wọn ṣe pẹlu gomina ipinlẹ Kano, Abba Yusuf lọjọ Iṣẹgun.

    Gẹgẹ bi o ṣe wiawọn ọlọpaa atawọn agbofinro yooku yoo ya bo gbogbo awọn to ba n domi alaafia ru ni ipinlẹ naa.

    Bakan naa lo tun kede pe wọn tidẹ okun ofin isede to wa nilẹ nipinlẹ naa kuro ni agogo mẹfa aarọ si mẹfa irọlẹ.

  16. Àwọn olùwọ́de jí ìbọn àtàwọn ẹrù òfin míràn kó lásìkò tí wọ́n fọ́ ilé ẹjọ́ ní Kano

    Awọn oluwọde kan atawọn ẹru ti wọn ji ko

    Oríṣun àwòrán, dailytrust

    Alukoro fun ileeṣẹ eto idajọ ni ipinlẹ Kano, Baba Jibo Ibrahim ni wọn ti gbe igbimọ kan kalẹ lati ṣe akọsilẹ awọn ẹru ofin ti awọn oluwọde ji ko lọ lasiko ti wọn fi fọ awọn ile ẹjọgiga ipinlẹ naa.

    Alukoro ileeṣẹ eto idajọ ni ipinlẹ Kano ni ibọn atawọn ohun ija oloro loriṣiriṣi lo wa ninu ohun ti awọn oluwọde naa ji ko lọ.

    Ninu ọrọ to ba ileeṣẹ iroyin Daily Trust sọ lọjọ Aje, ni titi di asiko ti ifọrọwerọ naa fi waye,wọn ṣi n ṣe akọsilẹ awọn ohun ti wọn ji ko lọ ni ile ẹjọ naa.

    Àwọn olùwọ́de jí ìbọn àtàwọn ẹrù òfin míràn kó lásìkò tí wọ́n fọ́ ilé ẹjọ́ ní Kano.

  17. Ọwọ́ DSS tẹ àwọn télọ̀ tó ń rán àṣíá Russia fún àwọn olùwọ́de ní Kano

    Aworan awọn agbofinro DSS kan

    Oríṣun àwòrán, Getty Images

    Ọwọ awọn oṣiṣẹ agbofinro DSS lorilẹede Naijiria ti tẹ awọn aranṣọ to n ran aṣia orilẹede Russia fun awọn oluwọde niilu Kano.

    Ileeṣẹ agbofinro DSS ni ọwọ tẹ awọn telọ naa ti wọn n ran awọn aṣia ti wọn n pin kaakiri ipinlẹ naa.

    Bakan naa ni ileeṣẹ agbofinro DSS tun fi kun un pe ọwọ awọn ti tẹ awọn to gbe iṣẹ naa fun wọn., bẹẹ ni iwadi awọn ṣi n tẹsiwaju lori rẹ.

    Ọmilẹgbẹ awọn oluwọde lapa ariwa orilẹede Naijiria ni wọn n mu aṣia orilẹede Russia kiri lasiko iwọde to n waye nibẹ.

  18. Ìjọba ìpínlẹ̀ Kaduna kéde kónílé-ó-gbélé

    Aworan gomina ipinlẹ Kaduna

    Ijọba ipinlẹ Kaduna ti kede konile-o-gbele oniwakati mẹrinlelogun ni olu ilu ipinlẹ naa ati ilu Zaria.

    Ijọba ipinlẹ naa gbe igbesẹ yii “lẹyin ayẹwo ipo ti eto abo wa ni ipinlẹ naa nipasẹ iwọde to n waye” lẹyin ti awọn iwọde waye lawọn agbegbe kan ni ipinlẹ naa.

    Atẹjade kan ti ijọba ipinlẹ Kaduna fi sita sọ pe “ẹri to daju wa pe awọn kọlọrọnsi kan ti ja iwọde naa gba, wọn si ti bẹrẹ si nii lo o lati fi jale ati lati ba awọn dukia ijọba jẹ.”

    Samuel Aruwan kọmiṣọna fun ọrọ abo ni ipinlẹ Kaduna, to fọwọ si atẹjade naa rọ awọn eeyan ipinlẹ naa lati maa tẹle ofin ki wọn si wa ninu ile koowa wọn, lasiko ti awọn agbofinro ba n ba iṣẹ wọn lọ lati rii pe abo to peye wa fun gbogbo mutumuwa nibẹ.

    Awọn ipinlẹ miran to ti kede ofin konile-o-gbele lati igba ti iwọde yii ti bẹrẹ ni Ọjọbọ ni Kano, Jigawa, Borno, Yobe, Kaduna ati Plateau.

    Amọṣa awọn kan lara awọn ipinlẹ naa ti wọgile ofin naa.

  19. Ààrẹ Tinubu sún ìpàdé ìgbìmọ̀ ìṣèjọba àpapọ̀ síwájú láti fikùlukù pẹ̀láwọn adarí iléeṣẹ́ àbò

    Aworan Aarẹ tinubu

    Oríṣun àwòrán, Asiwajubolatinubu/x

    Àkọlé àwòrán, Aarẹ Tinubu ba awọn ọmọ Naijiria sọrọ lowurọ ọjọ Aiku nibi to ti pe fun ijiroro ati ifikuluku lati dẹkun iwọde to ti gbode kan

    Aarẹ Bọla Tinubu ti sun ipade igbimọ iṣejọba to ga julọ ni Naijiria, FEC to yẹ ko waye lọjọ Aje siwaju di ọjọ miran ọjọ ire, lati le ṣe ipade pẹlu awọn olori ẹka ologun gbogbo lorilẹede Naijiria.

    Igbesẹ yii ko fẹẹ ṣẹyin bi nnka ṣe n lọ pẹlu iwọde ebi-n-panu #EndBadGovernance to n waye lawọn ipinlẹ kan lorilẹede Naijiria ninu eyi awọn eeyan ti n fi ẹhonu han lori bi igbayegbadun araalu ti ṣe dẹnukọlẹ lẹnu lọwọlọwọ yii.

    Lara awọn ti yoo wa nibi ipade naa ni igbakeji aarẹ orilẹede Naijiria, olubadamọran agba lori ọrọ abo lorilẹede Naijiria NSA,awọn olori ẹka ileeṣẹ ologun gbogbo, ọga agba ileeṣẹ ọlọpaa, ọga agba ileeṣẹ aṣọbode ati ileeṣẹ wọlewọde Naijiria pẹlu adari awọn oṣiṣẹ to n ba aarẹ ṣiṣẹ.

    Aarẹ Tinubu ba awọn ọmọ Naijiria sọrọ lowurọ ọjọ Aiku nibi to ti pe fun ijiroro ati ifikuluku lati dẹkun iwọde to ti gbode kan lorilẹede Naijiria lati Ọjọbọ.

    Amọṣa iwọde ṣi n lọ lawọn ilu bii Kano, Eko Abuja, Kaduna atawọn ipinlẹ melokan miran.

  20. Nítorí pé ojú bọ̀rọ̀ kò lè gba ọmọ lọ́wọ́ ẹ̀kùrọ́ Tinubu ni ìwọ́de wa ṣe tẹ̀sìwájú" - Àwọn olùwọ́de

    Awọn oluwọde
    Àkọlé àwòrán, Awọn oluwọde

    Iwọde awọn ọmọ Naijiria to n ke irora lati fi opin si iṣejọba buburu lorilẹede yii tun tẹsiwaju n'ipinlẹ Ọyọ lonii.

    Iwaju fasiti ilẹ Ibadan ni awọn oluwọde naa korajọpọ si gẹgẹ bi iṣe wọn. Ọkanojọkan kan akọle to n tọka ẹdun ọkan wọn ati awọn ẹtọ ti wọn n beere lọwọ ijọba ni wọn gbe lọwọ nibi iwọde naa.

    Ọkan lara awọn alakoso iwọde naa to sọrọ lowurọ oni, Ọjọgbọn Ademọla Arẹmu ṣe alaye wi pe lootọ ni Aarẹ Bọla Tinubu ba awọn Naijiria sọrọ lọjọ Aiku nitori iwọde ti wọn n ṣe, ṣugbọn Aarẹ kuna lati mẹnuba koko nnkan ti awọn oluwọde n pe fun.

    Arẹmu ni awọn oluwọde ko le ri ohunkokohun gba bi wọn ko ba fi ọwọ lile mu ijọba orilẹede yii.

    O ni awọn aṣẹyọri gẹgẹ bi ọlọdani lasan ti awọn eeyan ilu ko ri ipa rẹ ni gbogbo nnkan ti Aarẹ Tinuba ka ninu ọrọ ti o ba wọn sọ lọjọ Aiku.

    O ke si ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ labẹ aburada, NLC, TUC, NBA ati ẹgbẹ awọn ọdọ lati darapọ mọ iwọde naa lati le mu ki ijọba Tinubu ṣe ohun ti awọn eeyan ilu fẹ ni dandan.

    Lara ohun ti awọn oluwọde naa n pe fun ni idapada owo epo Bẹntiro si ẹta din ni igba Naira,atunṣe gbogbo awọn ileeṣẹ ti wọn ti n fọ epo to jẹ ti orilẹede yii, idapada owo ina ọba si iye to wa tẹlẹri, eto ẹkọ ọfẹ ati bẹẹ bẹẹ lọ.

    Awọn oluwọde
    Àkọlé àwòrán, Awọn oluwọde
    Awọn oluwọde
    Àkọlé àwòrán, Awọn oluwọde