Ìdí tí mo fi fẹ́ gba adé 'onípáálí' lẹ́yìn tí mo ti ní mi ò fẹ́ tẹ́lẹ̀ rèé - Ladoja

Lẹyin ti iroyin ti gbode kan pe Ọtun Olubadan Ilẹ Ibadan, Oloye Rashidi Ladoja, ti ni oun yoo gba ade onipaali to ti figba kan loun ko fẹ, ni oriṣiiriṣii ọrọ ti n ṣẹyọ lori ipinnu gomina Ọyọ tẹlẹ naa.
Ohun ti a gbọ ni pe ọsẹ yii ni Oloye Ladoja yoo gba ade ọhun paapaa, ko ni i pẹ rara.
Nigba to n ṣalaye idi to fi fẹẹ gba ade ‘onipaali’, gẹgẹ bo ṣe pe e lasiko ti gomina, Oloogbe Abiola Ajimobi n fun awọn agba oye Ibadan yooku lade naa, Ladọja ni,
‘’pe mo pinnu lati gba ade ko tumọ si pe mo ti di ọba, ikilọ kan to wa nibẹ niyẹn.
‘’Mo pinnu lati gba ade yii nitori ipa ti awọn ọmọ Ibadan ati awọn ti ki i ṣe ọmọ Ibadan ko lori ọrọ naa.
‘’Mo gbe ijọba Ologbe Abiola Ajimobi lo si kootu lori ọrọ yii, mo si jare, ko too di pe wọn pe ẹjọ Ko-tẹ-mi-lọrun.
‘’Ẹjọ naa ṣi wa ni kootu ti Ọba Saliu Adetunji fi waja.
‘’Wọn rọ mi pe ki n jawọ lori ẹ ko ma baa di iyansipo Ọba Oloogbe Lekan Balogun lọwọ, mo si gba’’
‘’Lẹyin ti wọn fi Balogun jọba tan ni ijọba Ṣeyi Makinde tun gbe ọrọ ade ilẹkẹ yii jade, nigba ti mi o si ba wọn da si i tẹlẹ, ko sohun to kan mi lati gba a’’
‘’Ìjọba Makinde fẹ́ kí n di Olúbàdàn ni wọ́n fi ní dandan lade ìlẹ̀kẹ̀’’

Oríṣun àwòrán, @Seyi
Ninu alaye ti Oloye Ladoja ṣe fawọn akọrorin nilee rẹ n’Ibadan lo ti ni bi oun ko ṣe gba ade naa nigba yẹn ko dun mọ igbimọ afọbajẹ Olubadan ninu.
O ni idi niyẹn ti wọn ṣe dunkooko lati ma fa oun kalẹ bi asiko ba to foun lati di Olubadan.
“Niṣe ni mo ni lati pada si kootu lati ja fun ẹtọ mi, ṣugbọn a pada fi ẹjọ naa silẹ nigba ti awọn eeyan nla-nla ọmọ Naijiria da si i .
Nnkan miran to tun fa awuyewuye bi Ladoja ṣe wi, ni ti abala to n kede ade ilẹkẹ naa ti wọn fi sinu iwe lasiko igbade Olubadan tuntun, Ọba Owolabi Olakuleyin.
‘’Emi o ni iwe eto naa lọwọ, ṣugbọn awọn to ri i sọ fun mi.
‘’Bo tiẹ jẹ pe awọn eeyan ro pe nitori temi ni wọn ṣe ṣe bẹẹ, ero temi yatọ lori ẹ. Mo ni ijọba Makinde fẹẹ ki n di Olubadan ni, ohun ti wọn n sọ ni pe aigbade yii nikan lo le di mi lọwọ lati ma di Olubadan.“
‘’Ariwo sọ lori ọrọ ade naa, ọpọ eeyan lo ni Ladoja ko gbọdọ gba ade to ti kọ silẹ tipẹ.
‘’Ṣugbọn nigba to jẹ ida mejidinlọgọrun-un (98%) eeyan lo fẹ ki n di Olubadan, ko sohun ti mo le ṣe ju ki n tun ero naa pa, ki n si beere lọwọ awọn eeyan to yẹ.’’
Awọn olori ẹsin atawọn yooku ti Ladoja fi ọrọ naa lọ ni wọn ni ko lọọ gba ade ilẹkẹ naa bo ṣe wi, eyi si ni idi rẹ ti Ọtun Olubadan, Rashidi Adewolu Ladoja yoo fi gba ade naa laipẹ rara.
Kò sí ohun tó lè dí mi lọ́wọ́ láti di Olúbàdàn – Ladoja

Gomina ipinlẹ Oyo nigba kan ri, Sẹnetọ Rashidi Ladoja ti sọ pe oun ti ṣetan lati de ade idẹ, to ba jẹ pe ọna kan ṣoṣo niyẹn lati di Olubadan ilẹ Ibadan.
Oloye Ladoja, eni to tun ti figba kan ri jẹ Sẹnetọ ni Naijiria sọ pe ko si gbogbo idiwọ ati idena ti wọn gbe ka iwaju oun, to le di oun lọna lati di Olubadan.
Ladoja lo sọrọ yii lori eto Agbami Oṣelu ti ileeṣẹ redio Fresh FM to wa niluu Ibadan, ipinlẹ Oyo.
Nibẹ lo ti sọ pe to ba jẹ ọna kan ṣoṣo to le di oun lọwọ lati de ipo toun ti n foju sọna fun lati ọdun to ti pẹ sẹyin niyẹn, ko si nnkan to da oun duro lati de ade naa.
Ipo Olubadan lo jẹ pe awọn oloye agba nilẹ Ibadan ni wọn n jẹ ẹ, iyẹn awọn to wa ni ipo bii Balogun ati Ọtun.
Ladoja ninu ọrọ rẹ sọ pe “Mo maa de ade naa to ba jẹ pe ohun ni yoo di mi lọwọ lati di Olubadan tilẹ Ibadan.”
Baba naa tẹsiwaju pe Ọlọrun ti ṣaanu oun de ibi to ni apẹẹrẹ, to si loun ti ṣe gbogbo ohun to yẹ lati di Olubadan.
Bakan naa lo jẹ ko di mimọ pe ọpọ lo n foju sọna lati di Olubadan, ṣugbọn ti ko si anfaani fun wọn.
O ni ọpọ lo ti de ipo Balogun tabi Ọtun Olubadan, ṣugbọn ti wọn ko de ipo Olubadan nitori pe kii ṣe ayanmọ wọn lati debẹ, to si loun yoo de ori itẹ ọhun.
“Nipa oore ọfẹ Ọlọrun, mo maa di Olubadan. Ọlọrun ti ṣaanu fun mi. Gbogbo ifunpa mi to ga soke ti lọ silẹ bayii, mo si ti wa ni ilera pipe.
“Ẹnikẹni ti Ọlọrun ba ti kadara wi pe yoo di Olubadan, danda ni ko de ipo Olubadan. Ko si oniruuru idena ti wọn le gbe soju ọna, bi Ọlọrun ba ti sọ pe yoo di Olubadan, o maa di Olubadan ṣaa ni.
“Asiko aburo mi, Abiola Ajimobi ni wọn bẹrẹ gbogbo eto yii, mo si bori. O ti wa nilẹ tipẹ. Ohun ti mo mọ ni pe Olubadan lo yẹ ko ṣe awọn ayipada, kii ṣe gomina.
“Ohun ti awọn ara Ibadan ba fẹ ki n ṣe ni maa ṣe. Ọlọrun si ni eleto. A ni ọpọ awọn ti wọn di Balogun ṣugbọn ti wọn ko di Olubadan.
Ladoja pari ọrọ ré pe “A ti ni ọpọ awọn to de ipo Ọtun Olubadan ṣugbọn ti awọn naa ko di Olubadan. Aarin ọjọ mẹwaa sira wọn ni Omiyale ati Kuye jade laye.”















