Ta ni ẹni tó kọ́kọ́ gbé ipò kìíní ní ìdíje Olympics fún Áfíríkà?

Abebe Bikila in running vest at the finish line of a marathon

Oríṣun àwòrán, Getty Images

    • Author, Marta Pausilli & Priya Sippy
    • Role, BBC News
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Ní ọdún 1960, ọmọ adaranjẹ̀ kan, láì wọ bàtà, ya gbogbo ayé lẹ́nu fi ìtàn balẹ̀ fún ilẹ̀ Áfíríkà ní Rome, níbi ìdíje Olympics.

Ní alẹ́ ọjọ́ náà, níṣe ni àwọn ọmọ ogun Italy tò sí ẹsẹ̀ títì, tí wọ́n tan iná dání bí ọmọ orílẹ̀ èdè Ethiopia kan, Abebe Bikila ṣe sáré dé òpin ilà ìdíje eré sísá àsáyípo.

Nígbà tí wọ́n ń bá eré sísá wọn lọ, Bikila nínú ṣòkòtò péńpé púpà àti aṣọ dúdú rẹ̀, ní òun Rhadi Ben Abdesselem láti Morocco jọ ń wàákò.

Àmọ́ nígbà tó ku máílì kan kí eré sísá náà parí ni Bikila bẹ̀rẹ̀ sí ní já Abdesselem sílẹ̀, ó sáré dé ibi ilà tí ìdíje náà parí sí, tó sì nawọ́ sókè pé òun ti ṣetán.

Yàtọ̀ sí pé ìgbà àkọ́kọ́ tí Bikila yóò kóp nínú ìdíje náà nìyí, òun ni Adúláwọ̀ àti ọmọ Ethiopia àkọ́kọ́ tí yóò gba ipò kìíní nínú ìdíje Olympics.

Nípa èyí ló fi fìtàn tuntun lélẹ̀ ní àgbáyé gẹ́gẹ́ bí ẹni tó parí eré sísá náà ní wákàtí méjì, ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀dógún àti ìṣẹ́jú àáyá mẹ́rìndínlógún.

Oríire rẹ̀ yìí ya ọ̀pọ̀lọpọ̀ lẹ́nu nítorí pé yàtọ̀ sí pé ìgbà àkọ́kọ́ tó ń kópa níbi ìdíje náà nìyí, Bikila kò wọ bàtà tó fi sá gbogbo eré tó sá náà.

Bikila kò fi bàtà sáré ìdíje náà nítorí bàtà rẹ̀ ti bàjẹ́ tó sì rò ó pé tí òun bá ní kí òun ṣẹ̀ṣẹ̀ máa wá bàtà tuntun le fa ìdíwọ́ fún òun.

Tim Judah tó jẹ́ òǹkọ̀wé ilẹ̀ Britain, tó ti kọ̀wé nípa Bikila ní ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ tí àwọn mọ̀ ni pé àwọn tí wọ́n máa ń gbégbá orókè nínú ìdíje náà máa ń jẹ́ ojú mímọ̀ àmọ́ Bikila kìí ṣe ẹni tí a mọ̀ rárá.

“Èyí jẹ́ kí jíjáwé olúborí ọmọ ilẹ̀ Áfíríkà tí kò wọ bàtà yàwá lẹ́nu púpọ̀.”

Abebe Bikila ń sáré àsáyípo láì wọ bàtà

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìpàdé akọni ni wọ́n fún Bikila nígbà tó padè dé orílẹ̀ èdè rẹ̀ lẹ́yìn ìdíje náà.

Àmọ́ ìjáwé olúborí rẹ̀ yìí jẹ́ kó di èèyàn mímọ̀ kọjá orílẹ̀ èdè rẹ̀ nìkan.

“Ìgbà yìí ni àwọn amúnisìn ń kúrò ní Áfíríkà, tí àwọn Áfíríkà náà ń hàn sáyé,” Judah sọ.

“Èyí ló jẹ́ kí ìjáwé olúborí rẹ̀ dàbí ìrètí nígbà náà.”

Àmì gbígbé igbá orókè nígbà náà ṣì ń tẹ̀síwájú títí di àsìkò yìí.

“Tí ẹ bá wo nǹkan tó ṣẹlẹ̀ ní Áfíríkà, ẹ máa ri pé lẹ́yìn tí Bikila gbé ipò kìíní ní Rome ni àwọn orílẹ̀ èdè Áfíríkà bẹ̀rẹ̀ sí ní gba òmìnira,” èyí ni ọ̀rọ̀ tó jáde lẹ́nu Haile Gebrselassie tó ti fìgbà kan rí jẹ́ akọni nínú eré sísá ní ìdíje Olympic àti àgbáyé.

Nígbà tí Bikila padà sí orílẹ̀ èdè rẹ̀, iléeṣẹ́ ìròyìn Kenya, Nation ròyìn pé Ọba Haile Selassie fún ní oyè èèkàn ìlú Ethiopia. Bákan náà ni wọ́n fun ní ilé àti ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ Volkswagen Beetle.

Bí Bikila ṣe bẹ̀rẹ̀ ayé rẹ̀

Ọmọ atẹrọ̀fọ̀ dìde ni Bikila, tí bí ó ṣe dàgbà jìnà sí àwọn nǹkan tó ń rí lẹ́yìn tó jáwé olúborí níbi ìdíje Olympic.

Ọdún 1932 ni wọ́n bi ní ìlú Jato, orílẹ̀ èdè Ethiopia. Adaranjẹ̀ ni bàbá rẹ̀.

Gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́ lẹ́yìn tó kó lọ sí Addis Ababa, ó darapọ̀ mọ́ ẹ̀ṣọ́ Imperial Guard, tí wọ́n sì pin sí ilé ọba láti máa ṣọ́ ọba Haile Selassie.

Níbẹ̀ ló ti pàdé akọ́niléré ọmọ ilẹ̀ Sweden, Onni Niskanen, tí ìjọba Ethiopia gbà láti ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ fún àwọn ọmọ ogun orílẹ̀ èdè Ethiopia, tó ri pé ó ní ẹbùn eré sísá.

Niskanen bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ Bikila ní eré sísá láti díje fún eré àsáyípo.

Àmọ́ nígbà tí wọ́n fẹ́ lọ fún ìdíje Olympic ní Rome, Wami Biratu, tó jẹ́ ẹnìkejì Bikali ni wọ́n fẹ́ mú lọ pé òun lọ mọ eré sá jùlọ ṣùgbọ́n nígbà tó ku ọjọ́ díẹ̀ tí wọ́n máa lọ ni Biratu bẹ̀rẹ̀ àárẹ̀, tí kò sì lè kópa nínú ìdíje náà mọ́.

Abebe Bikila káwọ́ sókè lẹ́yìn tún gbé ipò kìíní níbi ìdíje Olympic fún ìgbà kejì

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Gbígbé ipò kìíní ní ìdíje Olympic fún ìgbà kejì

Níbi ìdíje Olympic ọdún 1964 tó wáyé ní Tokyo ló ti fi ọba le nígbà tó tún gbé ipò kìíní nínú ìdíje eré àsáyípo kan náà, òun ni ẹni àkọ́kọ́ tí yóò gbé ipò kìíní tẹ̀lé ara wọn ní ìdíje náà.

Títí ti di àsìkò Bikila jẹ́ ọ̀kan lára àwọn eléré sísá mẹ́ta tó gbé ipò kìíní tẹ̀lé ara wọn. Àwọn méjì yòókù ni Cierpinski àti Eliud Kipchoge.

Nígbà ìkejì yìí, Bikali wọ bàtà àmọ́ tó tún kojú ìpèníjà mìíràn.

Ó ku ogójì ọjọ́ tí ìdíje náà máa wáyé ni ó ṣe iṣẹ́ abẹ.

Síbẹ̀, bó ṣe jẹ́ pé ó ṣẹ̀ṣẹ̀ gbádùn ni, ó tún fìtàn balẹ̀ ní Tokyo bí ó ṣe parí eré sísá ní wákàtí méjì, ìṣẹ́jú méjìlá àti ìṣẹ́jú àáyá mọ́kànlá.

Gẹ́gẹ́ bí àkọ́ọ́lẹ̀ World Athletics, ìdíje eré sísa àsáyípo àgbáyé méjìlá nínú mẹ́tàlá ni Bikila ti gbégbá orókè láàárín ọdún 1960 sí 1966.

Àmọ́ ọdún márùn-ún lẹ́yìn tó gbégbá orókè ní ìdíje Olympic kejì, ìṣẹ̀lẹ̀ kan ṣẹ̀.

Abebe Bikila jókòó nínú kẹ̀kẹ́ arọ tó ń ta ọfà

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Bíborí ìjàmbá ọkọ̀

Nínú oṣù Kẹta, ọdún 1969, ìròyìn ní Bikila ní ìjàmbá ọkọ̀ pẹ̀lú ọkọ̀ Volkswagen Beetle rẹ̀ èyí tó sọ ọ́ di arọ láti ibi ọrùn rẹ̀ títí délẹ̀.

Ilé ìwòsàn Stoke Mandeville ní orílẹ̀ èdè England ni wọ́n gbe lọ fún ìtọ́jú ọ̀pá ẹ̀yìn rẹ̀ àmọ́ tó ní láti gbà pé òun kò lè fi ẹsẹ̀ rẹ̀ méjéèjì rìn mọ́.

Nígbà tó bẹ̀rẹ̀ sí ní ọwọ́ rẹ̀ méjéèjì lò padà ló tún bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣe eré ìdárayà míì bíi bọ́ọ̀lù orí tábìlì.

Ní ọdún 1970 ló kópa nínú ìdíje Stoke Mandeville Games ní London gẹ́gẹ́ àkàndá.

Ọdún tó tẹ̀le ló tún díje ní Norway níbi tó ti gbégbá orókè nínú ìdíje sleigh-riding tó wà fún àwọn àkàndá.

Àwọn èrò gbe Abebe Bikila sókè

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Orípa rẹ̀ ń tẹ̀síwájú

Ní ọdún 1973 ni Bikila jáde láyé lẹ́ni ọdún mọ́kànlélógójì látàrí àwọn ìpèníjà tó kojú lẹ́yìn ìjàmbá ọkọ̀ tó ní.

Ọba Haile Selassie kéde ìsìnmi ọjọ́ kan láti fi dárò Bikila tí wọ́n sì ṣe òkú rẹ̀ bíi ti èèkàn ìlú.

Bí ó ṣe jẹ́ pé Bikila kò pẹ́ láyé, orúkọ rẹ̀ kò parun. Pápá ìṣeré tí wọ́n sọ ní orúkọ rẹ̀, Abebe Bikila wà ní Addis Ababa, tí ọ̀pọ̀ ilé ẹ̀kọ́ sì wà ní orúkọ rẹ̀ dòní.

Orípa Bikila tí kò lè parẹ́ láéláé ni jíjẹ́ ìwúrí fún àwọn eléré sísá ní ìlà oòrùn Áfíríkà tí wan ń rìn ní ìlànà rẹ̀.

Ọ̀pọ̀ àwọn eléré ní Ethiopia àti Kenya bíi Haile Gebrselassie àti Eliud Kipchoge ni wọ́n léwájú nínú eré ìdárayà náà báyìí.

“Èrè iṣẹ́ Abebe Bikila ni àwa eléré sísá Áfíríkà báyìí. Nítorí Abebe Bikila ni mo ṣe di eléré sísá àgbáyé báyìí,” Gebrselassie SỌ.

Getnet Wale Tó ń ṣojú Ethiopia nínú ìdíje 3000m steeplechase ní ìdíje Paris Olympics jùwe Bikila bíi ẹni tó la ọ̀nà kalẹ̀ fún wọn.

“Òun ni ẹni àkọ́kọ́. Títí di àsìkò yìí ni à ń rántí rẹ̀.”