Ojú òpó ìbáraẹnisọ̀rọ̀ ‘WhatsApp’ fẹ́ kúrò ní Naijiria, ohun tó fà á rèé

Àwòrán ojú òpó WhatsApp
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Gbajugbaja ni oju opo ibaraẹnisọrọ ti a mọ si WhatsApp jẹ lorilẹede Naijiria, oun loju opo to ya ju tawọn eeyan fi n kan sira wọn, ṣugbọn o ṣee ṣe ki WhatsApp ma ṣiṣẹ mọ ni Naijiria.

Ajọ kan to n ri si idaboobo awọn onraja, Federal Competition and Consumer Protection Commission (FCCPC) lo ni WhatsApp n tẹ ẹtọ awọn ọmọ Naijiria mọlẹ labala data lilo.

FCCPC tun fẹsun kan WhatsApp pe wọn ki i jẹ kawọn ọmọ Naijiria lagbara lorii data wọn ti wọn ba ra.

Wọn ni wọn tun maa n pin data awọn ọmọ Naijiria lai jẹ pe wọn gba aṣẹ lọwọ awọn to fowo ra data ọhun.

Bakan naa ni wọn ni Whatsapp tun n ṣe ojusaaju si awọn ọmọ Naijiria to n lo oju opo yii.

Wọn ni awọn ofin irẹnijẹ ni wọn n ṣe fawọn ọmọ Naijiria, ko si siru ẹ lawọn ilu mi-in ti wọn ti n lo WhatsApp kan naa.

Fun idi eyi, ajọ FCCPC paṣẹ pe ileeṣẹ Meta to ni WhatsApp gbọdọ dẹkun awọn nnkan wọnyi, wọn ni ki wọn ye yan awọn ọmọ Naijiria jẹ.

Yatọ si eyi, ajọ FCCPC ati abojuto Nigeria Data Protection Regulation (NDPR), paṣẹ pe WhatsApp gbọdọ san owo itanran $220 million, ti wọn ko fi ni i tẹ ẹtọ onibaara wọn loju mọ lọjọ iwaju.

Wọn ni awọn gbe igbesẹ yii lati da aabo bo ẹtọ awọn eeyan to n lo oju opo yii ni Naijiria, ati pe nibo mi-in naa ti WhatsApp ti lufin yii, ijiya kan naa lawọn fun wọn.

Iyẹn ko sọ pe ki wọn kuro ni Naijiria bi FCCPC ṣe wi, wọn ni ohun to jẹ ẹtọ kaakiri aye ko gbọdọ yatọ ni Naijiria lawọn n sọ.

WhatsApp fèsì

Ninu esi rẹ si ohun ti FCCPC n beere yii, WhatsApp sọ pe o ṣee ki oju opo yii ma ṣiṣẹ mọ lorilẹede Naijiria, wọn ni awọn le kuro nilẹ yii patapata.

Ileeṣẹ naa sọ pe ohun ti FCCPC n beere yii da bii ọna kan lati gbọ ti ẹnu awọn araalu ni .

Wọn rọ FCCPC lati yi ipinnu wọn pada lori ọrọ naa.

Ni bayii ṣaa, ero awọn eeyan ṣọtọọtọ lori igbesẹ yii.

Bawọn kan ṣe n sọ pe o dara bi FCCPC ṣe wadii WhatsApp yii, bẹẹ lawọn mi-in n beere pe ṣe awọn yoo ni ipin nibu $220m ti wọn ni ki ileeṣẹ naa san ni.

Awọn mi-in n sọ pe oju opo wo ni yoo tun da bii WhatsApp bi wọn ba fi le lọ nilẹ yii. Wọn ni yoo ṣoro lati ri oju opo mi-in ti yoo dabii WhatsApp to yara bi aṣa.

Ṣugbọn ṣaa, FCCPC duro lori ipinnu wọn, boya WhatsApp yoo mu tiẹ ṣe lawa o mọ.