Wo àwọn Ìpínlẹ̀ tí Ìwọ́de 'EndBadGovernance' kò tí wáyé

Awọn oluwọde kan
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Bí ìwọde ebi n panu ṣe bẹrẹ lawọn ipinlẹ kan lorilẹede Naijiria lọjọbọ ọjọ kinni oṣu kẹjọ, ọpọ awọn araalu lo tu sita lati fẹhonu han lori ọwọngogo to gbode.

Ìwọde yii waye ni ọpọ ipinlẹ ati ni Abuja tii ṣe olu ilu Naijiria, bi o ti lẹ jẹ pe ìwọde ọhun ko gbera sọ lawọn ipinlẹ kan lorilẹede.

Lara awọn ipinlẹ ti ìwọde ọhun ko ti waye ni ipinlẹ Ondo, Ekiti, Enugu ati ọpọ ipinlẹ lẹkun ila oorun NAijiria.

Niluu Abuja, awọn oluwọde kọkọ korajọpọ si papa isere Moshood Abiola to wa ni City Gate , ti wọn si n kọrin lọkan-o-jọkan lati fi ẹhonu wọn han nipa ebi,ìsẹ ati aini eto aabo to peye lorilẹ ede Naijiria.

Ọkan lara awọn oluwọde, Ọmọle Ibukunoluwa ni ko si ẹnikankan to n ti awọn lẹyin lati se eto iwọde yii to si jẹ pe awọn n se ìwọde naa nitori pe ebi n pa gbogbo ara ilu

Lara ohun ti wọn n bere fun ni ki wọn da owo epo pada si iye to wa tẹle ki ijọba yii to gba ijọba ni May 29, 2023

Ki wọn da owo ori ti wọn fi kun ina mọna-mọna ti wọn fi kun un pada

Kí lo waye nipinlẹ Ondo?

Igboro ilu Akurẹ, olu ilu ipinlẹ Ondo

Ní ipinlẹ Ondo, awọn oriko mejeeji ti o yẹ kawọn oluwọde ti pade n'ilu Akure, olu ilu Ipinlẹ Ondo lo da paroparo bi awọn ọdọ to ti n gbaradi fun iwọde ebi-n-panu naa ṣe kọ lati kopa l'Ondo.

Ileeṣẹ BBC Yoruba lọ si A Division ati Cathedral to jẹ oriko mejeeji to yẹ ki awọn oluwọde ti pade, awọn oriko yi da paroparo to si jẹ pe awọn Ọlọpa ni wọn wa ni awọn oriko naa.

Awọn Agbofinro lo wa ni gbogbo aarin igboro Akure eyi ti awọn ara ilu fi sọpe ifarahan awọn agbofinro lo fa ibẹrubojo eyi ti ko jẹ ki awọn ọdọ naa jade lati se iwọde.

Lasiko ti ileeṣẹ BBC Yoruba sabewo si ọja oba, gbogbo ile itaja lo wa ni titi pa latari ibẹru ohun to le waye lasiko iwọde naa.

Pupọ awọn eeyan to ba awọn akọroyin sọrọ niluu Akure salaye pe ibẹru bojo lo ba ọpọ eeyan to jẹ pe wọn sa pamọ si ile wọn.

Mo dupẹ gbogbo araalu - Kọmisọna Ọlọpaa ni Ekiti

Awọn eeyan kan n taja .
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Bakan naa nipinlẹ Ekiti, awọn ọlọpaa, soja, DSS, Civil Defence, road safety ati awọn Amotekun, lo wa kanpe ni isọri isọri kaakiri agbegbe fun iwọde ifẹhonuhan naa ni ilu Ado-Ekiti, olu ilu ipinlẹ Ekiti.

Nigbati akoroyin BBC News Yoruba lọ kaakiri awọn agbegbe bi Fajuyi Park, Oke iṣa, Post office, Oja-Ọba, ati Ijigbo roundabout lati ri pe katakara nlọ tí awon olugbe ilu Ado-Ekiti si n ba iṣe ojo wọn lọ.

Kọmisọna Ọlọpaa ni ipinlẹ Ekiti Adediran Akinwale ni oun dupẹ lọwọ awọn ara ilu Ekiti fun ifowosowopo wọn lori ifẹhonhan ti o yẹn ko waye pe wọn gbọran pé ki wọn ma jade fun iwode naa tori awọn jaduku ti o fẹ lo anfaani naa lati da rogbodiyan si le.

Komisana Ọlọpaa Akinwale fidi rẹ mulẹ pe alaafia yoo tun bo ma tesiwaju ni ipinlẹ Ekiti ati wipe titi di ọjọ oni, ko si ẹnikẹ́ni to ti jade lati wa fi to ile ise Ọlọpaa leti pe wọn fẹ ṣe iwode ifẹrunuhan kankan ni ipinlẹ Ekiti.

Lara awọn asoju ọdọ ati akeko ni ipinlẹ Ekiti to ba akọroyin soro ni Owolewa Taiwo ati Asaolu Femi ni awọn yi ìpinnu wọn tori awọn jaduku to fẹ lo anfaani iwode ifẹrunuhan lati ja awọn ara ilu lole ati lati da wahala silẹ ni ipinlẹ Ekiti.

Wọn rawọ ẹbẹ si Ijọba apapọ ati Gomina Biodun Oyebanji lati wa opin si gbogbo isoro to doju ko orile-ede Naijiria.

Awọn agba Yoruba Leaders of Thoughts naa tun ba akoroyin soro lori ewu ti o wa ninu iwode ifẹrunuhan ọlọjọ mẹwa naa.

Akowe agba fun egbe naa Bayo Aina ni looto ni gbogbo eniyen ni eto lati se iwọde ifẹrunuhan sugbon ki awọn ọmọ orile-ede Naijiria fun ara Tinubu ni anfaani diẹ ṣi lati yanju ebi ati osi ti o wa lori le ede wa.

Gbogbo awọn ara olugbe ipinle Ekiti lo n ba karakata wọn lọ lai wahala kankan.

Kotonnkan lawọn to jade lati wọde ni Kwara

Awọn oluwọde ni Ilọrin

Ni ilu Ilọrin ẹwẹ iwọnba lawọn to jade, koda wọn ko ju eyi ti oju le ka lọ.

Awọn melokan to yọju ni papa iṣire Metropolitan square ni ilu Ilọrin. Iye awọn agbofinmnro to fara han nibẹ gan pọ ju awọn oluwọde gan lọ.