Wo ìdí tí ìjọba ìpínlẹ̀ Kaduna fi tẹ̀lé ìgbésẹ̀ Kano, Yobe àtàwọn ìpínlẹ̀ míràn láti kéde kónílé-ó-gbélé

Ijọba ipinlẹ Kaduna ti kede konile-o-gbele oniwakati mẹrinlelogun ni olu ilu ipinlẹ naa ati ilu Zaria.
Ijọba ipinlẹ naa gbe igbesẹ yii “lẹyin ayẹwo ipo ti eto abo wa ni ipinlẹ naa nipasẹ iwọde to n waye” lẹyin ti awọn iwọde waye lawọn agbegbe kan ni ipinlẹ naa.
Atẹjade kan ti ijọba ipinlẹ Kaduna fi sita sọ pe “ẹri to daju wa pe awọn kọlọrọnsi kan ti ja iwọde naa gba, wọn si ti bẹrẹ si nii lo o lati fi jale ati lati ba awọn dukia ijọba jẹ.”
Samuel Aruwan kọmiṣọna fun ọrọ abo ni ipinlẹ Kaduna, to fọwọ si atẹjade naa rọ awọn eeyan ipinlẹ naa lati maa tẹle ofin ki wọn si wa ninu ile koowa wọn, lasiko ti awọn agbofinro ba n ba iṣẹ wọn lọ lati rii pe abo to peye wa fun gbogbo mutumuwa nibẹ.
Awọn ipinlẹ miran to ti kede ofin konile-o-gbele lati igba ti iwọde yii ti bẹrẹ ni Ọjọbọ ni Kano, Jigawa, Borno, Yobe, Kaduna ati Plateau.
Amọṣa awọn kan lara awọn ipinlẹ naa ti wọgile ofin naa.

Oríṣun àwòrán, Aminu Abdusalam@ Facebook
Ijọba ipinlẹ Kano ti sọ pe oun yoo fi ofin gbe awọn oloṣelu kan ti wọn fura si pe wọn lọwọ ninu rogbodiyan to waye lasiko iwọde to bẹrẹ lọjọ kin-in-ni oṣu kẹjọ, ọdun 2024.
Gẹgẹ bi Igbakeji gomina ipinlẹ Kano, Abdusalam Gwarzo, ṣe ṣalaye fun BBC, o ni awọn ti ri awọn ọrọ kan gbamu nipa awọn to da rogbodiyan iwọde naa silẹ, awọn yoo si gbe igbesẹ to kan laipẹ.
‘’A ko ṣi eeyan mu rara, a ni ẹri to daju nipa awọn oloṣelu to ko awọn janduku wa, wọn sanwo fun wọn lati waa daran yii ni. Awa naa si ti n gbọ oriṣiiriṣii nipa rẹ.
‘’A maa ri i daju pe ẹnikẹni to ba lọwọ si didaamu awọn eeyan nipinlẹ Kano foju ba ile ẹjọ. Ko si ariyajiyan kan, ẹni naa yoo foju ba ileẹjọ Sharia.’’
Igbakeji gomina Kano, Abdulsalam Gwarzo, lo sọ bẹẹ.
Nipa ofin konile-gbele to n lọ lọwọ nipinlẹ naa, ijọba ibẹ sọ pe yoo ṣi maa tẹsiwaju titi digba tawọn agofinro ba fidi ẹ mulẹ, pe awọn to ṣiṣẹ ibi naa ti fa ara wọn kalẹ, abi ki ọwọ ofin ba wọn.
Igbakeji gomina Kano yii rọ awọn obi lati mojuto awọn ọmọ wọn.
O ni ki wọn kọ wọn bi eeyan ṣe n nifẹ orilẹede rẹ, nitori jagidijagan ki i bimọ ire.
Ọwọ́ agbófinró tẹ afurasí 326, ìbọn AK47 méjì lásìkò ìwọ́de

Ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn ọmọde ati obinrin wa lara awọn afurasi ti ọwọ ba.
Ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Kano, ẹkun ariwa Naijiria ti ọwọ awọn ti tẹ awọn afurasi ọọdunrun o le mẹrindinlọgbọn ti wọn ni wọn lọwọ ninu wahala ati rogbodiyan to waye lasiko iwọde #EndBadGovernance to bẹrẹ lorilẹede Naijiria ni Ọjọbọ.
Ileeṣẹ ọmọogun ni awọn obinrin atawọn ọmọde wa lara awọn ti wọn gba mu.
Wọn ni awọn tun ri ibọn AK47 meji gba pada lọwọ wọn.
Iwọde [ebi n panu ti awọn ọmọ Naijiria kan gbe kalẹ̀ lọjọ kini oṣu kẹjọ ọdun 2024 bẹrẹ lalaafia ko to di wahala lawọn ipinlẹ kan.
Ni ilu Kano, awọn oluwọde fọ awọn ṣọọbu itaja atawọn ileeṣẹ nlanla kan ti wọn si ko awọn ẹru ati dukia olowo iyebiye salọ.
Nítorí àdúrà Jumat, Gómìnà Kano dẹwọ́ kónílé-ó-gbélé fún wákàtí díẹ̀

Oríṣun àwòrán, x/Abba Kabir Yusu
Ijọba ipinlẹ Kano ti gbẹsẹ kuro lori ofin konile-gbele oniwakati mẹrinlelogun to ṣe l’Ọjọbọ, ọjọ kin-in-ni, oṣu kẹjọ ọdun 2024.
Eyi ri bẹẹ nitori irun ọjọ Jimọ ti awọn olugbe ipinlẹ naa ni lati lọọ ki ni mọṣalaaṣi nla kaakiri ipinlẹ Kano lonii, ọjọ keji, oṣu kẹjọ ọdun 2024.
Atẹjade kan lati ọdọ ijọba ipinlẹ Kano, fidi ẹ mulẹ pe aaye wa fun awọn eeyan lati jade laarin aago mejila ọsan si aago marun-un irọlẹ, ki wọn lọọ kirun.
Ofin konile-gbele naa yoo tẹsiwaju lati aago marun-un irọlẹ titi ti nnkan yoo fi pada sipo.
Wọn rọ awọn olugbe Kano lati duro sile wọn lati aago marun-un irọlẹ oni, ọjọ keji, oṣu kẹjọ ọdun 2024, nitori ofin naa ṣi n ṣiṣẹ lọ.
Ẹ o ranti pe Gomina ipinlẹ Kano, Abba Yusuf, paṣẹ ofin konile-gbele ọhun lẹyin ti iwọde to n lọ lọwọ lorilẹde yii ba ibo mi-in yọ ni Kano.
Ole ti wọn n fi iwọde naa ja, pẹlu rogbodiyan to bẹ silẹ, ti wọn dana sun ile, mọto, ti ẹmi eeyan tun bọ lo fa a ti ijọba ibẹ fi paṣẹ konile-gbele fun wọn l’Ọjọbọ naa.

Gómìnà ìpínlẹ̀ Kano, Abba Kabir ti kéde òfin kónílé-ó-gbélé ní ìpínlẹ̀ náà lẹ́yìn tí ìwọ́de ebi ń panú di ohun tí àwọn èèyàn ń jálé, ba dúkìá jẹ́ lórí rẹ̀.
Káàkiri orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ni àwọn èèyàn ti ń ṣe ìwọ́de bẹ̀rẹ̀ láti òwúrọ̀ ọjọ́bọ̀, ọjọ́ Kìíní, oṣù Kẹjọ ọdún 2024.
Àmọ́ níṣe ni ọ̀rọ̀ bá ìbòmíràn yọ nígbà tí àwọn ọ̀dọ́ tó ń ṣe ìwọ́de ní ìpínlẹ̀ Kano yabo dúkìá ìjọba kan tí wọ́n sì ń kó àwọn nǹkan tó wà nínú rẹ̀ lọ.
Àwọn fídíò tó wà lórí ayélujára ṣàfihàn bí àwọn èèyàn náà ṣe ń kó àga, ẹ̀rọ kọ̀mpùtá àtàwọn nǹkan míì tó wà nínú ilé náà.
Mínísítà fétò ìbáraẹnisọ̀rọ̀, Bosun Tijani ní ibi tí àwọn èèyàn náà lọ ṣe ìkọlù sí jẹ́ ibi tí ìjọba pèsè láti fi kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé ẹ̀kọ́ girama nípa ìmọ̀ ẹ̀rọ.
Tijani ọ̀sẹ̀ tó ń bọ̀ ni àwọn ń gbèrò láti ṣí ibùdó náà èyí tí ìrètí wà pé ó máa pèsè iṣẹ́ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀dọ́.
Fídíò míì tún ṣàfihàn bí àwọn èèyàn ṣe ń kó oúnjé ní ṣọ́ọ̀bù àwọn èèyàn àti bí àwọn olùwọ́de ṣe ya lọ sí ilé ìjọba ìpínlẹ̀ Kano.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Àwọn ìròyìn kan ń sọ pé àwọn èèyàn kan pàdánù ẹ̀mí wọn nínú wáhàlá tó wáyé ní ìpínlẹ̀ náà àmọ́ BBC kò lè fìdí èyí múlẹ̀ títí di àsìkò tí à ń kó ìròyìn jọ.
Èyí ló mú kí gómìnà bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ níní ìkéde kan tó ṣe.
Gómìnà Yusuf ní ṣáájú ìwọ́de ní òun ṣèpàdé pẹ̀lú àwọn èèkàn ìlú ìpínlẹ̀ Kano, tí òun sì jẹ́ kó di mímọ̀ pé ẹ̀tọ́ wọn ni láti ṣe ìwọ́de àmọ́ ó gbọ́dọ́ wáyé ní pẹ̀lẹ́ kùtù àti àláfíà.
Gómìnà ní òun ti ṣáájú ṣèlérí fún àwọn èèyàn náà pé òun máa wà níkàlẹ̀ láti gbọ́ gbogbo ìbéèrè wọn àti pé gbogbo nǹkan tí wọ́n bá fẹ́ ni òun máa ṣe.
Ó ní òun máa fi gbogbo ìbéèrè wọn ránṣẹ́ sí ààrẹ Bola Ahmed.
Ó ṣàlàyé ṣáájú ni òun ti kọ́kọ́ gbàlejò àwọn tó ń ṣaájú ètò ìwọ́de náà nílé ìjọba tí wọ́n sì ti sọ gbogbo nǹkan tí wan ń fẹ́ fún òun tóun sì ti ṣàlérí láti jíṣẹ́ wọn fún ààrẹ.

Ó ṣo pé ó jẹ́ ohun ìbànújẹ́ fún láti ri pé ìwọ́de tó yẹ kó lọ wọ́ọ́rọ́wọ́ pàápàá fún àwọn tálákà àtàwọn aláìní ti di nǹkan táwọn jàǹdùkú ti jágbà.
Gómìnà náà ní àwọn jàǹdùkú náà wá lo àsìkò náà láti fi máa jálè, já ṣọ́ọ̀bù àwọn aládàni, tó fi mọ́ bíba àwọn dúkìá tó jẹ́ ti ìjọba jẹ́.
Ó sọ pé lẹ́yìn tí òun àtàwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò ìpínlẹ̀ náà foríkorí, tí àwọn fikùnlukùn ni àwọn pinnu láti ṣe ìkéde kónílé-ó-gbélé láti dènà dída omi àláfíà ìpínlẹ̀ náà rú ju bí ó ṣe wà lọ.
“Ìgbésẹ̀ yìí yóò ṣe ìdádúró bí àwọn ọ̀dàlúrú ṣe ń fi ìwọ́de bojú láti jalè, bá dúkìá jẹ́ àti ṣíṣokùnfà ikú àwọn èèyàn tí kò mọwọ́ mẹsẹ̀.”
Ó sọ pé ní ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ní kí òfin náà bẹ̀rẹ̀ láti dá ààbò bo ẹ̀mí àti dúkìá àwọn èèyàn.
Bákan náà ló rọ àwọn èèyàn láti wà ní ojú lalákàn fi ń ṣọrí kí àwọn jàǹdùkú má lò wọ́n láti fi dá wàhálà sílẹ̀.
“Mo gbàgbọ́ tí a bá wà ní ìṣọ̀kan ni a máa le kojú gbosgbo ìṣòro tó wà níwájú wa.”
This article contains content provided by Facebook. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Facebook cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Facebook post















