Kí ni ẹ̀sìn rẹ sọ nípa ìwọ́de àti ṣíṣe ìfẹ̀hónúhàn?

Awuyewuye si n lọ lori iwọde ‘ebi n pa wa’ ti yoo bẹrẹ l’Ọjọbọ, ọjọ kinni oṣu Kẹjọ kaakiri orilẹede Naijiria.
Aarẹ Bola Tinubu ti ṣe oniruuru ipade pẹlu awọn gomina, ọba alaye, awọn olori ẹsin at'awọn mii tọrọ kan, bi ọjọ iwọde naa ṣe n sun mọ.
Aarẹ lo awọn ipade yii lati le jẹ kawọn alẹnulọrọ yii le b'awọn to n gbero lati ṣe ifẹhonuhan sọrọ ki wọn le wọgile iwọde ọhun.
Amọ, nibi ti ọrọ naa de duro bayii, o dabi ẹni pe iwọde naa yoo gberasọ l’Ọjọbọ lai ṣe ani ani.
Oniruuru awọn alẹnulọrọ lo ti n sọrọ lori iwọde naa to n bọ.
Bawọn ọba alaye ṣe n sọrọ, lawọn aafa n kilọ tawọn pasitọ naa ko si gbẹyin.
Awọn kan tiẹ tun n ṣe ariyanjiyan lori bo ya ṣiṣe iwọde tako ẹsin musulumi, kristẹni tabi ẹsin abalaye.
Wọnyii ni ohun tawọn olori ẹsin sọ nipa iha ti ẹsin wọn kọ si ṣiṣe ifẹhonuhan.
Ẹsin musulumi faramọ ṣiṣe ifẹhonuhan, amọ... – Sheik Akeugbagold
Gbajugbaja onimọ nipa ẹsin musulumi, Sheik Taofeek Akeugberu Akeugbagold ṣalaye fun BBC Yoruba wi pe ‘’ẹsin Islam faye gba ṣiṣe iwọde bo tilẹ jẹ pe ko tii si ohun to n jẹ iwọde laye Anọbi.
Ṣugbọn awọn ọna wa tawọn eeyan maa n gba fi ẹhonu han si nnkan ti ko tẹ wọn lọrun ti ijọba ba n ṣe nigba naa.
Ti o ba jẹ wi pe ẹsin Islam o fọwọ si iwọde ṣiṣe ni, Ọlọrun o ni sọ fun Mose wi pe ki o lọ sọ fun Pharao to n fiya jẹ awọn ọmọ Israel pe o ti kọja aye rẹ.
Koko ohun ti mo n sọ ni pe iwọde n bẹ ninu Islam ti ko ba ti la wahala lọ.
Ọlọrun sọ fun Mose wi pe ki o jiṣẹ fun Pharao lai da nnkan ru tabi lai ba nnkan jẹ.
Adiisi Anọbi tun sọ pe ki ẹnikẹni ti inira ba de ba sọrọ sita, ki o si fi ibinu rẹ han.’’
Akeugbagold ni ko si ijọba to maa sọ pe kawọn eeyan ma ṣe iwọde ti wọn ko ba ni ba nnkan jẹ.
Sheik Akeugbagold sọ pe ẹsin Islam ko tako ki araalu ṣe ifẹhonuhan ni wọn igba ti ko ba ti la wahala lọ.
Amọ, o fikun ọrọ rẹ wi pe laye Anọbi, ko si wi pe awọn eeyan maa to soju titi lati ṣe iwọde.
Akeugbagold ni awọn araalu maa n lọ siwaju awọn ọba nigba naa ni lati sọ fun wi pe awọn o faramọ ohun to n lọ ni.
Ifa ko tako ṣisẹ ifẹhonuhan – Akọda Awo Idowu Olukunle
Babalawo to tun jẹ Akoda Awo, Idowu Olukunle naa ṣalaye fun BBC Yoruba pe Ifa faramọ ṣiṣe iwọde.
Akoda Awo ni ‘’iyawo le pariwo sọkọ ti ọkọ ko ba gbọran.
Ọmọ le pariwo si eti baba ati iya rẹ ti nnkan kan ba n lọ ninu ile.
Awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ le pariwo si eti ọga wọn naa ti ara ba ni wọn.
Bakan naa ni araalu ilu pariwo si eti ẹni to n dari ilu, ko si ohun to buri nibẹ.’’
Babalawo Olukunle ko ṣai fidi rẹ mulẹ pe Ifa o faye gba kawọn eeyan maa ba nnkan jẹ lasiko ti wọn ba n ṣe iwọde.
Akoda Awo tun wa sọrọ lorukọ ara rẹ ati idile rẹ wi pe o yẹ kawọn olori orilẹede Naijiria gbọ ohun tawọn araalu n fẹ iwọde le lori ki wọn si ṣe atunṣe.
‘’Ara n ni ilu, awọn eeyan n pariwo; owo ọkọ ti a n wọ lojoojumọ ti di gọbọi.
Epo ni akọkọ ninu gbogbo ohun to n fiya jẹ ọmọ Naijiria lasiko yii.
Nitori naa, ojuṣe ijọba ni lati wa ojutuu si ohun tawọn araalu n ṣe iwọde le lori,’’ Akoda Awo ṣalaye.
Ẹsin kristẹni ko tako ṣiṣe iwọde amọ o tako iwa jagidijagan lasiko ifẹhonuhan – Baba Sebi Ọba
Nigba ti o n a BBC Yoruba sọrọ Alufaa Ọmọwe S.M.O. Mustapha sọ fun BBC Yoruba wi pe ẹsin awọn ọmọlẹyin Kristi faramọ ṣiṣe iwọde.
Amọ, Alufaa Mustapha fidi rẹ mulẹ wi pe Bibeli tako iwa jagidijagan lasiko iwọde.
‘’Ẹsin Kristẹni ko ni iṣoro kankan pẹlu ṣiṣe iwọde, ṣugbọn a kii ṣe iwọde ni Naijiria.
Jagidijagan ni a maa n ṣe, mi o tii ri iwọde ti wọn ṣe ni Naijiria ri to lọ ni irọwọ rọsẹ.
Awọn araalu maa n ṣe iwọde ni ọpọlọpọ orilẹede ti o ṣi maa n lọ ni alaafia.
Awọn eeyan maa n fi iwọde beere ohun ti wọn ba fẹ ki ijọba ṣe.
Amọ, ni Naijiria wọn maa fi n ba nnkan jẹ ni gẹgẹ bi ohun to ṣẹlẹ lasiko iwọde EndSARS to kọja lọdun 2020.
Ọpọ igba lawọn janduku maa n ja iwọde gba ti wọn ṣi maa n lo lati ba dukia ijọba jẹ.
Nitori naa, ẹsin Kristẹni tako bi a ṣe maa n sẹwọde ni Naijiria tori Bibeli sọ pe Ọlọrun ko si nibi rudurudu; eyi to tumọ si pe kristẹni naa ko gbọdọ wa nibi rudurudu.
O san kawọn eeyan jokoo sile ju ki wọn lọ sibi ti wọn ti n ṣe ifẹhonuhan lọ.















