‘Ọlọ́gbọ́n bíi Solomọ́nì, onífáàrí tó mọ ara á mú ni Ọwá Idanre tó wàjà’

Ọba Aroloye

Oríṣun àwòrán, sunshinetruth

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ni ọjọru ni iroyin bọ sita pe Ọwa ilu Idanre, Ọba Ọba Adegunle Aroloye jáde láyé lẹ́ni ọdún 102.

Ninu ọrọ to ba BBC News Yoruba sọ, Ọkan lara awọn ọmọ Ọbalaye naa, Ọmọọba Oluwakayọde Adebambọ Arọloye ṣalaye pe ọlọgbọn pupọ ‘afi bii ti Solomọni’ ni kabiyesi to waja naa.

O ni gbogbo ọrọ ni Kabiyesi Arọloye ni esi fun to bẹ ti awọn eeyan ilu naa fi gbagbọ pe gbogbo ohun ti wọn ba mu de ọdọ rẹ ni yoo ba awọn fi ọgbọn inu to.

O fi kun un pe onifaari to mọ ara a mu ni Ọba Arọloye nigba aye rẹ.

“Baba n wọ aṣọ. Nigbakugba ti ẹ ba ri baba, o le jẹ Ankara ni wọn fẹ wọ, Ẹ o rii gẹgẹ bi onimọtoto.

O ni nigba aye rẹ o rii daju pe ilu Idanre ati ọr Aje rẹ tubọ gbopọn sii.

Adanu nla ni iku Ọwa ti ilu Idanre fun ipínlẹ̀ Ondo ati gbogbo ilẹ̀ Yoruba - Gomina Ipinlẹ Ondo

Ninu ọrọ ibanikẹdun to kọ ranṣẹ, gomina ipinlẹ Ondo, Lucky Ayedatiwa ni adanu nla ni iku Ọba Adegunle Arọloye jẹ fun ipinlẹ Ondo ati ilẹ Yoruba lapapọ.

O ni lara awọn ọbalaye ti iyan wọn ko ṣe ko kere lorilẹede Naijiria ni Ọba Arọloye ẹni to ni o lo iriri ati ọgbọn inu lati fi mu alaafia ba ilu Idanre ati agbegbe rẹ.

“A o tubọ maa ranti ẹmi ifaraẹnijin, itọnisọna, ati ifọkansin ti ko lẹgbẹ to ni fun idagbasoke ilu Idanre ati ipinlẹ Ondo.

Ọwá ìlú Idanre, Ọba Adegunle Aroloye jáde láyé lẹ́ni ọdún 102
Ọba Aroloye

Ọwa ilu Idanre ni ipinlẹ Ondo, Ọba Frederick Adegunle Aroloye, Arubiefin kẹrin ti waja.

Agba oye ilu Idanre to tun jẹ Lisa ilu Idanre, Oloye Christopher Oluwọle Akindlolire fi idi iroyin yii mulẹ ni owurọ Ọjọru.

O ni igbesẹ gbogbo to yẹ ti n bẹrẹ fun ayẹyẹ ikẹyin rẹ.

Ẹni ọdun mejilelọgọrun ni ọba Aroloye ki o to jade laye.

Ọdun mejidinlaadọta ni Ọba Aroloye lo lori apere Ọwa Idanre.

Ẹkunrẹrẹ iroyin n bọ laipẹ...