Japan dáná sun Super Falcons Nàìjíríà ráúráú nínú ìdíje Olympics saájú ìwọ́de 'ebi ń pa wá'

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Nnkan o tun ṣẹnu ire fun ẹgbẹ agbabọọlu Super Falcons Nàìjíríà ninu idije ere bọọlu Olympics 2024 lorilẹede France lẹyin ti Japan juwe ọna ile fun wọn.
Ami ayo mẹta si ẹyọkan ni Japan fi lu wọn ni alubami ti wọn o si le ta putu.
Ti ẹ o ba gbagbe, Super Falcons fidirẹmi ninu ifẹsẹwọnsẹ àkọkọ ti wọn gba pẹlu Brazil.
Bakan naa ni ọmọ tun ṣori fun Naijiria ninu ifẹsẹwọnsẹ keji ti wọn tun gba pẹlu Spain.
Ṣaaju ifẹsẹwọnsẹ Ọjọru pẹlu Japan ni Falcons ni ireti pe awọn si le tẹsiwaju ninu idije Olympics t'awọn ba le lu Japan.
Amọ, kaka ki o ri bẹẹ, nise lọrọ bẹyin yọ yi Naijiria sí tun jẹ ajẹtun iya lọwọ Japan.
Nnkan bi ọdun mẹrindilogun sẹyin ni ẹgbẹ agbabọọlu Super Falcons ti kopa gbẹyin ninu idije ere bọọlu Olympics.
Kí ni ìrètí Super Falcons tó bá pàde Japan nírọ̀lẹ́ òní ní Paris 2024 Olympics?
Ikọ agbabọọlu obinrin Naijiria, Super Falcons, ti wa ni bebe ati ja kuro ninu idije Paris 2024 Olympics bayii lẹyin ti wọn lulẹ ninu ifẹwọnsẹ wọn pẹlu Brazil ati Spain.
Ijakulẹ wọn pẹlu Spain ba awọn ololufẹ wọn lọkan jẹ pupọ latari igbiyanju ninu ifẹsẹwọnsẹ ọhun.
Ijakulẹ ọhun tun mu ki nnkan buru si fun ikọ naa latari pe wọn yoo pada sile ti wọn ba tun lulẹ ninu ifẹsẹwọnsẹ to kan.

Oríṣun àwòrán, THE NFF
Aago mẹrin irọle oni ni ifẹsẹwọnsẹ naa yoo waye.
Wayi o, ikọ Super Falcons ṣi ni ireti ti wọn ba pade Japan lẹyin ti Japan ti kọkọ din dundu iya fun Brazil pẹlu ami ayo 2:1.
Esi ifẹsẹwọn Japan ati Brazil naa ni ireti Naijiria bayii, iyẹn ti Naijiria ba le yege ninu ifẹsẹwọnsẹ pẹlu Japan lonii.
Ki Super Falcons to le pegede si ipele komẹseo-ọ-yọ, o gbọdọ na Japan pẹlu o kere tan, ami ayo meji.
Ọpọ awọn ololufẹ bọọlu lo gbagbọ pe o ṣeeṣe ki ikọ Naijiria bori Japan amọ yoo ṣoro fun wọn lẹyin ijakulẹ meji iṣaaju.
Bo tilẹ jẹ pe awọn to n gba ọwọ ẹyin fun Super Falcons ta lẹnu ninu idije ọhun, o jọ bii pe awọn to n gba ọwọ iwaju ku diẹ kaato.
Ti Naijiri ba fẹ ṣasẹyọri ni irọlẹ oni, awọn to n gba ọwọ iwaju ni lati jawe sobi ojuṣe wọn, iṣẹ nla lo si wa fun awọn eeyan bii Asisat Oshoala ati Rasheedat Ajibade.
Wayi o, awọn ti igbagbọ wa pe yoo gba bọọlu fun Naijiria loni ni Chiamaka Nnadozie; Chidinma Okeke, Blessing Demehin, Osinachi Ohale, Michelle Alozie; Toni Payne, Christy Ucheibe, Deborah Abiodun, Rasheedat Ajibade; Asisat Oshoala ati Esther Okoronkwo.
Nigba ti awọn to ṣeeṣe ki wọn soju Japan jẹ Ayaka Yamashita; Miyabi Moriya, Moeka Minami, Saki Kumagai, Hana Takahashi, Toko Kogo; Fuka Nagano, Yui Hasegawa, Hinata Miyazawa; Maika Hamano ati Mina Tanaka.















