Arábìnrin tó gbé ìkòkò tí kò sí nǹkan nínú rẹ̀ lọ síbi ìwọ́de l'Eko ṣàlàyé ìdí tó fi ṣe bẹ́ẹ̀
Yoruba bọ wọn ni ebi kii wọnu ki ọran mii o wọọ.
Ohun difa fun Arabinrin Nofisat Sikiru to gbe ikoko lọ sibi iwọde ‘ebi n pa wa’ niluu Eko lati le jẹ ki ijọba mọ pe oun o ri ounjẹ jẹ latari ọwọngogo nnkan lorilẹede Naijiria.
Fọnran arabinrin naa lu ori itagun ayelujara pa lẹyin to kopa ninu iwọde ọhun pẹlu omi loju rẹ.
Nofisat sọ fun BBC pe ‘’nkan ti mo fẹ fi han ọmọ araye ni pato ni pe ko si nkan kan to maa jẹ.
Agbegbe Ojota ti iwọde yii ti waye ni mo ti n ta ọja, ounjẹ sise ati tutu ni mo n ta.
Ko si iṣẹ ti mo i ṣe, ole nikan ni n ko ja, wọn tun gbowo mi lọ, ọmọ tun ku mọ mi lọwọ.
Ọjọ kejila oṣu Kẹfa ọdun yii ni akọbi mi jade laye, mo waa wa loju kan bi omi adagun.
Ohun to mo fi gbe ikoko ti ko si nnkan ninu rẹ jade niyẹn.
Iyẹn gan an lo jẹ ki n gbe ikoko jade ki ọmọ araye le ṣaanu mi.’’
Lẹyin ti fọnran iwọde naa tan kaakiri ori ayelujara ni awọn eeyan bẹrẹ si ṣeleri fun Nofisat.
O ni ẹnikẹni ti o fẹ fun oun lowo yoo de ibi ti oun gan an ko lero laye lọ.
Nofisat ni ọja loun maa fi owo ti wọn ba foun bẹrẹ pada.
‘’Mi o ra aṣọ, mi o ra nkan nkan, ṣugbọn ki n maa ṣiṣẹ, ki n le maa jẹun.
Bi Ọlọrun ba dẹ ni ọlọjọ de, o tan sibẹ niyẹn.
Mo rọ ijọba pe ki wọn ran wa lọwọ ki gbogbo nkan to wọn gogo ṣe maa walẹ,'' Nofisat lo sọ bẹẹ.






