Èyí ni bí àwọn èyà Jew ṣe ń gba àtọ̀ òkú ọmọ wọn láti lè ní ọmọ-ọmọ láyé

Ai ni arẹmọ ko yẹ agba. Bakan naa lo si tun jẹ pe iran to ba fẹran ọmọ bibi ko ni i fẹẹ ku akurun, wọn yoo fẹẹ fi ọmọ saye lọ ṣaa ni.
Ṣugbọn nigba ti idaamu ba bẹ silẹ lorilẹede kan, ti ogun ṣẹyọ lojiji, ọpọ ọmọkunrin ti wọn ba lọ soju ogun ni wọn ki i de mọ, ti wọn yoo ti ku soju ogun.
Ohun to n ṣẹlẹ ree ni orilẹede Israel, latigba ti Hamas ti n kọlu wọn.
Ọpọlọpọ obi lo ti padanu awọn gendekunrin wọn soju ogun, paapaa awọn ti ọmọ wọn jẹ ologun.
Pupọ awọn ọmọ to n ku sogun naa ni ko niyawo, debi ti wọn yoo tilẹ bimọ ki wọn too ku.
Eyi lo mu awọn obi wọn faramọ igbesẹ kan ti wọn ti maa n gba atọ lara awọn oku naa, ti wọn yoo si wa obinrin ti yoo ba wọn gba kinni ọhun sara.
Obinrin to ba gba atọ naa yoo loyun, yoo si fi oyun naa bi ojulowo ọmọ bii igba ti ibalopọ akọ atabo ba waye naa ni.
Awọn obi to n tẹle ilana yii sọ pe o maa n jẹ ọna kan lati fi maa ranti ọmọ awọn to ku, yoo si tun tumọ si pe ko ku akurun.
Ìlànà yìí kò rọrùn bẹ́ẹ̀, nítorí òfin tó rọ̀ mọ́ ọ

Nigba ti ọmọkunrin ṣọja ẹni ogun ọdun kan, Reef, ku sogun ni Guusu Gaza, iyẹn lọjọ kẹfa, oṣu kẹrin ọdun 2024 yii, baba rẹ, Avi Harush, ko gbọ nile.
Ṣugbọn bi Avi ko ṣe gbọ iku ọmọ rẹ to, sibẹ, ara n fu u pe nnka aburu kan fẹẹ ṣẹlẹ.
Awọn ṣoja pada waa tufọ naa fun un, inu rẹ bajẹ gẹgẹ bi obi, o si ronu ohun toun yoo ṣe lati maa ranti Reef to ku lọmọde soju ogun.
Reef ko ni ọrẹbinrin debi ti yoo tilẹ ni iyawo tabi bimọ, awọn to waa tufọ sọ fun baba rẹ pe awọn ṣi le gba atọ ara Reef nigba to ku naa, bi baba rẹ ba fẹ ko lọmọ laye.
Baba Reef fẹ bẹẹ, o ni ọmọ oun nifẹẹ ọmọ gan-an nigba aye rẹ. Bayii ni baba yii bẹrẹ si i kede ohun to ṣẹlẹ si i, awọn obinrin si i jade pe awọn yoo ba a gba atọ Reef s’ara.
Eto naa waye, obinrin kan gba atọ naa, o si fi bimọ tuntun lanti-lanti to di ọmọ-ọmọ fun Avi, Baba Reef.
Ṣugbọn lọpọ igba, ki i rọrun lati ri igbesẹ yii gbe.
Eyi ri bẹẹ nitori obi to fẹẹ ṣe bẹẹ yoo ni lati fi da kootu loju pe ọmọ oun nifẹẹ si ọmọ bibi nigba aye rẹ.
To ba jẹ ọmọ ti ko ka ibimọ si nnkan pataki nigba aye rẹ lo ku, yoo ṣoro ki kootu too gba pe ki wọn gba atọ rẹ lẹyin to ku tan ko le baa lọmọ laye.
Ohun mi-in to tun mu igbesẹ naa ṣoro ni pe o maa n gba ọpọlọpọ asiko ki wọn kootu too fi aṣẹ si i.
Báwo ni wọ́n ṣe ń gba àtọ̀ òkú?

Oríṣun àwòrán, Reuters
Laaarin wakati mẹrinlelogun ti oku ku lo daa ju lati gba atọ lara rẹ, bo tilẹ jẹ pe atọ naa ṣi le ṣiṣẹ, ko si ni agbara titi wọ wakati mejilelaadọrin.
Bi wọn ba fẹẹ gba atọ lara oku, wọn yoo ge nnkan ọmọkunrin oku naa, wọn yoo si ge ẹran diẹ, nibẹ ni wọn yoo ti ri atọ gba ti wọn yoo si lọọ fi pamọ sinu ẹrọ amu nnkan tutu.
Ki wọn too dari rẹ si ara obinrin ti yoo gbe e .
"Gbigba atọ lara ọmọkurin to ku jẹ nnkan to nitumọ gan-an. Ilana to gbẹyin ninu eyi ti eeyan le fi lọmọ laye lọjọ iwaju ni.’’
Dokita Itai Gat, Adari nileewosan Shamir Medical Center, lo sọrọ yii.
Dokita Gat funra rẹ naa maa n ṣiṣẹ abẹ gbigba atọ lara oku.
O ni iyatọ ti wa bayii lori igbesẹ yii, nitori ọpọ eeyan lo ti n tẹwọ gba a, ofin nikan ni iṣoro tawọn eeyan ni nipa rẹ bo ṣe sọ.
Gbajugbaja onimọ nilẹẹ Jew, Yuval Sherlo, to jẹ olori nileeṣẹ to n ri si ohun to yẹ nilẹẹ Jew, ‘Tzohar Center for Jewish Ethics,’ sọ pe ọrọ atọ gbigba lara oku yii kẹnu pupọ.
Yuval sọ pe, " gẹgẹ bi ofin, a ko le fipa mu ọkunrin lati di baba ọmọ, yala loju aya rẹ tabi lẹyin rẹ. "
O ni ofin meji lo ṣe pataki ninu igbesi aye awọn Jew, akọkọ ni pe ki eeyan ma ku akurun, ikeji si ni pe ki wọn sin oku rẹ lodidi lai jẹ pe ẹya ara kankan yingin.
Awọn onimọ kan nilẹẹ Jew sọ pe ki wọn ge apa kan ẹya ara eeyan ti wọn fẹẹ sin ko ṣe nnkan, awọn mi-in si sọ pe ko yẹ ki wọn fọwọ kan ẹya ara oku rara.
Nibi ti ọrọ naa de duro bayii, awọn aṣofin Israel n ṣiṣẹ lori rẹ, lati mọ eyi ti yoo fẹsẹ mulẹ, ṣugbọn igbiyanju wọn ko ti i so eso rere.
Wo mọ̀lẹ́bí tó kọ́kọ́ lo ìlànà yìí àti ọmọ tí wọ́n fi bí


Tọkọtaya Rachel ati Yaakov Cohen ni wọn kọkọ gba atọ ọmọ wọn, Keivan ti awọn Palestine pa ni 2002, ni Gaza.
Ọmọbinrin ni wọn fi atọ naa bi, wọn pe orukọ rẹ ni Osher.
Iya to bi Osher ni orukọ rẹ n jẹ Irit. O ṣalaye fun BBC pe nigba ti dokita ti yẹ oun wo, ti wọn ni oun peye lati loyun loun ṣe gba lati gbe atọ Keivan sara, ti oun si fi bi Osher.
"Awọn kan sọ pe a n mu Ọlọrun ṣere ni pẹlu ilana yii, ṣugbọn emi ko ro bẹẹ.
Iyatọ wa ninu ọmọ to mọ baba rẹ ati eyi to jẹ wọn gbe atọ baba rẹ si iya rẹ lara ni’’
Irit lo ṣalaye bẹẹ.
Osher, ọmọ ti wọn fi atọ naa bi paapaa sọrọ, o ni, ‘’mo mọ pe wọn lọọ wa atọ baba mi ni, wọn si wa obinrin to yẹ lati bi mi’’
Ọmọdebinrin naa to ti pe ọdun mejila bayii, loun mọ pe oju ogun Palestine ni wọn pa baba oun si.
Awọn aworan ẹyẹ Dolphin lo ya si yara rẹ kaakiri, o ni oun gbọ pe baba oun fẹran awọn ẹyẹ naa nigba to wa laye.
Bakan naa ni Rachel, iya to bi Keivan, sọ pe o wu ọmọ oun lati bimọ nigba to wa laye.
O ni fọto rẹ toun wo lẹyin iku rẹ n ke tantan nitori ọmọ ni.
Rachel sọ pe oun ati baba Kevian jagun naa labẹ ofin, o gba ọpọlọpọ ọdun, ṣugbọn awọn pada bori, Osher, ọmọ-ọmọ awọn si waye rọgbọdọ-rọgbọdọ.
Gẹgẹ bi ohun ti awọn eeyan to sunmọ ijọba sọ fun BBC lori ilana yii, wọn ni ariyanjiyan wa nipa gbigba aṣẹ lọwọ ẹni to ti ku, pe ṣe o wu ki wọn fi atọ rẹ bi ọmọ tuntun tabi bẹẹ kọ.
Ariyanjiyan tun wa lorii pe ṣe ọmọ ti wọn fi atọ oku bi yoo ni ẹtọ iru eyi ti awọn ọmọ ti ṣọja to ku sogun naa ti bi tẹlẹ( To ba jẹ ẹni to ti bimọ funra rẹ ṣiwaju iku).
Nnkan miran tun ni pe bi iyawo oku ko ba fẹ ki wọn lo atọ ọkọ fun ibimọ nkọ?
Bẹẹ lawọn kan sọ pe awọn obi oku ni ki wọn fi ọrọ atọ naa le lọwọ, nitori awọn ni nnkan ṣe julọ.
Ṣugbọn fun awọn eeyan to ti lo ilana yii to si jẹ́ fun, ko si ohun to daa to o.
















