Ìwádìí bẹ̀rẹ̀ lórí ọkùnrin tó kú sínú kànga nílùú Ilorin

Aworan kanga
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ọjọ buruku esu gbomimu lọjọ Aiku ọjọ kẹrin oṣu Keje ọdun yìí jẹ lagbegbe Aliara Mọnjẹasurawa ni ijọba ibilẹ guusu Ilọrin, ipinlẹ Kwara.

Sa dede ni wọn ri oku ọkunrin kan ti wọn ko mọ orukọ rẹ ni ninu kanga.

Adari ẹka eto iroyin ile isẹ panapana ipinlẹ Kwara, ọgbẹni Hasaan Hakeem Adekunle lo fidi ọrọ yii mulẹ.

O salaye pe ''ṣe ni wọn pe ile isẹ panapana lori ẹrọ ibanisọrọ pe wọn ri oku ẹnikan ninu kanga

Loju ẹsẹ lawọn gbera lọ sibẹ ti awọn si yọ oku ọkunrin ẹni ọdun mejidinlogoji naa, táwọn si gbe oku naa fun Ọga agba ọlọpaa lagọ ọlọpaa Ganmon, DCO Ọlatunji.

Ọgbẹni Adekunle sọ pe iwadii ṣi n lọ lọwọ lori Iṣẹlẹ naa.

Aworan kanga

Ninu ọrọ rẹ, ọkan lara awọn ara adugbo naa to ba BBC Yoruba sọrọ, Ọgbẹni Kayọde Yusuf sọ pe, awọn ara adugbo naa o da ọkunrin to ku si kànga naa mọ, nitori kìí ṣe ara adugbo naa.

Arabirin Mariam ti oun naa n gbe ladugbo naa ni ohun pọn mi ni ninu kanga naa lana, awọn o ri kankan nibẹ.

Ni bayii awọn ọlọpaa ti gbe oku ọkùnrin naa lọ budo igboku pamọ si, ti iwadii ṣi n lọ lọwọ.