Èèyàn mélòó ló ti kú lásìkò ìwọ́de #EndBadGovernance yí?

Àjọ Rights group Amnesty International ti bu ẹnu àtẹ́ lu bí àwọn olùwọ́de kan ṣe pàdánù ẹ̀mí wọn látọwọ́ àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò Nàìjíríà.
Adarí àjọ ọ̀hún ní Nàìjíríà, Isa Sanusi nínú àtẹ̀jáde kan tó fi síta lọ́jọ́ Ẹtì, ọjọ́ Kẹta, oṣù Kẹjọ, ọdún 2024 ní èèyàn mẹ́tàlá ló pàdánù ẹ̀mí ní ọjọ́ àkọ́kọ́ ìwọ́de, tí ọ̀pọ̀ èèyàn sì farapa.
Èyí ló ń wáyé lẹ́yìn tí iléeṣẹ́ ètò ààbò aládàni kan ní Nàìjíríà – Beacon Consulting ṣe ní èèyàn ogún lọ jáde láyé níbi ìwọ́de náà.
Àwọn àjọ méjéèjì ni wọ́n gbà pé èèyàn mẹ́fà ló pàdánù ẹ̀mí wọn ní Suleja, ìpínlẹ̀ Niger nígbà tí àwọn mẹ́rin pàdánù ẹ̀mí wọn ní Maiduguri, tí àwọn mẹ́ta sì jẹ́ Ọlọ́run nípè ní Kaduna.
Àwọn ibòmíràn táwọn èèyàn tún ti pàdánù ẹ̀mí wọn sọ́wọ́ àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò gẹ́gẹ́ bí àwọn àjọ náà ṣe sọ ni Kano, Kebbi àti Jigawa.
Wọ́n ní ṣíṣe ìkọlù sáwọn olùwọ́de tó ń lọ ní àláfíà wọn kìí ṣe ohun tó ṣe á gbọ́ rárá àti pé kò bá òfin mu.
Isa Sanusi ké pe ìjọba Nàìjíríà láti ṣe ìwádìí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó wáyé níbi ìwọ́de náà kí wọ́n sì fi ìjìyà tó tọ́ jẹ ẹ̀ṣọ́ ààbò tó bá lọ́wọ́ nínú lílo ọwọ́ agbára láti fi kojú àwọn olùwọ́de tó gbẹ̀mí àwọn èèyàn.
Ọ̀gá ọlọ́pàá ní Nàìjíríà, Kayode Egbetokun ní àwọn àwọn ti sọ fún àwọn ọlọ́pàá káàkiri Nàìjíríà láti wà ní sẹpẹ́, kí wọ́n wà ní ìgbáradì láti tètè dáhùn sí ẹnikẹ́ni tó bá gbèrò láti dá omi àláfíà ìlú rú.

Ìròyìn ní ọlọ́pàá kan pàdánù ẹ̀mí ẹ̀mí rẹ̀, tọ́pọ̀ àwọn mìíràn sì farapa nígbà tí àwọn olùwọ́de ṣe ìkọlù síwọn lọ́jọ́ àkọ́kọ́ ìwọ́de náà.
Egbetokun ní àdó olóró tó dún gbàmù láàárín ibi àwọn olùwọ́de ṣekúpa èèyàn mẹ́rin lójú ẹsẹ̀ tí àwọn mẹ́tàlélọ́gbọ̀n mìíràn s[pi farapa, tí wọ́n wà ní ẹsẹ̀ kan ayé ẹsẹ̀ kan ọ̀run báyìí nílé ìwòsàn tí wọ́n ti ń gba ìtọ́jú lọ́wọ́.

Bákan náà ló ní àwọn kan dáná sun àwọn àgọ́ ọlọ́pàá, tí wọ́n sì tún gbèrò láti yawọ àwon ilé ìjọba kan, tí wọ́n sì tún bá àwọn dúkìá ìjọba jẹ́ ní àwọn, já ṣọ́ọ̀bù láti jalè ní àwọn ìpínlẹ̀ kan ní ẹkùn àríwá Nàìjíríà.
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Kano ní àwọn ti nawọ́ gán àwọn afurasí 269 tí èròńgbà wà pé wọ́n lọ́wọ́ nínú ìwà jàǹdùkú ní Kano.
Ìpínlẹ̀ Kano àtàwọn ìpínlẹ̀ mìíràn bíi Borno, Yobe àti Jigawa ni ìjọba ti kéde kónílé ó gbélé nítorí wàhálà tọ wáyé láwọn ìpínlẹ̀ náà.














