Kí ló mú àwọn ìpínlẹ̀ kan kéde kónílé-ó-gbélé lásìkò ìwọ́de #EndBadGovernance, ìgbà wo ni yóò sì kásẹ̀-ń-lẹ̀?

Ìwọde ebi n pa ilu gberasọ lorilẹede Naijiria, ti ọpọ araalu si tu sita lati fi ehonu wọn han sita.
Ìwọde ọhun ti ọpọ sapejuwe gẹgẹ bii ìwọde alaafia lo gba ọna miiran yọ nigba ti rogbodiyan bẹ silẹ ni awọn ipinlẹ kan.
Ní apa Ariwa orilẹede Naijiria, ọpọ awọn Gomina lo kede igbesẹ konile-gbele lati le fi aye silẹ fun alaafia.
Ipinlẹ Borno
Nipinlẹ Borno, ileeṣẹ Ọlọpaa kede igbesẹ konile-gbele fún wakati mẹrinlelogun.
Gomina Babagana Umara Zulum ni ìjọba gbe Igbesẹ lẹyin ti rogbodiyan bẹ silẹ ni agbegbe Bulunkutu ni Maiduguri lẹyin ti bugbaamu waye.
Eeyan mẹrindinlogun lo padanu ẹmi wọn nibi ibugbaamu naa ti ọpọ si farapa yanayana.
Awọn Ọlọpaa ni lati yín tajutaju lati le tu awọn eeyan na ka.
Ipinlẹ Kano

Bakan naa nipinlẹ Kano, Gomina Abba Kabir Yusuf kede ofin koníle-o-gbele ní ìpínlẹ naa fun wakati mẹrinlelogun.
Ikede yii lo waye lẹyin ti ìwọde to waye nípinlẹ naa di rogbodiyan.
Ọpọ eeyan lo da gbere faye níbi ìwọde naa nigba ti awọn oluwọde si kọlu ile ijọba.
Gomina Yusuf wa pa a laṣẹ fawọn agbofinro lati ri daju pe ofin konile-gbele naa fẹ ṣe mulẹ.
Ipinlẹ Yobe
Nipinlẹ Yobe, ofin konile-gbele naa ti bẹrẹ fun wakati mẹrinlelogun ni agbegbe Gashua ati Nguru.
Ijọba gbe igbesẹ yii lẹyin ti awọn araalu bẹrẹ si ni ma fọ sọọbu, ti wọn ji ìjọba lole.
Ọpọ dukia lo ṣofo latari rogbodiyan yii sugbọn ileeṣẹ Ọlọpaa ti wa kaakiri lati ri pe alaafia jọba
Ipinlẹ Nasarawa
Ipinlẹ Nasarawa naa kede konile-gbele ni ijọba ibilẹ Karu níbi tí rogbodiyan tí bẹ silẹ lasiko ìwọde EndBadGovernance.
Gomina Ipinlẹ Nasarawa, Abdullahi A. Sule ninu atẹjade kan ti Muhammad Baba - Shehu lo kede ọrọ yii.
O ni ìwọde naa gba ọna miiran, ti ijọba si ni lati gbe igbesẹ naa ni kiakia lati jẹ ki alaafia jọba.
Ọpọ dukia lo bajẹ ni agbegbe, ti awọn eeyan kan si n fi naa jale ni agbegbe Mararaba.















